الليل
The Night • 21 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Allāhu fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.
2Ó tún fi ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n búra.
3Ó tún fi Ẹni tí Ó dá akọ àti abo búra.[1]
4Dájúdájú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni iṣẹ́ yín.
5Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu),
6(tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní òdodo,
7A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un.
8Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni tó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run,
9(tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní irọ́,
10A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un.
11Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá parun, tí ó já bọ́ (sínú Iná).
12Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà.
13Àti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé.
14Nítorí náà, Mo ti fi Iná tó ń jò fòfò kìlọ̀ fún yín.
15Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú,
16ẹni tí ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i.
17Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu),
18ẹni tó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀).
19Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni,
20bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ.
21Láìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rere rẹ̀).