التين
The Fig • 8 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Allāhu fi èso tīn àti èso zaetūn búra.
2Ó tún fi àpáta Sīnīn búra.
3Ó tún fi ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí búra.
4Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí tó dára jùlọ.
5Lẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná).
6Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn.
7Ta l’ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí)?
8Ṣé Allāhu kọ́ ni Ẹni t’Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni?