Al-Infitar

الانفطار

The Cleaving19 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتۡ﴿١

1Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,[1]

وَإِذَا ٱلۡكَوَاكِبُ ٱنتَثَرَتۡ﴿٢

2àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,

وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ فُجِّرَتۡ﴿٣

3àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,

وَإِذَا ٱلۡقُبُورُ بُعۡثِرَتۡ﴿٤

4àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,

عَلِمَتۡ نَفۡسٞ مَّا قَدَّمَتۡ وَأَخَّرَتۡ﴿٥

5(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).

يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡإِنسَٰنُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ ٱلۡكَرِيمِ﴿٦

6Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,

ٱلَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّىٰكَ فَعَدَلَكَ﴿٧

7Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.

فِيٓ أَيِّ صُورَةٖ مَّا شَآءَ رَكَّبَكَ﴿٨

8Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.

كَلَّا بَلۡ تُكَذِّبُونَ بِٱلدِّينِ﴿٩

9Rárá! Bí kò ṣe pé ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.

وَإِنَّ عَلَيۡكُمۡ لَحَٰفِظِينَ﴿١٠

10Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.

كِرَامٗا كَٰتِبِينَ﴿١١

11(Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.

يَعۡلَمُونَ مَا تَفۡعَلُونَ﴿١٢

12Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٖ﴿١٣

13Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.

وَإِنَّ ٱلۡفُجَّارَ لَفِي جَحِيمٖ﴿١٤

14Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.

يَصۡلَوۡنَهَا يَوۡمَ ٱلدِّينِ﴿١٥

15Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.

وَمَا هُمۡ عَنۡهَا بِغَآئِبِينَ﴿١٦

16Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀.

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ﴿١٧

17Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?

ثُمَّ مَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ﴿١٨

18Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?

يَوۡمَ لَا تَمۡلِكُ نَفۡسٞ لِّنَفۡسٖ شَيۡـٔٗاۖ وَٱلۡأَمۡرُ يَوۡمَئِذٖ لِّلَّهِ﴿١٩

19(Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.

RELATED SURAHS