Al-'Alaq

العلق

The Clot19 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

ٱقۡرَأۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلَّذِي خَلَقَ﴿١

1Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.

خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ مِنۡ عَلَقٍ﴿٢

2Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.

ٱقۡرَأۡ وَرَبُّكَ ٱلۡأَكۡرَمُ﴿٣

3Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.

ٱلَّذِي عَلَّمَ بِٱلۡقَلَمِ﴿٤

4Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.

عَلَّمَ ٱلۡإِنسَٰنَ مَا لَمۡ يَعۡلَمۡ﴿٥

5Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.

كَلَّآ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَيَطۡغَىٰٓ﴿٦

6Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-ààlà

أَن رَّءَاهُ ٱسۡتَغۡنَىٰٓ﴿٧

7nítorí pé ó rí ara rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀.

إِنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلرُّجۡعَىٰٓ﴿٨

8Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.

أَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي يَنۡهَىٰ﴿٩

9Sọ fún mi nípa ẹni tó ń kọ̀

عَبۡدًا إِذَا صَلَّىٰٓ﴿١٠

10fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!

أَرَءَيۡتَ إِن كَانَ عَلَى ٱلۡهُدَىٰٓ﴿١١

11Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)

أَوۡ أَمَرَ بِٱلتَّقۡوَىٰٓ﴿١٢

12tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)!

أَرَءَيۡتَ إِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰٓ﴿١٣

13Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?

أَلَمۡ يَعۡلَم بِأَنَّ ٱللَّهَ يَرَىٰ﴿١٤

14Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)

كَلَّا لَئِن لَّمۡ يَنتَهِ لَنَسۡفَعَۢا بِٱلنَّاصِيَةِ﴿١٥

15Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀tá Allāhu ṣe rò ó sí.[1]) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí[2] rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);

نَاصِيَةٖ كَٰذِبَةٍ خَاطِئَةٖ﴿١٦

16àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

فَلۡيَدۡعُ نَادِيَهُۥ﴿١٧

17Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.

سَنَدۡعُ ٱلزَّبَانِيَةَ﴿١٨

18Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná.

كَلَّا لَا تُطِعۡهُ وَٱسۡجُدۡۤ وَٱقۡتَرِب۩﴿١٩

19Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ó ṣe ń sọ nípa Wa). Má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o sì súnmọ́ (Allāhu).

RELATED SURAHS