Al-Waqi'ah

الواقعة

The Event96 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِذَا وَقَعَتِ ٱلۡوَاقِعَةُ﴿١

1Nígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀,

لَيۡسَ لِوَقۡعَتِهَا كَاذِبَةٌ﴿٢

2- kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-

خَافِضَةٞ رَّافِعَةٌ﴿٣

3ó máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra).

إِذَا رُجَّتِ ٱلۡأَرۡضُ رَجّٗا﴿٤

4Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì,

وَبُسَّتِ ٱلۡجِبَالُ بَسّٗا﴿٥

5àti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú,

فَكَانَتۡ هَبَآءٗ مُّنۢبَثّٗا﴿٦

6- wọ́n sì máa di eruku àfẹ́dànù -

وَكُنتُمۡ أَزۡوَٰجٗا ثَلَٰثَةٗ﴿٧

7ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta.[1]

فَأَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ﴿٨

8Àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún?

وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشۡـَٔمَةِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشۡـَٔمَةِ﴿٩

9Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?

وَٱلسَّٰبِقُونَ ٱلسَّٰبِقُونَ﴿١٠

10Àwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú.

أُوْلَٰٓئِكَ ٱلۡمُقَرَّبُونَ﴿١١

11Àwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu)

فِي جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ﴿١٢

12nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.

ثُلَّةٞ مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ﴿١٣

13Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.

وَقَلِيلٞ مِّنَ ٱلۡأٓخِرِينَ﴿١٤

14Wọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.

عَلَىٰ سُرُرٖ مَّوۡضُونَةٖ﴿١٥

15(Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun.

مُّتَّكِـِٔينَ عَلَيۡهَا مُتَقَٰبِلِينَ﴿١٦

16Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn.

يَطُوفُ عَلَيۡهِمۡ وِلۡدَٰنٞ مُّخَلَّدُونَ﴿١٧

17Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn

بِأَكۡوَابٖ وَأَبَارِيقَ وَكَأۡسٖ مِّن مَّعِينٖ﴿١٨

18pẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn láti inú odò kan tó ń ṣàn (káà kiri ọ̀dọ̀ wọn).

لَّا يُصَدَّعُونَ عَنۡهَا وَلَا يُنزِفُونَ﴿١٩

19Kò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà.

وَفَٰكِهَةٖ مِّمَّا يَتَخَيَّرُونَ﴿٢٠

20Èso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn).

وَلَحۡمِ طَيۡرٖ مِّمَّا يَشۡتَهُونَ﴿٢١

21Àti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn).

وَحُورٌ عِينٞ﴿٢٢

22Àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ (tún wà fún wọn).

كَأَمۡثَٰلِ ٱللُّؤۡلُوِٕ ٱلۡمَكۡنُونِ﴿٢٣

23Wọ́n dà bí àlúùúlù (òkúta olówó-iye-bíye) tí wọ́n fi pamọ́ sínú apó rẹ̀.

جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ﴿٢٤

24(Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

لَا يَسۡمَعُونَ فِيهَا لَغۡوٗا وَلَا تَأۡثِيمًا﴿٢٥

25Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.

إِلَّا قِيلٗا سَلَٰمٗا سَلَٰمٗا﴿٢٦

26Àyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà.

وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡيَمِينِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلۡيَمِينِ﴿٢٧

27Àwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún?

فِي سِدۡرٖ مَّخۡضُودٖ﴿٢٨

28(Wọn yóò wà) ní ìdí igi tí kò ní ẹ̀gún,

وَطَلۡحٖ مَّنضُودٖ﴿٢٩

29àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ tó so jìgbìnnì,

وَظِلّٖ مَّمۡدُودٖ﴿٣٠

30àti ibòji tó gbòòrò,

وَمَآءٖ مَّسۡكُوبٖ﴿٣١

31àti omi tó ń ṣàn láì dáwọ́ dúró,

وَفَٰكِهَةٖ كَثِيرَةٖ﴿٣٢

32àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso,

لَّا مَقۡطُوعَةٖ وَلَا مَمۡنُوعَةٖ﴿٣٣

33tí kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn).

وَفُرُشٖ مَّرۡفُوعَةٍ﴿٣٤

34(Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè.

إِنَّآ أَنشَأۡنَٰهُنَّ إِنشَآءٗ﴿٣٥

35Dájúdájú Àwa dá (àwọn obìnrin Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní ẹ̀dá kan (tó yàtọ̀ sí tayé).

فَجَعَلۡنَٰهُنَّ أَبۡكَارًا﴿٣٦

36A sì ṣe wọ́n ní wúńdíá,

عُرُبًا أَتۡرَابٗا﴿٣٧

37olólùfẹ́ ọkọ. Wọ́n sì dọ́gba ní ọjọ́ orí.

لِّأَصۡحَٰبِ ٱلۡيَمِينِ﴿٣٨

38(Wọ́n wà) fún àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.

ثُلَّةٞ مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ﴿٣٩

39Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.

وَثُلَّةٞ مِّنَ ٱلۡأٓخِرِينَ﴿٤٠

40Wọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.[1]

وَأَصۡحَٰبُ ٱلشِّمَالِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلشِّمَالِ﴿٤١

41Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?

فِي سَمُومٖ وَحَمِيمٖ﴿٤٢

42(Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná (iná) àti omi tó gbóná parí,

وَظِلّٖ مِّن يَحۡمُومٖ﴿٤٣

43àti ní abẹ́ ibòji eléèéfín dúdú,

لَّا بَارِدٖ وَلَا كَرِيمٍ﴿٤٤

44kò tutù, kò sì dára.

إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَبۡلَ ذَٰلِكَ مُتۡرَفِينَ﴿٤٥

45Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn.

وَكَانُواْ يُصِرُّونَ عَلَى ٱلۡحِنثِ ٱلۡعَظِيمِ﴿٤٦

46Wọ́n sì máa ń ṣoríkunkun lórí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

وَكَانُواْ يَقُولُونَ أَئِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ﴿٤٧

47Wọ́n sì máa ń wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?

أَوَءَابَآؤُنَا ٱلۡأَوَّلُونَ﴿٤٨

48Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”

قُلۡ إِنَّ ٱلۡأَوَّلِينَ وَٱلۡأٓخِرِينَ﴿٤٩

49Sọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn,

لَمَجۡمُوعُونَ إِلَىٰ مِيقَٰتِ يَوۡمٖ مَّعۡلُومٖ﴿٥٠

50dájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀.”

ثُمَّ إِنَّكُمۡ أَيُّهَا ٱلضَّآلُّونَ ٱلۡمُكَذِّبُونَ﴿٥١

51Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́,

لَأٓكِلُونَ مِن شَجَرٖ مِّن زَقُّومٖ﴿٥٢

52dájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ).

فَمَالِـُٔونَ مِنۡهَا ٱلۡبُطُونَ﴿٥٣

53Ikùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà.

فَشَٰرِبُونَ عَلَيۡهِ مِنَ ٱلۡحَمِيمِ﴿٥٤

54Ẹ̀yin yó sì máa mu omi tó gbóná parí lé e lórí.

فَشَٰرِبُونَ شُرۡبَ ٱلۡهِيمِ﴿٥٥

55Ẹ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ.

هَٰذَا نُزُلُهُمۡ يَوۡمَ ٱلدِّينِ﴿٥٦

56Èyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san.

نَحۡنُ خَلَقۡنَٰكُمۡ فَلَوۡلَا تُصَدِّقُونَ﴿٥٧

57Àwa l’A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo!

أَفَرَءَيۡتُم مَّا تُمۡنُونَ﴿٥٨

58Ẹ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́),

ءَأَنتُمۡ تَخۡلُقُونَهُۥٓ أَمۡ نَحۡنُ ٱلۡخَٰلِقُونَ﴿٥٩

59ṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀?

نَحۡنُ قَدَّرۡنَا بَيۡنَكُمُ ٱلۡمَوۡتَ وَمَا نَحۡنُ بِمَسۡبُوقِينَ﴿٦٠

60Àwa l’A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara

عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ أَمۡثَٰلَكُمۡ وَنُنشِئَكُمۡ فِي مَا لَا تَعۡلَمُونَ﴿٦١

61láti yí irú yín padà (láti inú erùpẹ̀ sí alààyè), kí á sì ṣẹ̀dá yín (ní ọ̀tun) sínú ohun tí ẹ kò mọ̀ (nínú àwọn ìrísí).

وَلَقَدۡ عَلِمۡتُمُ ٱلنَّشۡأَةَ ٱلۡأُولَىٰ فَلَوۡلَا تَذَكَّرُونَ﴿٦٢

62Ẹ kúkú mọ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ (pé láti ibi àìsí ni ẹ ti di alààyè), ẹ kò ṣe lo ìrántí?

أَفَرَءَيۡتُم مَّا تَحۡرُثُونَ﴿٦٣

63Ẹ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀,

ءَأَنتُمۡ تَزۡرَعُونَهُۥٓ أَمۡ نَحۡنُ ٱلزَّٰرِعُونَ﴿٦٤

64ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde tàbí Àwa l’À ń jẹ́ kí ó hù jáde?

لَوۡ نَشَآءُ لَجَعَلۡنَٰهُ حُطَٰمٗا فَظَلۡتُمۡ تَفَكَّهُونَ﴿٦٥

65Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀).

إِنَّا لَمُغۡرَمُونَ﴿٦٦

66(Ẹ̀yin yó sì wí pé:) “Dájúdájú àwa ti di onígbèsè.”

بَلۡ نَحۡنُ مَحۡرُومُونَ﴿٦٧

67(Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) “Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni.”

أَفَرَءَيۡتُمُ ٱلۡمَآءَ ٱلَّذِي تَشۡرَبُونَ﴿٦٨

68Ẹ sọ fún mi nípa omi tí ẹ̀ ń mu,

ءَأَنتُمۡ أَنزَلۡتُمُوهُ مِنَ ٱلۡمُزۡنِ أَمۡ نَحۡنُ ٱلۡمُنزِلُونَ﴿٦٩

69ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l’À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀?

لَوۡ نَشَآءُ جَعَلۡنَٰهُ أُجَاجٗا فَلَوۡلَا تَشۡكُرُونَ﴿٧٠

70Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi tó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́?

أَفَرَءَيۡتُمُ ٱلنَّارَ ٱلَّتِي تُورُونَ﴿٧١

71Ẹ sọ fún Mi nípa iná tí ẹ̀ ń dá,

ءَأَنتُمۡ أَنشَأۡتُمۡ شَجَرَتَهَآ أَمۡ نَحۡنُ ٱلۡمُنشِـُٔونَ﴿٧٢

72ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá?

نَحۡنُ جَعَلۡنَٰهَا تَذۡكِرَةٗ وَمَتَٰعٗا لِّلۡمُقۡوِينَ﴿٧٣

73Àwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò.

فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ﴿٧٤

74Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.

۞ فَلَآ أُقۡسِمُ بِمَوَٰقِعِ ٱلنُّجُومِ﴿٧٥

75Nítorí náà, Mò ń fi àwọn àyè tí ìkọ̀ọ̀kan gbólóhùn al-Ƙur’ān wà nínú sánmọ̀ búra.[1]

وَإِنَّهُۥ لَقَسَمٞ لَّوۡ تَعۡلَمُونَ عَظِيمٌ﴿٧٦

76Dájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀.

إِنَّهُۥ لَقُرۡءَانٞ كَرِيمٞ﴿٧٧

77Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé.

فِي كِتَٰبٖ مَّكۡنُونٖ﴿٧٨

78Ó wà nínú Tírà kan tí wọ́n ń fi ààbò bò (ìyẹn Laohul-Mahfūṭḥ).

لَّا يَمَسُّهُۥٓ إِلَّا ٱلۡمُطَهَّرُونَ﴿٧٩

79Kò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika).

تَنزِيلٞ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ﴿٨٠

80Wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

أَفَبِهَٰذَا ٱلۡحَدِيثِ أَنتُم مُّدۡهِنُونَ﴿٨١

81Nítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí l’ẹ̀ ń pè ní irọ́?

وَتَجۡعَلُونَ رِزۡقَكُمۡ أَنَّكُمۡ تُكَذِّبُونَ﴿٨٢

82Ẹ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo ní irọ́.[1]

فَلَوۡلَآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلۡحُلۡقُومَ﴿٨٣

83Kí ni ó máa ti rí (fún yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun,

وَأَنتُمۡ حِينَئِذٖ تَنظُرُونَ﴿٨٤

84tí ẹ̀yin yó sì máa wò bọ̀ọ̀ nígbà yẹn?

وَنَحۡنُ أَقۡرَبُ إِلَيۡهِ مِنكُمۡ وَلَٰكِن لَّا تُبۡصِرُونَ﴿٨٥

85Àwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran.[1]

فَلَوۡلَآ إِن كُنتُمۡ غَيۡرَ مَدِينِينَ﴿٨٦

86Ẹ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀,

تَرۡجِعُونَهَآ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ﴿٨٧

87kí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.

فَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلۡمُقَرَّبِينَ﴿٨٨

88Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa),

فَرَوۡحٞ وَرَيۡحَانٞ وَجَنَّتُ نَعِيمٖ﴿٨٩

89ìsinmi, èsè tó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀).

وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡيَمِينِ﴿٩٠

90Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún,

فَسَلَٰمٞ لَّكَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡيَمِينِ﴿٩١

91àlàáfíà ni fún ọ láààrin àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.

وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلۡمُكَذِّبِينَ ٱلضَّآلِّينَ﴿٩٢

92Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn olùṣìnà,

فَنُزُلٞ مِّنۡ حَمِيمٖ﴿٩٣

93n̄ǹkan àlejò (wọn) ni omi tó gbóná parí

وَتَصۡلِيَةُ جَحِيمٍ﴿٩٤

94àti wíwọ inú iná Jẹhīm.

إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ حَقُّ ٱلۡيَقِينِ﴿٩٥

95Dájúdájú èyí, òhun ni òdodo tó dájú.

فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ﴿٩٦

96Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.

RELATED SURAHS