القدر
The Power • 5 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Dájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì.[1]
2Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Òru Abiyì?
3Òru Abiyì lóore ju ẹgbẹ̀rún oṣù.
4Àwọn mọlāika àti Jibrīl yó sì máa sọ̀kalẹ̀ nínú òru náà pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn fún gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.
5Àlàáfíà ni òru náà títí di àsìkò àfẹ̀mọ́júmọ́.