At-Takwir

التكوير

The Overthrowing29 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِذَا ٱلشَّمۡسُ كُوِّرَتۡ﴿١

1Nígbà tí wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,

وَإِذَا ٱلنُّجُومُ ٱنكَدَرَتۡ﴿٢

2àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,

وَإِذَا ٱلۡجِبَالُ سُيِّرَتۡ﴿٣

3àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),

وَإِذَا ٱلۡعِشَارُ عُطِّلَتۡ﴿٤

4àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,

وَإِذَا ٱلۡوُحُوشُ حُشِرَتۡ﴿٥

5àti nígbà tí wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,

وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ سُجِّرَتۡ﴿٦

6àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,

وَإِذَا ٱلنُّفُوسُ زُوِّجَتۡ﴿٧

7àti nígbà tí wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)

وَإِذَا ٱلۡمَوۡءُۥدَةُ سُئِلَتۡ﴿٨

8àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé

بِأَيِّ ذَنۢبٖ قُتِلَتۡ﴿٩

9ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún,

وَإِذَا ٱلصُّحُفُ نُشِرَتۡ﴿١٠

10àti nígbà tí wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀,

وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ كُشِطَتۡ﴿١١

11àti nígbà tí wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè,

وَإِذَا ٱلۡجَحِيمُ سُعِّرَتۡ﴿١٢

12àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò,

وَإِذَا ٱلۡجَنَّةُ أُزۡلِفَتۡ﴿١٣

13àti nígbà tí wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo),

عَلِمَتۡ نَفۡسٞ مَّآ أَحۡضَرَتۡ﴿١٤

14(nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi).

فَلَآ أُقۡسِمُ بِٱلۡخُنَّسِ﴿١٥

15Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwọn ìràwọ̀ tó ń yọ ní alẹ́, tó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán búra,

ٱلۡجَوَارِ ٱلۡكُنَّسِ﴿١٦

16(ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ tó ń rìn lọ rìn bọ̀, tó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn.

وَٱلَّيۡلِ إِذَا عَسۡعَسَ﴿١٧

17Mo tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.[1]

وَٱلصُّبۡحِ إِذَا تَنَفَّسَ﴿١٨

18Mo tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀ búra.

إِنَّهُۥ لَقَوۡلُ رَسُولٖ كَرِيمٖ﴿١٩

19Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé,[1]

ذِي قُوَّةٍ عِندَ ذِي ٱلۡعَرۡشِ مَكِينٖ﴿٢٠

20alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá,

مُّطَاعٖ ثَمَّ أَمِينٖ﴿٢١

21ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán.

وَمَا صَاحِبُكُم بِمَجۡنُونٖ﴿٢٢

22Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe wèrè.

وَلَقَدۡ رَءَاهُ بِٱلۡأُفُقِ ٱلۡمُبِينِ﴿٢٣

23Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere.[1]

وَمَا هُوَ عَلَى ٱلۡغَيۡبِ بِضَنِينٖ﴿٢٤

24Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i).

وَمَا هُوَ بِقَوۡلِ شَيۡطَٰنٖ رَّجِيمٖ﴿٢٥

25Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) aṣ-Ṣaetọ̄n, ẹni ẹ̀kọ̀.

فَأَيۡنَ تَذۡهَبُونَ﴿٢٦

26Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ?

إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرٞ لِّلۡعَٰلَمِينَ﴿٢٧

27Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.

لِمَن شَآءَ مِنكُمۡ أَن يَسۡتَقِيمَ﴿٢٨

28(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé.

وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ﴿٢٩

29Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

RELATED SURAHS