الغاشية
The Overwhelming • 26 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Ṣebí ọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
2Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn.
3Wọ́n ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni nílé ayé).
4Wọ́n sì máa wọ inú Iná tó gbóná janjan (ní ọ̀run).
5Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú gbígbóná mu.
6Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ.
7Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi.
8Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn
9nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀.
10(Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.
11Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀.
12Omi ìṣẹ́lẹ̀rú tó ń ṣàn wà nínú rẹ̀.
13Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀,
14àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn),
15àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn,
16àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká.
17Nítorí náà, ṣé wọn kò wòye sí ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni;
18àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè;
19àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀);
20àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ pẹrẹsẹ?
21Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí.
22Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn
23àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́.
24Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà tó tóbi jùlọ.
25Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà.
26Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn.