الأنبياء
The Prophets • 112 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Ìṣírò-iṣẹ́ súnmọ́ fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì wà nínú ìfọ́núfọ́ra, tí wọ́n ń gbúnrí (kúrò níbi òdodo).
2Kò sí ìrántí titun kan tí ó máa dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn àfi kí wọ́n gbọ́ ọ lẹ́ni tí yóò máa (fi) ṣeré.
3Wọ́n fọ́núfọ́ra ni. Àwọn tó ṣàbòsí sì fi ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ (ààrin ara wọn) pamọ́ pé: “Ṣé èyí tayọ abara bí irú yín ni? Ṣé ẹ máa tẹ̀lé idán ni, nígbà tí ẹ̀yin náà ríran?”
4Ó sọ pé: “Olúwa mi mọ ọ̀rọ̀ tó ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.”
5Rárá, wọ́n tún wí pé: “Àwọn àlá tí ó lọ́pọ̀ mọ́ra wọn tí kò ní ìtúmọ̀ ni (al-Ƙur’ān.” Wọ́n tún wí pé): “Rárá, ó hun ún ni.” (Wọ́n tún wí pé): “Rárá, eléwì ni. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) kí ó mú àmì kan wá fún wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi rán àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
6Kò sí àwọn tó gbàgbọ́ ṣíwájú wọn nínú àwọn ìlú tí A ti parẹ́ (lẹ́yìn ìsọ̀kalẹ̀ àmì). Ṣé àwọn sì máa gbàgbọ́ (nígbà tí àmì bá dé)?
7A kò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀.[1]
8A kò sì ṣe wọ́n ní abara tí kì í jẹun. Wọn kò sì jẹ́ olùṣegbére (nílé ayé).[1]
9Lẹ́yìn náà, A mú àdéhùn Wa ṣẹ fún wọn. A sì gba àwọn Òjíṣẹ́ àti àwọn tí A bá fẹ́ là. A sì pa àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà run.
10Dájúdájú A ti sọ tírà kan kalẹ̀ fún yín, tí ìrántí nípa ọ̀rọ̀ ara yín wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?
11Mélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́, tí ó jẹ́ alábòsí! A sì gbé àwọn ìjọ mìíràn dìde lẹ́yìn wọn.
12Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa (tó ń bọ̀), wọ́n sì ń sá lọ fún un.
13Ẹ má ṣe sá lọ. Ẹ padà síbi n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fún yín àti àwọn ibùgbé yín nítorí kí A lè bi yín ní ìbéèrè.
14Wọ́n wí pé: “Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”
15Igbe wọn yìí kò dúró títí A fi sọ wọ́n di koríko tí wọ́n gé, wọ́n sì dòkú kalẹ̀.
16Àwa kò dá sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe.
17Tí ó bá jẹ́ pé A gbèrò láti ṣèré ni, ọ̀dọ̀ Wa ni A kúkú tí máa ṣe é tí A bá jẹ́ olùṣe-(eré).
18Rárá o! À ń sọ òdodo lu irọ́ (mọ́lẹ̀ ni). Òdodo sì máa fọ́ agbárí irọ́. Irọ́ sì máa pòórá. Ègbé sì ni fún yín nípa ohun tí ẹ ń fi ròyìn (Rẹ̀ ní ti irọ́).
19TiRẹ̀ ni àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àti pé àwọn tó ń bẹ lọ́dọ̀ Rẹ̀, wọn kì í ṣègbéraga níbi ìjọ́sìn Rẹ̀. Kò sì rẹ̀ wọ́n.
20Wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ ní òru àti ní ọ̀sán; wọn kò sì sinmi.
21Tàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan tí wọ́n mú jáde láti ara ilẹ̀, tí wọ́n ń jí òkú dìde ni?
22Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan wà nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ lẹ́yìn Allāhu, sánmọ̀ àti ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
23Wọn kò níí bi (Allāhu) ní ìbéèrè nípa n̄ǹkan tí Ó ń ṣe. Àwọn ni wọ́n máa bi ní ìbéèrè (nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn).
24Tàbí wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Sọ pé: “Ẹ mú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ yín wa.” (Al-Ƙur’ān) yìí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn tó wà pẹ̀lú mi àti ọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ṣíwájú mi.[1] Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò mọ òdodo; wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀.
25A kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.”[1]
26Wọ́n wí pé: “Àjọkẹ́-ayé sọ ẹnì kan di ọmọ (nínú àwọn mọlāikah Rẹ̀).” Mímọ́ ni fún Un - Kò rí bẹ́ẹ̀; ẹrúsìn alápọ̀n-ọ́nlé ni wọ́n.
27Wọn kì í ṣíwájú Allāhu sọ ọ̀rọ̀. Wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀.
28(Allāhu) mọ ohun tó ń bẹ níwájú wọn àti ohun tó ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì níí ṣìpẹ̀ (ẹnì kan) àfi ẹni tí (Allāhu) bá yọ́nú sí. Wọ́n tún ń páyà fún ìbẹ̀rù Rẹ̀.
29Àti pé ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó bá wí pé: “Dájúdájú èmi ni ọlọ́hun lẹ́yìn Rẹ̀.” Nítorí ìyẹn sì ni A óò fi san án ní ẹ̀san iná Jahanamọ. Báyẹn sì ni A ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san.
30Ṣé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kò wòye pé dájúdájú àwọn sánmọ̀ lẹ̀pọ̀ àti ilẹ̀ náà lẹ̀pọ̀ tẹ́lẹ̀ ni, A sì yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, A sì ṣe gbogbo n̄ǹkan ní abẹ̀mí láti ara omi? Nítorí náà, ṣé wọn kò níí gbàgbọ́ ni?[1]
31A sì fi àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ́ wọn lẹ́sẹ̀. A sì fi àwọn ọ̀nà fífẹ̀ sáààrin àwọn àpáta nítorí kí wọ́n lè rí ọ̀nà tọ̀.
32A tún ṣe sánmọ̀ ní àjà tí wọ́n ń ṣọ́ (níbi jíjábọ́). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi àwọn àmì rẹ̀.
33Òun ni Ẹni tí Ó dá òru àti ọ̀sán pẹ̀lú òòrùn àti òṣùpá. Ìkọ̀ọ̀kan (òòrùn àti òṣùpá) wà ní òpópónà roboto tó ń tọ̀.
34A kò ṣe bíbẹ gbére fún abara kan ṣíwájú rẹ. Ǹjẹ́ tí o bá kú, àwọn sì ni olùṣegbére bí?[1]
35Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ló máa tọ́ ikú wò. A sì máa fi aburú àti rere ṣàdánwò fún yín. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí.
36Nígbà tí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ bá rí ọ, wọn kò sì níí kà ọ́ kún kiní kan bí kò ṣe oníyẹ̀yẹ́ pé: “Ṣé èyí ni ẹni tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ́hun yín?” Aláìgbàgbọ́ sì ni àwọn náà nípa ìrántí Àjọkẹ́-ayé.
37Wọ́n fi ìkánjú sínú àdámọ́ ènìyàn. Mo máa fi àwọn àmì Mi hàn yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe kán Mi lójú.
38Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
39Tí ó bá jẹ́ pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ mọ ìgbà tí wọn kò níí dá Iná dúró níwájú wọn àti ní ẹ̀yìn wọn, tí A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́, (wọn ìbá tí wá ìyà pẹ̀lú ìkánjú).
40Ṣùgbọ́n (ìyà Iná) yóò bá wọn ní òjijì, nígbà náà ó máa kó ìdààmú bá wọn; wọn kò sì níí lè dá a padà. A kò sì níí sún (ìyà náà) síwájú fún wọn.
41Wọ́n kúkú ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ! Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí àwọn tó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ po.
42Sọ pé: “Ta ni ẹni tí ó ń ṣọ yín ní òru àti ní ọ̀sán níbi ìyà Àjọkẹ́-ayé?” Àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí Olúwa wọn.
43Tàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan tó máa gbà wọ́n sílẹ̀ lẹ́yìn Wa ni? Wọn kò lè ran ara wọn lọ́wọ́. Wọn kò sì lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́dọ̀ Wa.
44Síbẹ̀síbẹ̀ A fún àwọn wọ̀nyí àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn títí ìṣẹ̀mí ayé wọn fi gùn. Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń mú ilẹ̀ dínkù (mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́) láti àwọn etí ìlú (wọnú ìlú nípa fífún àwọn mùsùlùmí ní ìṣẹ́gun lórí wọn). Nítorí náà, ṣé àwọn ni wọ́n máa borí ni?
45Sọ pé: “Ìmísí ni mo fi ń kìlọ̀ fún yín. Àwọn adití kò sì níí gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá ń kìlọ̀ fún wọn.”
46Àti pé dájúdájú tí abala kan nínú ìyà Olúwa rẹ bá fọwọ́ bà wọ́n, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò; dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”
47A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò.
48Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) Hārūn ní ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun tó ń ṣòpínyà láààrin òdodo àti irọ́), ìmọ́lẹ̀ àti ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).[1]
49(Àwọn ni) àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀. Olùpáyà sì ni wọ́n nípa Àkókò náà.
50Èyí sì ni ìrántí oníbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Ṣé ẹ̀yin yóò takò ó ni?
51Dájúdájú A ti fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní ìmọ̀nà tirẹ̀ ṣíwájú (kí ó tó dàgbà). Àwa sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀.
52(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀ pé: “Kí ni àwọn ère wọ̀nyí tí ẹ̀ ń dúró tì, tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ṣe jẹ́ ná?”
53Wọ́n wí pé: “A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń jọ́sìn fún wọn ni.”
54Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”
55Wọ́n wí pé: “Ṣé o mú òdodo wá fún wa ni tàbí ìwọ wà nínú àwọn ẹlẹ́fẹ̀.”
56Ó sọ pé: “Rárá. Olúwa yin ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; Ẹni tí Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá wọn. Èmi sì wà nínú àwọn ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.
57Àti pé mo fi Allāhu búra, dájúdájú mo máa dète sí àwọn òrìṣà yín lẹ́yìn tí ẹ bá pẹ̀yìn dà, tí ẹ lọ.”
58Ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ àfi àgbà (òrìṣà) wọn nítorí kí wọ́n lè padà dé bá a.
59Wọ́n wí pé: “Ta ni ó ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa? Dájúdájú onítọ̀un wà nínú àwọn alábòsí.”
60Wọ́n wí pé: “A gbọ́ tí ọ̀dọ́kùnrin kan ń bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n. Wọ́n ń pe (ọmọ náà) ní ’Ibrọ̄hīm.”
61Wọ́n wí pé: “Ẹ mú un wá han àwọn ènìyàn kí wọ́n lè jẹ́rìí lé e lórí.”
62Wọ́n wí pé: “Ṣé ìwọ lo ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa, ’Ibrọ̄hīm?”
63Ó sọ pé: “Rárá o, àgbà wọn yìí ló ṣe (wọ́n bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, ẹ bi wọ́n léèrè wò tí wọ́n bá máa ń sọ̀rọ̀.”[1]
64Nígbà náà, wọ́n yíjú síra wọn, wọ́n sì wí pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ni alábòsí.”
65Lẹ́yìn náà, wọ́n sorí kọ́ (wọ́n sì wí pé): “Ìwọ náà kúkú mọ̀ pé àwọn wọ̀nyí kì í sọ̀rọ̀.”
66Ó sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí kò lè ṣe yín ní àǹfààní kiní kan, tí kò sì lè kó ìnira kan bá yín lẹ́yìn Allāhu?
67Ṣíọ̀ ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, ṣé ẹ̀yin kò níí ṣe làákàyè ni?"
68Wọ́n wí pé: “Ẹ dáná sun ún; kí ẹ sì ran àwọn ọlọ́hun yín lọ́wọ́, tí ẹ̀yin bá níkan-án ṣe.”
69A sọ pé: “Iná, di tútù àti àlàáfíà lára ’Ibrọ̄hīm.”
70Wọ́n gbèrò ète sí i, ṣùgbọ́n A ṣe wọ́n ní olófò jùlọ.
71A sì gba òun àti Lūt là sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí fún gbogbo ẹ̀dá.
72A ta á ní ọrẹ ọmọ, ’Is-hāƙ àti Ya‘ƙūb tí ó jẹ́ àlékún (ìyẹn, ọmọọmọ). Olúkùlùkù (wọn) ni A ṣe ní ẹni rere.
73A ṣe wọ́n ní aṣíwájú tó ń tọ́ àwọn ènìyàn sí ọ̀nà pẹ̀lú àṣẹ Wa. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí wọn nípa ṣíṣe iṣẹ́ rere, ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Wọ́n sì jẹ́ olùjọ́sìn fún Wa.
74(Ẹ rántí Ànábì) Lūt. A fún un ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì gbà á là nínú ìlú tí wọ́n ti ń ṣe àwọn iṣẹ́ burúkú. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú, òbìlẹ̀jẹ́.
75A sì mú un wọ inú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹni rere.
76(Ẹ rántí Ànábì) Nūh, nígbà tí ó pe ìpè ṣíwájú. A sì jẹ́pè rẹ̀. A sì gba òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ là nínú ìbànújẹ́ ńlá.
77A sì ṣàrànṣe fún un lórí àwọn ènìyàn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú. A sì tẹ̀ wọ́n rì pátápátá.
78(Ẹ rántí Ànábì) Dāwūd àti (Ànábì) Sulaemọ̄n, (rántí) nígbà tí àwọn méjèèjì ń ṣe ìdájọ́ lórí (ọ̀rọ̀) oko, nígbà tí àgùtàn ìjọ kan jẹko wọ inú oko náà. Àwa sì jẹ́ Olùjẹ́rìí sí ìdájọ́ wọn.
79A sì fún (Ànábì) Sulaemọ̄n ní àgbọ́yé rẹ̀. Àti pé ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ni A fún ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì tẹ àwọn àpáta àti ẹyẹ ba; wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) pẹ̀lú (Ànábì) Dāwūd. Àwa l’A ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀.
80A tún fún un ní ìmọ̀ nípa ṣíṣe ẹ̀wù irin fún yín nítorí kí ó lè jẹ́ odi ìṣọ́ fún yín níbi ogun yín. Nítorí náà, ǹjẹ́ olùdúpẹ́ (fún Allāhu) ni ẹ̀yin bí?
81A sì tẹ atẹ́gùn líle lórí ba fún (Ànábì) Sulaemọ̄n. Ó ń gbé e lọ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí. A sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
82Nínú àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n, àwọn tó ń wa kùsà òkun tún wà fún un. Wọ́n tún ń ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn. Àwa sì ń jẹ́ Olùṣọ́ fún wọn.
83(Ẹ rántí Ànábì) ’Ayyūb, nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Dájúdájú ọwọ́ ìnira ti kàn mí. Ìwọ sì ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú.”
84A sì jẹ́pè rẹ̀. A mú gbogbo ìnira rẹ̀ kúrò fún un. A tún fún un ní àwọn ẹbí rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn; (ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn olùjọ́sìn (fún Wa).
85(Ẹ rántí Ànábì) ’Ismọ̄‘īl àti (Ànábì) ’Idrīs àti (Ànábì) Thul-Kifl; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) wà nínú àwọn onísùúrù.
86A sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni rere.
87(Ẹ rántí) ẹlẹ́ja, nígbà tí ó bá ìbínú lọ, ó sì lérò pé A ò níí gbá òun mú. Ó sì pe (Olúwa rẹ̀) nínú àwọn òkùnkùn (inú ẹja) pé: "Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ìwọ (Allāhu). Mímọ́ ni fún Ọ. Dájúdájú èmi wà nínú àwọn alábòsí.”[1]
88A jẹ́pè rẹ̀. A sì gbà á là nínú ìbànújẹ́. Báyẹn ni A ṣe ń gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là.
89(Ẹ rántí Ànábì) Zakariyyā nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Olúwa mi, má fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan (tí kò níí bímọ). Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùjogún.”[1]
90A jẹ́pè rẹ̀. A sì ta á lọ́rẹ ọmọ, (Ànábì) Yahyā. A sì ṣe àtúnṣe ìyàwó rẹ̀ fún un. Dájúdájú wọ́n ń yára gágá níbi àwọn iṣẹ́ rere. Wọ́n ń pè Wá pẹ̀lú ìrètí àti ìpáyà. Wọ́n sì jẹ́ olùtẹríba fún Wa.
91(Ẹ rántí obìnrin) èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn nínú àwọn atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá sí i lára. A sì ṣe òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá.[1]
92Dájúdájú (’Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.
93(Àwọn ènìyàn) sì dá ọ̀rọ̀ (ẹ̀sìn) wọn sí kélekèle láààrin ara wọn; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) sì máa padà sí ọ̀dọ̀ Wa.
94Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kò sí kíkọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀. Àti pé dájúdájú Àwa máa ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún un.
95Èèwọ̀ ni fún ará ìlú kan tí A ti parẹ́ (pé kí ó tún padà sí ayé); dájúdájú wọn kò níí padà mọ́ (sí ilé ayé).
96(Wọn yóò wà nínú barsaku) títí A óò fi ṣí àwọn Ya’jūj àti Ma’jūj sílẹ̀. Àwọn (wọ̀nyí) yó sì máa sáré jáde láti inú gbogbo àyè gíga.
97Àdéhùn òdodo náà súnmọ́ pẹ́kípẹ́kí. Nígbà náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò máa ranjú kalẹ̀ ràngàndàn, (wọ́n yó sì wí pé): “Ègbé ni fún wa! Dájúdájú àwa ti wà nínú ìgbàgbéra nípa èyí. Rárá, àwa jẹ́ alábòsí ni.”
98Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ni ìkoná Jahanamọ; ẹ̀yin yó sì wọ inú rẹ̀.
99Tí ó bá jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí ni ọlọ́hun ni, wọn ìbá tí wọ inú Iná. Olùṣegbére sì ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nínú rẹ̀.
100Iná yóò máa kùn yùn-ùn sí wọn létí; wọn kò sì níí gbọ́ (ọ̀rọ̀ mìíràn).
101Dájúdájú àwọn tí rere ti ṣíwájú fún láti ọ̀dọ̀ Wa, àwọn wọ̀nyẹn ni A óò gbé jìnnà sí Iná.
102Wọn kò sì níí gbọ́ kíkùn rẹ̀. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú ìgbádùn tí ẹ̀mí wọn ń fẹ́.
103Ìpáyà tó tóbi jùlọ kò níí bà wọ́n nínú jẹ́. Àwọn mọlāika yóò máa pàdé wọn, (wọn yóò sọ pé): “Èyí ni ọjọ́ yín tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín.”
104(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí A máa ká sánmọ̀ bíi kíká ewé tírà.[1] Gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ (ibẹ̀ náà ni) A óò dá a padà sí. (Ó jẹ́) àdéhùn tí A ṣe. Dájúdájú Àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀.
105Àti pé A ti kọ ọ́ sínú àwọn ìpín-ìpín Tírà (tí A sọ̀kalẹ̀) lẹ́yìn (èyí tí ó wà nínú) Tírà Ìpìlẹ̀ (ìyẹn, Laohul- Mahfūṭḥ) pé dájúdájú ilẹ̀ (ìyẹn ilẹ̀ Ọgbà Ìdẹ̀ra),[1] àwọn ẹrúsìn Mi, àwọn ẹni rere, ni wọn yóò jogún rẹ̀.
106Dájúdájú ohun tí ó máa tó ẹ̀dá (nípa ọ̀rọ̀ ayé àti ọ̀rọ̀ ọ̀run)[1] wà nínú (al-Ƙur’ān) yìí fún ìjọ tó ń jọ́sìn (fún Allāhu ní ọ̀nà òdodo).
107A kò sì fi iṣẹ́ ìmísí rán ọ bí kò ṣe pé kí o lè jẹ́ ìkẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá.
108Sọ pé: “Ohun tí Wọ́n ń fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí ni pé, Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ṣé ẹ̀yin máa di mùsùlùmí?”
109Tí wọ́n bá gbúnrí, sọ nígbà náà pé: “Èmi ń fi to yín létí pé èmi àti ẹ̀yin dìjọ dá dúró fún ogun ẹ̀sìn (tí ó máa ṣẹlẹ̀ láààrin wa báyìí). Èmi kò sì mọ̀ bóyá ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín ti súnmọ́ tàbí ó sì jìnnà.
110Dájúdájú (Allāhu) mọ ohun tí ó hàn nínú ọ̀rọ̀. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.
111Èmi kò sì mọ̀ bóyá (lílọ́ yín lára) máa jẹ́ àdánwò àti ìgbádùn fún yín títí di ìgbà díẹ̀.”
112Ó sọ pé: “Olúwa mi, ṣèdájọ́ pẹ̀lú òdodo. Olúwa wa ni Àjọkẹ́-ayé, Ẹni tí à ń wá àánú Rẹ̀ lórí ohun tí ẹ̀ ń fi ròyìn (Rẹ̀).”[1]