الصافات
Those Ranged in Ranks • 182 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Allāhu fi àwọn mọlāika tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ búra.
2Allāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà bura.
3Allāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń ka ìrántí bura.
4Dájúdájú ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo.
5Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn.
6Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́
7àti ìṣọ́ kúrò níbi (aburú) gbogbo aṣ-Ṣaetọ̄n olóríkunkun.
8(Àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika tó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀. Bí wọ́n bá sì gbìyànjú láti yọ́ ọ̀rọ̀ gbọ́ láti sánmọ̀, àwọn mọlāika) yó sì máa kù wọ́n lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀).
9Wọ́n máa lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn.
10(Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná tó máa jó o tẹ̀lé e.[1]
11Bi wọ́n léèrè wò pé, ṣé àwọn (ènìyàn) ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (n̄ǹkan mìíràn)[1] tí A dá? Dájúdájú Àwa dá àwọn (ènìyàn) láti ara ẹrẹ̀ tó lẹ̀ mọ́ra wọn.
12Rárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur’ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́.
13Àti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí.
14Nígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́.
15Wọ́n sì wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.
16Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?
17Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
18Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ.”
19Nítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn.
20Wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san.”
21Èyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.
22Ẹ kó àwọn tó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún
23lẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm.
24Ẹ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè.
25Kí ni kò jẹ́ kí ẹ ran ara yín lọ́wọ́?
26Rárá, wọ́n ti juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ ní òní ni.
27Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bi ara wọn léèrè ìbéèrè.[1]
28(Àwọn ènìyàn) wí pé: “Dájúdájú ẹ̀yin l’ẹ̀ ń gba ọ̀tún wọlé sí wa lára (láti ṣì wá lọ́nà).”[1]
29(Àwọn àlùjànnú) wí pé: “Rárá o (àwa kọ́), ẹ̀yin ni ẹ kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
30Àti pé àwa kò ní agbára kan lórí yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ìjọ olùtayọ-ẹnu ààlà.
31Ọ̀rọ̀ Olúwa wa sì kò lé wa lórí pé dájúdájú àwa yóò tọ́ Iná wò.
32Nítorí náà, a ṣì yín lọ́nà. Dájúdájú àwa náà sì jẹ́ olùṣìnà.”
33Dájúdájú ní ọjọ́ yẹn, akẹgbẹ́ ni wọ́n nínú Ìyà. (Wọ́n dìjọ máa wà nínú Iná.)
34Dájúdájú báyẹn ni Àwa yóò ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
35Dájúdájú nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé “Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu.”, wọn yóò máa ṣègbéraga.
36Wọ́n sì ń wí pé: “Ṣé a máa fi àwọn òrìṣà wa sílẹ̀ nítorí eléwì wèrè kan?”
37Kò rí bẹ́ẹ̀. Ó mú òdodo wá ni. Ó sì ń jẹ́rìí sí òdodo àwọn Òjíṣẹ́ náà.
38Dájúdájú ẹ máa tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò.
39A kò níí san yín ní ẹ̀san kan àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
40Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
41Ti àwọn wọ̀nyẹn sì ni arísìkí tí wọ́n ti mọ̀;
42àwọn èso. Àwọn sì ni alápọ̀n-ọ́nlé
43nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
44Lórí àwọn ìtẹ́ ni wọn yóò ti kọjú síra wọn.
45Wọn yóò máa gbé ife ọtí mímọ́ láti inú odò kan tó ń ṣàn káà kiri ọ̀dọ̀ wọn.
46Funfun ni (ọtí náà). Ó ń dùn lẹ́nu àwọn tó máa mu ún.
47Kò sí ìpalára kan fún wọn nínú rẹ̀, wọn kò sì níí hunrírà lórí rẹ̀.
48Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, àwọn ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ yó sì wà lọ́dọ̀ wọn.
49Wọ́n dà bí ẹyin tí wọn kò ì bó èèpo rẹ̀ kúrò lára rẹ̀.[1]
50Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè.
51Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú èmi ní ọ̀rẹ́ kan
52tí ó ń wí pé, “Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde?
53Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?”
54Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)?”
55Ó yọjú wò ó. Ó sì rí i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm.
56Ó (sì) sọ pé: “Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán.
57Àti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná.
58Àwa kò sá níí kú mọ́ báyìí?
59Àfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà.
60Dájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá.”
61Nítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ.
62Ǹjẹ́ ìyẹn l’ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún)?
63Dájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí.
64Dájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm.
65Èso rẹ̀ dà bí orí àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n.
66Dájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Wọ́n sì máa jẹ ẹ́ ní àjẹyo bámúbámú.
67Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu àwọnúwẹ̀jẹ̀ olómi gbígbóná tó gbóná parí lé e lórí.
68Lẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm.
69Dájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà.
70Àwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn.
71Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn.
72Dájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn.
73Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí.
74Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
75Dájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè.
76A gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà.
77A dá àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ sí lẹ́yìn rẹ̀.
78A sì fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
79Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Nūh láààrin gbogbo ẹ̀dá.
80Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
81Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
82Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn yòókù rì sínú agbami.
83Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wà nínú ìjọ (tí ó tẹ̀lé ìlànà) rẹ̀.[1]
84(Ẹ rántí) nígbà tí ó dojú kọ Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn mímọ́.
85(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún?
86Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti sọ irọ́ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu?
87Kí sì ni èrò ọkàn yín sí Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”[1]
88Ó ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ ní wíwò kan.
89Ó sì sọ pé: “Dájúdájú ó rẹ̀ mí.”
90Nítorí náà, wọ́n pa á tì, wọ́n sì lọ.
91Nígbà náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí jẹun ni?
92Kí ni ó ṣe yín tí ẹ kò sọ̀rọ̀?”
93Nígbà náà, ó dojú lílù kọ wọ́n pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún (ó sì rún wọn wómúwómú).
94(Àwọn abọ̀rìṣà) sáré wá dojú kọ ọ́.
95Ó sọ pé: “Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni?
96Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
97Wọ́n wí pé: “Ẹ mọ ilé kan fún un, kí ẹ sì jù ú sínú iná.”
98Wọ́n gbèrò ète sí i. A sì sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ.
99Ó sọ pé: “Dájúdájú mo máa lọ sí (ìlú tí) Olúwa mi (pa mí láṣẹ láti lọ). Ó sì máa tọ́ mi sọ́nà (láti dé ibẹ̀).[1]
100Olúwa mi, ta mí lọ́rẹ ọmọ nínú àwọn ẹni rere.”
101A sì fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìfaradà.
102Nígbà tí (ọmọ náà) dàgbà, tí ó tó bá (bàbá rẹ̀) ṣe iṣẹ́, (bàbá rẹ̀) sọ pé: "Ọmọ mi, dájúdájú èmi lá àlá pé dájúdájú mò ń dúńbú rẹ. Nítorí náà, wòye sí i, kí ni o rí sí i." Ó sọ pé: “Bàbá mi, ṣe ohun tí Wọ́n pa láṣẹ fún ọ. O máa bá mi nínú àwọn onísùúrù, tí Allāhu bá fẹ́.”
103Nígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sì dojú[1] (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀,
104A pè é (báyìí) pé, ’Ibrọ̄hīm,
105o kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
106Dájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé.
107A sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀.
108A tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
109Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm.
110Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
111Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
112A tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ’Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere.
113Àti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (tó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì.[1]
114Dájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
115A gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà.
116A tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn).
117A sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà tó yanjú.
118A tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà.
119A fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
120Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
121Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
122Dájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
123Dájúdájú (Ànábì) ’Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
124(Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni?
125Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀?[1]
126(ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
127Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná.
128Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
129A fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
130Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ilyās.
131Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
132Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
133Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
134(Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là.
135Àyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).[1]
136Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run.
137Dájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀
138àti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni?
139Dájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
140(Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi tó kún (fún èrò).
141Ó sì bá wọn ṣe kúríà papọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí kúrìá já.[1]
142Nítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi.
143Nítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu,
144dájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.
145Nítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera.
146A sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó.
147A tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i.[1]
148Wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀.
149Bi wọ́n léèrè wò pé: “Ṣé Olúwa rẹ l’ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin?
150Tàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí?”
151Gbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé:
152“Allāhu bímọ.” Dájúdájú òpùrọ́ sì ni wọ́n.
153Ṣé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni?
154Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí?
155Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?
156Tàbí ẹ ní ẹ̀rí tó yanjú lọ́wọ́ ni?
157Ẹ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
158Wọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé, dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni.
159Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
160Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
161Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu),
162ẹ kò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà
163àfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm.
164Kò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀.
165Dájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ni.
166Àti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu).
167Wọ́n kúkú ń wí pé:
168“Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́,
169dájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).”
170Ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
171Dájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́.
172Dájúdájú àwọn, àwọn l’a kúkú máa ṣàrànṣe fún.
173Àti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí.
174Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀.
175Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.
176Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?
177Nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí gbàgede wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún.
178Kúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná.
179Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.
180Mímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa (tó ni) agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
181Kí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́
182Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.