الرحمن
The Most Merciful • 78 ayahs • Medinan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Àjọkẹ́-ayé,
2Ó fi ìmọ̀ al-Ƙur’ān mọ (ẹni tí Ó fẹ́).
3Ó ṣẹ̀dá ènìyàn.
4Ó sì fi àlàyé (ọ̀rọ̀ sísọ) mọ̀ ọ́n.
5Òòrùn àti òṣùpá (ń rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé).
6Àwọn ìtàkùn ilẹ̀ àti igi ń forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).
7Àti sánmọ̀, Allāhu gbé e sókè. Ó sì fi òṣùwọ̀n òfin déédé lélẹ̀ (fún ẹ̀dá)
8pé kí ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà níbi òṣùwọ̀n.
9Ẹ gbé òṣùwọ̀n náà dúró pẹ̀lú dọ́gbadọ́gba. Kí ẹ sì má ṣe dín òṣùwọ̀n kù.
10Ilẹ̀, (Allāhu) gbé e kalẹ̀ (sí abẹ́ sánmọ̀ fún àwọn ẹ̀dá.
11Èso àti dàbínù alápó wà lórí (ilẹ̀).
12Àti èso onípòpórò àti olóòórùn dídùn (wà lórí ilẹ̀).
13Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
14(Allāhu) ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ gbígbẹ tó ń dún kokoko bí ìkòkò amọ̀.
15Ó sì ṣẹ̀dá àlùjànnú láti ara ahọ́n iná tí kò ní èéfín.
16Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
17Olúwa ibùyọ òòrùn méjèèjì àti ibùwọ̀ òòrùn méjèèjì.[1]
18Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
19(Allāhu) mú odò méjì (odò oníyọ̀ àti odò aládùn) ṣàn pàdé ara wọn.
20Gàgá kan sì wà láààrin àwọn méjèèjì tí wọn kò sì lè tayọ ẹnu-ààlà (rẹ̀ láààrin ara wọn).
21Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
22Òkúta oníyebíye àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn ń jáde nínú àwọn (odò) méjèèjì náà.
23Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
24Ti (Allāhu) ni àwọn ọkọ̀ ojú-omi gogoro tó ń rìn nínú agbami òdò (tí wọ́n dà) bí àpáta gíga.
25Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
26Gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ máa tán.
27Ojú Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé sì máa wà títí láéláé.
28Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
29Àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń bèèrè (n̄ǹkan) lọ́dọ̀ Rẹ̀; Ó sì wà lórí ìṣe lójoojúmọ́.
30Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
31A óò mú tiyín gbọ́ (lọ́jọ́ ẹ̀san), ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú.
32Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
33Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, tí ẹ bá lágbára láti sá jáde nínú àwọn agbègbè sánmọ̀ àti ilẹ̀, ẹ sá jáde. Ẹ kò lè sá jáde àfi pẹ̀lú agbára.
34Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
35Wọ́n máa ju ahọ́n iná àti èéfín (tàbí oje idẹ) iná lé ẹ̀yin méjèèjì lórí, ẹ̀yin méjèèjì kò sì níí lè ranra yín lọ́wọ́.
36Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
37Nítorí náà, nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì máa pọ́n wá wẹ̀ bí epo pupa gbígbá.
38Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
39Nítorí náà, ní ọjọ́ yẹn Wọn kò níí bi ènìyàn àti àlùjànnú kan léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; (ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Wa).
40Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
41Wọ́n máa dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ̀ pẹ̀lú àmì ara wọn. Wọ́n sì máa fi àásó orí àti ẹsẹ̀ gbá wọn mú.
42Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
43Èyí ni iná Jahanamọ tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń pè ní irọ́.
44Wọn yóò máa rìn lọ rìn bọ̀ láààrin Iná àti omi tó gbóná parí.[1]
45Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
46Ọgbà Ìdẹ̀ra méjì ń bẹ fún ẹni tó bá páyà ìdúró rẹ̀ níwájú Olúwa rẹ̀.
47Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
48(Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra méjèèjì ní) àwọn ẹ̀ka igi tó kún fún àwọn èso oríṣiríṣi.
49Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
50Odò méjì tó ń ṣàn wà nínú ọgbà méjèèjì.
51Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
52Oríṣi méjì méjì ni èso kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ọgbà méjèèjì.[1]
53Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
54Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí ìtẹ́, tí àwọn ìtẹ́ inú rẹ̀ jẹ́ àrán tó nípọn. Àwọn èso ọgbà méjèèjì sì wà ní àrọ́wọ́tó.
55Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
56Àwọn obìnrin tí kì í wo ọkùnrin mìíràn wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò sì fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn.
57Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
58Wọ́n dà bíi ìlẹ̀kẹ̀ ṣẹ̀gi àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn (nípa ẹwà àti dídára wọn).
59Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
60Ǹjẹ́ ẹ̀san mìíràn wà fún ṣíṣe rere bí kò ṣe (ẹ̀san) rere.
61Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
62Ọgbà Ìdẹ̀ra méjì kan tún ń bẹ yàtọ̀ sí méjì (àkọ́kọ́ yẹn).
63Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
64Aláwọ̀ ewéko (ni Ọgbà méjèèjì náà).
65Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
66Àwọn odò méjì tó ń tú omi jáde láì dáwọ́ dúró wà (nínú ọgbà méjèèjì náà).
67Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
68Èso ìpanu, dàbínù àti èso rumọ̄n wà nínú ọgbà méjèèjì náà.
69Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
70Àwọn obìnrin rere, arẹwà wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra náà.
71Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
72Àwọn ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ kan (ni wọ́n), tí A fi pamọ́ sínú ilé-ọ̀ṣọ́.
73Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
74Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn.
75Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
76Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí àwọn tìmùtìmù aláwọ̀ ewéko àti ìtẹ́ tó dára.
77Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
78Ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé.