الأعلى
The Most High • 19 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ.
2Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba.
3Ẹni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà.[1]
4Ẹni tí Ó mú koríko tútù hù jáde,
5Ó sì sọ ọ́ di gbígbẹ tó dúdú.
6Àwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé.
7Àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́.[1] Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun tó pamọ́.
8Àwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ.
9Nítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò.[1]
10Ẹni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí.
11Olórí-burúkú sì máa takété sí i.
12(Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná tó tóbi.
13Lẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà).
14Dájúdájú ẹni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀sìn rẹ̀) ti jèrè.[1]
15Ó sì rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun.
16Rárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé.
17Ọ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé.
18Dájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàǹdá àkọ́kọ́,
19tákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā.