Al-Mutaffifin

المطففين

The Defrauders36 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَيۡلٞ لِّلۡمُطَفِّفِينَ﴿١

1Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù,

ٱلَّذِينَ إِذَا ٱكۡتَالُواْ عَلَى ٱلنَّاسِ يَسۡتَوۡفُونَ﴿٢

2àwọn (òǹtajà) tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn,[1] wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún,

وَإِذَا كَالُوهُمۡ أَو وَّزَنُوهُمۡ يُخۡسِرُونَ﴿٣

3nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù.

أَلَا يَظُنُّ أُوْلَٰٓئِكَ أَنَّهُم مَّبۡعُوثُونَ﴿٤

4Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde

لِيَوۡمٍ عَظِيمٖ﴿٥

5ní Ọjọ́ ńlá kan?

يَوۡمَ يَقُومُ ٱلنَّاسُ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ﴿٦

6Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde dúró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡفُجَّارِ لَفِي سِجِّينٖ﴿٧

7Ní ti òdodo dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni burúkú (tó ń dín òṣùwọ̀n kù) kúkú máa wà nínú Sijjīn.

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا سِجِّينٞ﴿٨

8Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Sijjīn!

كِتَٰبٞ مَّرۡقُومٞ﴿٩

9Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn).

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ﴿١٠

10Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́,

ٱلَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ﴿١١

11àwọn tó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.

وَمَا يُكَذِّبُ بِهِۦٓ إِلَّا كُلُّ مُعۡتَدٍ أَثِيمٍ﴿١٢

12Kò sì sí ẹni tó ń pè é ní irọ́ àyàfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀.

إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ﴿١٣

13Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí).”

كَلَّاۖ بَلۡۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ﴿١٤

14Rárá (al-Ƙur’ān kì í ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́) bí kò ṣe pé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ aburú l’ó jọba lórí ọkàn wọn.

كَلَّآ إِنَّهُمۡ عَن رَّبِّهِمۡ يَوۡمَئِذٖ لَّمَحۡجُوبُونَ﴿١٥

15Rárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí sẹ́), dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn.

ثُمَّ إِنَّهُمۡ لَصَالُواْ ٱلۡجَحِيمِ﴿١٦

16Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm.

ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ﴿١٧

17Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: “Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.”

كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡأَبۡرَارِ لَفِي عِلِّيِّينَ﴿١٨

18Ní ti òdodo, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn.

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا عِلِّيُّونَ﴿١٩

19Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ‘illiyyūn!

كِتَٰبٞ مَّرۡقُومٞ﴿٢٠

20Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn).

يَشۡهَدُهُ ٱلۡمُقَرَّبُونَ﴿٢١

21Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i.

إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٍ﴿٢٢

22Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn.

عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ﴿٢٣

23Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.

تَعۡرِفُ فِي وُجُوهِهِمۡ نَضۡرَةَ ٱلنَّعِيمِ﴿٢٤

24Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn.

يُسۡقَوۡنَ مِن رَّحِيقٖ مَّخۡتُومٍ﴿٢٥

25Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí.

خِتَٰمُهُۥ مِسۡكٞۚ وَفِي ذَٰلِكَ فَلۡيَتَنَافَسِ ٱلۡمُتَنَٰفِسُونَ﴿٢٦

26Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn.

وَمِزَاجُهُۥ مِن تَسۡنِيمٍ﴿٢٧

27Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà).

عَيۡنٗا يَشۡرَبُ بِهَا ٱلۡمُقَرَّبُونَ﴿٢٨

28(Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu.

إِنَّ ٱلَّذِينَ أَجۡرَمُواْ كَانُواْ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يَضۡحَكُونَ﴿٢٩

29Dájúdájú àwọn tó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín.

وَإِذَا مَرُّواْ بِهِمۡ يَتَغَامَزُونَ﴿٣٠

30Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn olùdẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́.

وَإِذَا ٱنقَلَبُوٓاْ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمُ ٱنقَلَبُواْ فَكِهِينَ﴿٣١

31Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí.

وَإِذَا رَأَوۡهُمۡ قَالُوٓاْ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَضَآلُّونَ﴿٣٢

32Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà.”

وَمَآ أُرۡسِلُواْ عَلَيۡهِمۡ حَٰفِظِينَ﴿٣٣

33Àwa kò sì rán wọn ní iṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn.

فَٱلۡيَوۡمَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنَ ٱلۡكُفَّارِ يَضۡحَكُونَ﴿٣٤

34Nítorí náà, ní òní àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín.

عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ﴿٣٥

35Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.

هَلۡ ثُوِّبَ ٱلۡكُفَّارُ مَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ﴿٣٦

36Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)?

RELATED SURAHS