النازعات
Those Who Drag Forth • 46 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Allāhu fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́ búra.
2Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo búra.
3Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀ búra.
4Ó tún fi àwọn mọlāika tó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà búra.
5Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń ṣètò nínú sánmọ̀ àti ilé ayé pẹ̀lú àṣẹ Allāhu búra.
6Ní ọjọ́ tí ìmìtìtì máa mi gbogbo ayé tìtì.[1]
7Ohun tí ó máa tẹ̀lé e máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e.[1]
8Àwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.
9Ojú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ.
10Wọn yóò wí pé: “Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)?
11Ṣé nígbà tí a ti di eegun tó kẹfun tán?”
12Wọ́n wí pé: “Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni tó pè é ní irọ́.)”
13Nítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni.
14Nígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa.
15Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
16(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonúfojì mímọ́, Tuwā.
17Lọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.
18Kí o sì sọ pé: “Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí?
19Kí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, kí o sì páyà (Rẹ̀).”
20Ó sì fi àmì tó tóbi hàn án.
21(Àmọ́) ó pè é ní òpùrọ́. Ó sì yapa (rẹ̀).
22Lẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó).
23Ó kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì.
24Ó sì wí pé: “Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ.”
25Nítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́).[1]
26Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).
27Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ?
28Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé tó gún régé.
29Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde.
30Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn.[1]
31Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀.
32Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin.
33Ìgbádùn ni fún yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
34Ṣùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé,
35ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun tó ṣe níṣẹ́.
36Wọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni tó ríran.
37Nítorí náà, ní ti ẹni tó tayọ ẹnu-ààlà,
38tí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé,
39dájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
40Ní ti ẹni tí ó páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀),
41dájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
42Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: “Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀?”
43Níbo ni ìwọ wà sí ìmọ̀ rẹ̀ ná?[1]
44Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà.
45Ìwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni tó ń páyà rẹ̀.
46Ní ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan.