عبس
He Frowned • 42 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Ó fajú ro, ó sì pẹ̀yìndà[1]
2nítorí pé afọ́jú wá bá a.
3Kí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)
4tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní?
5Ní ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀,
6òun ni ìwọ tẹ́tí sí.
7Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́).
8Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, tó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú),
9tí ó sì ń páyà (Allāhu),
10ìwọ kò sì kọbi ara sí i.
11Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
12Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀.
13(Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé,
14A gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́
15ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika),
16àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere.
17Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ!
18Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀?
19Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀.
20Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un.
21Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè.
22Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde.
23Rárá o! Ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un.
24Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀.
25Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀.
26Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn.
27A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀;
28àti èso àjàrà àti kànnáfùrù,
29àti igi òróró Zaetūn àti dàbínù,
30àti àwọn ọgbà tó kún fún igi,
31àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde).
32(Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
33Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀,
34ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀,
35àti ìyá rẹ̀ àti bàbá rẹ̀,
36àti ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
37Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn tó máa tó o ó rán.
38Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀.
39Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú.
40Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀.
41Òkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀.
42Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.