Ad-Duha

الضحى

The Morning Hours11 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلضُّحَىٰ﴿١

1Allāhu fi ìyálẹ̀ta búra.

وَٱلَّيۡلِ إِذَا سَجَىٰ﴿٢

2Ó tún fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.

مَا وَدَّعَكَ رَبُّكَ وَمَا قَلَىٰ﴿٣

3Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ.

وَلَلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ لَّكَ مِنَ ٱلۡأُولَىٰ﴿٤

4Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé.

وَلَسَوۡفَ يُعۡطِيكَ رَبُّكَ فَتَرۡضَىٰٓ﴿٥

5Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i.

أَلَمۡ يَجِدۡكَ يَتِيمٗا فَـَٔاوَىٰ﴿٦

6Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé.

وَوَجَدَكَ ضَآلّٗا فَهَدَىٰ﴿٧

7Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́.[1]

وَوَجَدَكَ عَآئِلٗا فَأَغۡنَىٰ﴿٨

8Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀.

فَأَمَّا ٱلۡيَتِيمَ فَلَا تَقۡهَرۡ﴿٩

9Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí).

وَأَمَّا ٱلسَّآئِلَ فَلَا تَنۡهَرۡ﴿١٠

10Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn).

وَأَمَّا بِنِعۡمَةِ رَبِّكَ فَحَدِّثۡ﴿١١

11Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde.

RELATED SURAHS