الماعون
The Small Kindnesses • 7 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Sọ fún mi nípa ẹni tó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san ní irọ́!
2Ìyẹn ni ẹni tó ń lé ọmọ-òrukàn dànù.
3Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù.
4Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) tó ń kírun;[1]
5àwọn tó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀;
6àwọn tó ń ṣe ṣekárími;
7àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn).