Ya-Sin

يس

Ya-Sin83 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

يسٓ﴿١

1Yā sīn (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]

وَٱلۡقُرۡءَانِ ٱلۡحَكِيمِ﴿٢

2(Allāhu) fi Al-Ƙur’ān tí ó kún fún ọgbọ́n búra.[1]

إِنَّكَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ﴿٣

3Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.

عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ﴿٤

4(O) wà lórí ọ̀nà tààrà (’Islām).

تَنزِيلَ ٱلۡعَزِيزِ ٱلرَّحِيمِ﴿٥

5(Al-Ƙur’ān jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

لِتُنذِرَ قَوۡمٗا مَّآ أُنذِرَ ءَابَآؤُهُمۡ فَهُمۡ غَٰفِلُونَ﴿٦

6nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, (àwọn) tí wọn kò ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn bàbá wọn rí. Nítorí náà, afọ́núfọ́ra sì ni wọ́n (nípa ìmọ̀nà).[1]

لَقَدۡ حَقَّ ٱلۡقَوۡلُ عَلَىٰٓ أَكۡثَرِهِمۡ فَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ﴿٧

7Dájúdájú ọ̀rọ̀ náà ti kò lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lórí; wọn kò sì níí gbàgbọ́.

إِنَّا جَعَلۡنَا فِيٓ أَعۡنَٰقِهِمۡ أَغۡلَٰلٗا فَهِيَ إِلَى ٱلۡأَذۡقَانِ فَهُم مُّقۡمَحُونَ﴿٨

8Dájúdájú Àwa ti kó ẹ̀wọ̀n sí wọn lọ́rùn (mọ́ ọwọ́ wọn). Ó sì ga dé àgbọ̀n (wọn). Wọ́n sì gà wọ́n lọ́rùn sókè.

وَجَعَلۡنَا مِنۢ بَيۡنِ أَيۡدِيهِمۡ سَدّٗا وَمِنۡ خَلۡفِهِمۡ سَدّٗا فَأَغۡشَيۡنَٰهُمۡ فَهُمۡ لَا يُبۡصِرُونَ﴿٩

9Àti pé Àwa fi gàgá kan síwájú wọn, gàgá kan sẹ́yìn wọn; A bò wọ́n lójú, wọn kò sì ríran.

وَسَوَآءٌ عَلَيۡهِمۡ ءَأَنذَرۡتَهُمۡ أَمۡ لَمۡ تُنذِرۡهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ﴿١٠

10Bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o kò kìlọ̀ fún wọn; wọn kò níí gbàgbọ́.[1]

إِنَّمَا تُنذِرُ مَنِ ٱتَّبَعَ ٱلذِّكۡرَ وَخَشِيَ ٱلرَّحۡمَٰنَ بِٱلۡغَيۡبِۖ فَبَشِّرۡهُ بِمَغۡفِرَةٖ وَأَجۡرٖ كَرِيمٍ﴿١١

11Ẹni tí ìkìlọ̀ rẹ (máa wúlò fún) ni ẹni tí ó tẹ̀lé Ìrántí (al-Ƙur’ān), tí ó sì páyà Àjọkẹ́-ayé ní ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, fún un ní ìró ìdùnnú nípa àforíjìn àti ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé.

إِنَّا نَحۡنُ نُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَنَكۡتُبُ مَا قَدَّمُواْ وَءَاثَٰرَهُمۡۚ وَكُلَّ شَيۡءٍ أَحۡصَيۡنَٰهُ فِيٓ إِمَامٖ مُّبِينٖ﴿١٢

12Dájúdájú Àwa l’À ń sọ àwọn òkú di alàyè. A sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n tì síwájú àti orípa (iṣẹ́ ọwọ́) wọn. Gbogbo n̄ǹkan ni A ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú tírà kan tó yanjú.

وَٱضۡرِبۡ لَهُم مَّثَلًا أَصۡحَٰبَ ٱلۡقَرۡيَةِ إِذۡ جَآءَهَا ٱلۡمُرۡسَلُونَ﴿١٣

13Fi àpèjúwe kan lélẹ̀ fún wọn nípa àwọn ará ìlú kan nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wá bá wọn.

إِذۡ أَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡهِمُ ٱثۡنَيۡنِ فَكَذَّبُوهُمَا فَعَزَّزۡنَا بِثَالِثٖ فَقَالُوٓاْ إِنَّآ إِلَيۡكُم مُّرۡسَلُونَ﴿١٤

14(Rántí) nígbà tí A rán Òjíṣẹ́ méjì níṣẹ́ sí wọn. Wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. A sì fi ẹnì kẹta ró àwọn méjèèjì lágbára. Wọ́n sì sọ pé: “Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.”[1]

قَالُواْ مَآ أَنتُمۡ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُنَا وَمَآ أَنزَلَ ٱلرَّحۡمَٰنُ مِن شَيۡءٍ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا تَكۡذِبُونَ﴿١٥

15Wọ́n wí pé: “Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú tiwa. Àjọkẹ́-ayé kò sì sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe òpùrọ́.”

قَالُواْ رَبُّنَا يَعۡلَمُ إِنَّآ إِلَيۡكُمۡ لَمُرۡسَلُونَ﴿١٦

16Wọ́n sọ pé: “Olúwa wa mọ̀ pé dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.

وَمَا عَلَيۡنَآ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ﴿١٧

17Kò sì sí ojúṣe kan fún wa bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.”

قَالُوٓاْ إِنَّا تَطَيَّرۡنَا بِكُمۡۖ لَئِن لَّمۡ تَنتَهُواْ لَنَرۡجُمَنَّكُمۡ وَلَيَمَسَّنَّكُم مِّنَّا عَذَابٌ أَلِيمٞ﴿١٨

18Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa rí àmì aburú lára yín. Tí ẹ kò bá jáwọ́ (níbi ìpèpè yín), dájúdájú a máa sọ yín lókò pa. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì jẹ yín láti ọ̀dọ̀ wa.”

قَالُواْ طَٰٓئِرُكُم مَّعَكُمۡ أَئِن ذُكِّرۡتُمۚ بَلۡ أَنتُمۡ قَوۡمٞ مُّسۡرِفُونَ﴿١٩

19Wọ́n sọ pé: “Àmì aburú yín ń bẹ pẹ̀lú yín. Ṣé nítorí pé wọ́n ṣe ìṣítí fún yín (l’ẹ fi rí àmì aburú lára wa)? Kò rí bẹ́ẹ̀! Ìjọ alákọyọ ni yín ni.”

وَجَآءَ مِنۡ أَقۡصَا ٱلۡمَدِينَةِ رَجُلٞ يَسۡعَىٰ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱتَّبِعُواْ ٱلۡمُرۡسَلِينَ﴿٢٠

20Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́ náà.

ٱتَّبِعُواْ مَن لَّا يَسۡـَٔلُكُمۡ أَجۡرٗا وَهُم مُّهۡتَدُونَ﴿٢١

21Ẹ tẹ̀lé ẹni tí kò bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín. Olùmọ̀nà sì ni wọ́n.

وَمَالِيَ لَآ أَعۡبُدُ ٱلَّذِي فَطَرَنِي وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ﴿٢٢

22Kí ni ó máa mú mi tí èmi kò fi níí jọ́sìn fún Ẹni tí Ó pilẹ̀ ẹ̀dá mi? Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.

ءَأَتَّخِذُ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةً إِن يُرِدۡنِ ٱلرَّحۡمَٰنُ بِضُرّٖ لَّا تُغۡنِ عَنِّي شَفَٰعَتُهُمۡ شَيۡـٔٗا وَلَا يُنقِذُونِ﴿٢٣

23Ṣé kí èmi sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́ fi ìnira kàn mí, ìṣìpẹ̀ wọn kò lè rọ̀ mí lọ́rọ̀ kiní kan, wọn kò sì lè gbà mí là.

إِنِّيٓ إِذٗا لَّفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ﴿٢٤

24(Bí èmi kò bá jọ́sìn fún Allāhu) nígbà náà dájúdájú mo ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

إِنِّيٓ ءَامَنتُ بِرَبِّكُمۡ فَٱسۡمَعُونِ﴿٢٥

25Dájúdájú èmi gbàgbọ́ nínú Olúwa Ẹlẹ́dàá yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́ mi.” (Àwọn aláìgbàgbọ́ sì pa onígbàgbọ́ òdodo yìí.)

قِيلَ ٱدۡخُلِ ٱلۡجَنَّةَۖ قَالَ يَٰلَيۡتَ قَوۡمِي يَعۡلَمُونَ﴿٢٦

26(Àwọn mọlāika) wọ́n sọ pé: “Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Ó sọ pé: “(Ó mà ṣe o!) Àwọn ènìyàn mi ìbá ní ìmọ̀

بِمَا غَفَرَ لِي رَبِّي وَجَعَلَنِي مِنَ ٱلۡمُكۡرَمِينَ﴿٢٧

27nípa bí Olúwa mi ṣe foríjìn mí àti (bí) Ó ṣe fi mí sí ara àwọn alápọ̀n-ọ́nlé (wọn ìbá ronú pìwàdà).”

۞ وَمَآ أَنزَلۡنَا عَلَىٰ قَوۡمِهِۦ مِنۢ بَعۡدِهِۦ مِن جُندٖ مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَمَا كُنَّا مُنزِلِينَ﴿٢٨

28A kò sọ ọmọ ogun kan kalẹ̀ lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí láti sánmọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. A kò sì sọ (mọlāika kan) kalẹ̀ (fún ìparun wọn).

إِن كَانَتۡ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ فَإِذَا هُمۡ خَٰمِدُونَ﴿٢٩

29(Ìparun wọn) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan; nígbà náà ni wọ́n di òkú kalẹ̀.

يَٰحَسۡرَةً عَلَى ٱلۡعِبَادِۚ مَا يَأۡتِيهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ﴿٣٠

30Àbámọ̀ mà ni fún àwọn ẹrúsìn náà (nígbà tí wọ́n bá fojú ara wọn rí Iná); òjíṣẹ́ kan kò níí wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.

أَلَمۡ يَرَوۡاْ كَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّنَ ٱلۡقُرُونِ أَنَّهُمۡ إِلَيۡهِمۡ لَا يَرۡجِعُونَ﴿٣١

31Ṣé wọn kò wòye pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? (Ṣé wọn kò wòye pé) dájúdájú wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ wọn mọ́ (nílé ayé) ni?

وَإِن كُلّٞ لَّمَّا جَمِيعٞ لَّدَيۡنَا مُحۡضَرُونَ﴿٣٢

32Dájúdájú gbogbo wọn pátápátá sì ni (àwọn mọlāika) máa kó wá sí ọ̀dọ̀ Wa.

وَءَايَةٞ لَّهُمُ ٱلۡأَرۡضُ ٱلۡمَيۡتَةُ أَحۡيَيۡنَٰهَا وَأَخۡرَجۡنَا مِنۡهَا حَبّٗا فَمِنۡهُ يَأۡكُلُونَ﴿٣٣

33Àmì ni òkú ilẹ̀[1] jẹ́ fún wọn. A sọ ọ́ di ààyè. A sì mú èso jáde láti inú rẹ̀. Wọ́n sì ń jẹ nínú rẹ̀.

وَجَعَلۡنَا فِيهَا جَنَّٰتٖ مِّن نَّخِيلٖ وَأَعۡنَٰبٖ وَفَجَّرۡنَا فِيهَا مِنَ ٱلۡعُيُونِ﴿٣٤

34A tún ṣe àwọn ọgbà dàbínù àti àjàrà sórí ilẹ̀. A sì mú àwọn odò ìṣẹ́lẹ̀rú ṣàn láti inú rẹ̀

لِيَأۡكُلُواْ مِن ثَمَرِهِۦ وَمَا عَمِلَتۡهُ أَيۡدِيهِمۡۚ أَفَلَا يَشۡكُرُونَ﴿٣٥

35nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀ àti èyí tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe![1] Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?

سُبۡحَٰنَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلۡأَزۡوَٰجَ كُلَّهَا مِمَّا تُنۢبِتُ ٱلۡأَرۡضُ وَمِنۡ أَنفُسِهِمۡ وَمِمَّا لَا يَعۡلَمُونَ﴿٣٦

36Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde àti nínú ẹ̀mí ara wọn àti nínú ohun tí wọn kò mọ̀.[1]

وَءَايَةٞ لَّهُمُ ٱلَّيۡلُ نَسۡلَخُ مِنۡهُ ٱلنَّهَارَ فَإِذَا هُم مُّظۡلِمُونَ﴿٣٧

37Àmì kan ni òru jẹ́ fún wọn, tí À ń yọ ọ̀sán jáde láti inú rẹ̀. Nígbà náà (tí A bá yọ ọ́ tán) wọn yóò tún wà nínú òkùnkùn (alẹ́ mìíràn).[1]

وَٱلشَّمۡسُ تَجۡرِي لِمُسۡتَقَرّٖ لَّهَاۚ ذَٰلِكَ تَقۡدِيرُ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡعَلِيمِ﴿٣٨

38Àti pé òòrùn yóò máa rìn lọ sí àyè rẹ̀. Ìyẹn ni ètò (ti) Alágbára, Onímọ̀.

وَٱلۡقَمَرَ قَدَّرۡنَٰهُ مَنَازِلَ حَتَّىٰ عَادَ كَٱلۡعُرۡجُونِ ٱلۡقَدِيمِ﴿٣٩

39Òṣùpá náà, A ti ṣe òdíwọ̀n àwọn ibùsọ̀ fún un (tí ó ti ma máa tóbi sí i) títí ó máa fi padà dà bíi àran ọ̀pẹ tó ti pẹ́ (gbígbẹ).

لَا ٱلشَّمۡسُ يَنۢبَغِي لَهَآ أَن تُدۡرِكَ ٱلۡقَمَرَ وَلَا ٱلَّيۡلُ سَابِقُ ٱلنَّهَارِۚ وَكُلّٞ فِي فَلَكٖ يَسۡبَحُونَ﴿٤٠

40Kò yẹ fún òòrùn láti lo àsìkò òṣùpá. Kò sì yẹ fún alẹ́ láti lo àsìkò ọ̀sán. Ìkọ̀ọ̀kan wà ní òpópónà róbótó tó ń tọ̀.

وَءَايَةٞ لَّهُمۡ أَنَّا حَمَلۡنَا ذُرِّيَّتَهُمۡ فِي ٱلۡفُلۡكِ ٱلۡمَشۡحُونِ﴿٤١

41Àmì kan tún ni fún wọn pé, dájúdájú Àwa gbé àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn gun ọkọ̀ ojú-omi tó kún kẹ́kẹ́.

وَخَلَقۡنَا لَهُم مِّن مِّثۡلِهِۦ مَا يَرۡكَبُونَ﴿٤٢

42A tún ṣẹ̀dá (òmíràn) fún wọn nínú irú rẹ̀ tí wọn yóò máa gún.[1]

وَإِن نَّشَأۡ نُغۡرِقۡهُمۡ فَلَا صَرِيخَ لَهُمۡ وَلَا هُمۡ يُنقَذُونَ﴿٤٣

43Tí A bá fẹ́ Àwa ìbá tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Kò níí sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn. Wọn kò sì níí gbà wọ́n là.

إِلَّا رَحۡمَةٗ مِّنَّا وَمَتَٰعًا إِلَىٰ حِينٖ﴿٤٤

44Àfi (kí Á fi) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa (yọ wọ́n jáde, kí A sì tún fún wọn ní) ìgbádùn ayé títí di ìgbà díẹ̀.

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱتَّقُواْ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيكُمۡ وَمَا خَلۡفَكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ﴿٤٥

45(Wọ́n máa gbúnrí) nígbà tí A bá sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó wà níwájú yín[1] àti ohun tó wà lẹ́yìn yín[2] nítorí kí A lè kẹ yín.”

وَمَا تَأۡتِيهِم مِّنۡ ءَايَةٖ مِّنۡ ءَايَٰتِ رَبِّهِمۡ إِلَّا كَانُواْ عَنۡهَا مُعۡرِضِينَ﴿٤٦

46Àti pé āyah kan nínú àwọn āyah Olúwa wọn kò níí wá bá wọn àfi kí wọ́n máa gbúnrí kúrò níbẹ̀.

وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ أَنفِقُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ قَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَنُطۡعِمُ مَن لَّوۡ يَشَآءُ ٱللَّهُ أَطۡعَمَهُۥٓ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ﴿٤٧

47Nígbà tí A bá sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún yín.”, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí fún àwọn tó gbàgbọ́ pé: “Ṣé kí á bọ́ ẹni tí (ó jẹ́ pé) Allāhu ìbá fẹ́ ìbá bọ́ ọ (àmọ́ kò bọ́ ọ. Àwa náà kò sì níí bá A bọ́ ọ)?” Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé (ẹ wà) nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡوَعۡدُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ﴿٤٨

48Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

مَا يَنظُرُونَ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ تَأۡخُذُهُمۡ وَهُمۡ يَخِصِّمُونَ﴿٤٩

49Wọn kò retí kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan ṣoṣo tí ó máa gbá wọn mú nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àríyànjiyàn lọ́wọ́.

فَلَا يَسۡتَطِيعُونَ تَوۡصِيَةٗ وَلَآ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمۡ يَرۡجِعُونَ﴿٥٠

50Nígbà náà, wọn kò níí lè sọ àsọọ́lẹ̀ kan. Wọn kò sì níí lè padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn.

وَنُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَإِذَا هُم مِّنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ يَنسِلُونَ﴿٥١

51Wọ́n á sì fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, nígbà náà ni wọn yóò máa sáré jáde láti inú sàréè wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.

قَالُواْ يَٰوَيۡلَنَا مَنۢ بَعَثَنَا مِن مَّرۡقَدِنَاۜۗ هَٰذَا مَا وَعَدَ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَصَدَقَ ٱلۡمُرۡسَلُونَ﴿٥٢

52Wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò! Ta ni ó ta wá jí láti ojú oorun wa?” Èyí ni n̄ǹkan tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti sọ òdodo (nípa rẹ̀).

إِن كَانَتۡ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ فَإِذَا هُمۡ جَمِيعٞ لَّدَيۡنَا مُحۡضَرُونَ﴿٥٣

53Kò jẹ́ kiní kan tayọ igbe ẹyọ kan ṣoṣo. Nígbà náà ni (àwọn mọlāika) yóò kó gbogbo wọn wá sí ọ̀dọ̀ Wa.

فَٱلۡيَوۡمَ لَا تُظۡلَمُ نَفۡسٞ شَيۡـٔٗا وَلَا تُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ﴿٥٤

54Nítorí náà, ní òní wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. A kò sì níí san yín ní ẹ̀san àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

إِنَّ أَصۡحَٰبَ ٱلۡجَنَّةِ ٱلۡيَوۡمَ فِي شُغُلٖ فَٰكِهُونَ﴿٥٥

55Dájúdájú ní òní, àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò kún fún ìgbádùn.

هُمۡ وَأَزۡوَٰجُهُمۡ فِي ظِلَٰلٍ عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ مُتَّكِـُٔونَ﴿٥٦

56Àwọn àti àwọn ìyàwó wọn yóò wà lábẹ́ àwọn ibòji, wọn yó sì rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn.

لَهُمۡ فِيهَا فَٰكِهَةٞ وَلَهُم مَّا يَدَّعُونَ﴿٥٧

57Èso wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ohun tí wọ́n yóò máa bèèrè fún tún wà fún wọn pẹ̀lú.

سَلَٰمٞ قَوۡلٗا مِّن رَّبّٖ رَّحِيمٖ﴿٥٨

58Àlàáfíà ni ọ̀rọ̀ tí ó má máa wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

وَٱمۡتَٰزُواْ ٱلۡيَوۡمَ أَيُّهَا ٱلۡمُجۡرِمُونَ﴿٥٩

59Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ bọ́ sí ọ̀tọ̀ ní òní.

۞ أَلَمۡ أَعۡهَدۡ إِلَيۡكُمۡ يَٰبَنِيٓ ءَادَمَ أَن لَّا تَعۡبُدُواْ ٱلشَّيۡطَٰنَۖ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوّٞ مُّبِينٞ﴿٦٠

60Ẹ̀yin ọmọ (Ànábì) Ādam, ṣe Èmi kò ti pa yín ní àṣẹ pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún aṣ-Ṣaetọ̄n? Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.

وَأَنِ ٱعۡبُدُونِيۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ﴿٦١

61Àti pé kí ẹ jọ́sìn fún Mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà.

وَلَقَدۡ أَضَلَّ مِنكُمۡ جِبِلّٗا كَثِيرًاۖ أَفَلَمۡ تَكُونُواْ تَعۡقِلُونَ﴿٦٢

62Àti pé (aṣ-Ṣaetọ̄n) kúkú ti ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹ̀dá lọ́nà nínú yín. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni?

هَٰذِهِۦ جَهَنَّمُ ٱلَّتِي كُنتُمۡ تُوعَدُونَ﴿٦٣

63Èyí ni iná Jahanamọ tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín.

ٱصۡلَوۡهَا ٱلۡيَوۡمَ بِمَا كُنتُمۡ تَكۡفُرُونَ﴿٦٤

64Ẹ wọ inú rẹ̀ ní òní nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́.

ٱلۡيَوۡمَ نَخۡتِمُ عَلَىٰٓ أَفۡوَٰهِهِمۡ وَتُكَلِّمُنَآ أَيۡدِيهِمۡ وَتَشۡهَدُ أَرۡجُلُهُم بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ﴿٦٥

65Ní òní, A máa di ẹnu wọn pa. Àwọn ọwọ́ wọn yó sì máa bá Wa sọ̀rọ̀. Àwọn ẹsẹ̀ wọn yó sì máa jẹ́rìí sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

وَلَوۡ نَشَآءُ لَطَمَسۡنَا عَلَىٰٓ أَعۡيُنِهِمۡ فَٱسۡتَبَقُواْ ٱلصِّرَٰطَ فَأَنَّىٰ يُبۡصِرُونَ﴿٦٦

66Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fọ́ wọn lójú, wọn ìbá sì yára wá si ojú ọ̀nà, báwo ni wọ́n ṣe máa ríran ná?

وَلَوۡ نَشَآءُ لَمَسَخۡنَٰهُمۡ عَلَىٰ مَكَانَتِهِمۡ فَمَا ٱسۡتَطَٰعُواْ مُضِيّٗا وَلَا يَرۡجِعُونَ﴿٦٧

67Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá yí wọn padà sí ẹ̀dá mìíràn nínú ibùgbé wọn. Wọn kò sì níí lágbára láti lọ síwájú. Wọn kò sì níí padà sẹ́yìn.

وَمَن نُّعَمِّرۡهُ نُنَكِّسۡهُ فِي ٱلۡخَلۡقِۚ أَفَلَا يَعۡقِلُونَ﴿٦٨

68Ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ẹ̀mí gígùn lò, A óò sọ ẹ̀dá rẹ̀ di ọ̀lẹ, ṣé wọn kò níí ṣe làákàyè ni!

وَمَا عَلَّمۡنَٰهُ ٱلشِّعۡرَ وَمَا يَنۢبَغِي لَهُۥٓۚ إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرٞ وَقُرۡءَانٞ مُّبِينٞ﴿٦٩

69A kò kọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní ewì. Kò yẹ ẹ́ (kò sì rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti kéwì). Kí ni ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí i) bí kò ṣe ìrántí àti al-Ƙur’ān pọ́nńbélé

لِّيُنذِرَ مَن كَانَ حَيّٗا وَيَحِقَّ ٱلۡقَوۡلُ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ﴿٧٠

70nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ alààyè àti nítorí kí ọ̀rọ̀ náà lè kò lórí àwọn aláìgbàgbọ́.

أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّا خَلَقۡنَا لَهُم مِّمَّا عَمِلَتۡ أَيۡدِينَآ أَنۡعَٰمٗا فَهُمۡ لَهَا مَٰلِكُونَ﴿٧١

71Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá nínú ohun tí A fi ọwọ́ Wa ṣe (tí ó jẹ́) àwọn ẹran-ọ̀sìn fún wọn? Wọ́n sì ní ìkápá lórí wọn.

وَذَلَّلۡنَٰهَا لَهُمۡ فَمِنۡهَا رَكُوبُهُمۡ وَمِنۡهَا يَأۡكُلُونَ﴿٧٢

72A tẹ̀ wọ́n lórí ba fún wọn; wọ́n ń gùn nínú wọn, wọ́n sì ń jẹ nínú wọn.

وَلَهُمۡ فِيهَا مَنَٰفِعُ وَمَشَارِبُۚ أَفَلَا يَشۡكُرُونَ﴿٧٣

73Àwọn àǹfààní àti ohun mímu tún wà fún wọn nínú rẹ̀. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?

وَٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ ءَالِهَةٗ لَّعَلَّهُمۡ يُنصَرُونَ﴿٧٤

74Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣàrànṣe fún wọn!

لَا يَسۡتَطِيعُونَ نَصۡرَهُمۡ وَهُمۡ لَهُمۡ جُندٞ مُّحۡضَرُونَ﴿٧٥

75Wọn kò sì lè ṣe àrànṣe fún wọn; ṣebí àwọn òrìṣà ni ọmọ ogun tí (àwọn mọlāika) máa kó wá sínú Iná fún àwọn abọ̀rìṣà (láti fi jẹ wọ́n níyà).[1]

فَلَا يَحۡزُنكَ قَوۡلُهُمۡۘ إِنَّا نَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَ﴿٧٦

76Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú Àwa mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀.

أَوَلَمۡ يَرَ ٱلۡإِنسَٰنُ أَنَّا خَلَقۡنَٰهُ مِن نُّطۡفَةٖ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٞ مُّبِينٞ﴿٧٧

77Ṣé ènìyàn kò wòye pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú àtọ̀? (Ṣebí lẹ́yìn) ìgbà náà l’ó di alátakò pọ́nńbélé.

وَضَرَبَ لَنَا مَثَلٗا وَنَسِيَ خَلۡقَهُۥۖ قَالَ مَن يُحۡيِ ٱلۡعِظَٰمَ وَهِيَ رَمِيمٞ﴿٧٨

78Àti pé ó fi àkàwé lélẹ̀ nípa Wa.[1] Ó sì gbàgbé ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ó wí pé: “Ta ni Ó máa sọ egungun di alààyè nígbà tí ó ti kẹfun?”

قُلۡ يُحۡيِيهَا ٱلَّذِيٓ أَنشَأَهَآ أَوَّلَ مَرَّةٖۖ وَهُوَ بِكُلِّ خَلۡقٍ عَلِيمٌ﴿٧٩

79Sọ pé: “Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ l’Ó máa sọ ọ́ di alààyè. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo ẹ̀dá.

ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلشَّجَرِ ٱلۡأَخۡضَرِ نَارٗا فَإِذَآ أَنتُم مِّنۡهُ تُوقِدُونَ﴿٨٠

80(Òun ni) Ẹni tí Ó mú iná jáde fún yín láti ara igi tútù. Ẹ sì ń fi dáná.

أَوَلَيۡسَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِقَٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يَخۡلُقَ مِثۡلَهُمۚ بَلَىٰ وَهُوَ ٱلۡخَلَّٰقُ ٱلۡعَلِيمُ﴿٨١

81Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò ní agbára láti dá irú wọn (mìíràn) bí? Bẹ́ẹ̀ ni (Ó ní agbára). Òun sì ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀.

إِنَّمَآ أَمۡرُهُۥٓ إِذَآ أَرَادَ شَيۡـًٔا أَن يَقُولَ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ﴿٨٢

82Àṣẹ Rẹ̀ nígbà tí Ó bá gbèrò kiní kan ni pé, Ó máa sọ fún un pé “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.

فَسُبۡحَٰنَ ٱلَّذِي بِيَدِهِۦ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيۡءٖ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ﴿٨٣

83Nítorí náà, mímọ́ ni fún Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.

RELATED SURAHS