الطارق
The Night Comer • 17 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1(Allāhu) fi sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ búra.
2Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Tọ̄riƙ?
3Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni).
4Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika).
5Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀.
6Wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi tó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́.
7Ó ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin.
8Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀
9ní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́.
10Nígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un.
11Allāhu fi sánmọ̀ tó ń rọ òjò ní ọdọọdún búra.
12Ó tún fi ilẹ̀ tó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso) búra.
13Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́).
14Kì í sì ṣe àwàdà.
15Dájúdájú wọ́n ń déte gan-an.
16Èmi náà sì ń déte gan-an.[1]
17Nítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀.