المدثر
The Cloaked One • 56 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Ìwọ olùdaṣọbora.
2Dìde kí o ṣèkìlọ̀.
3Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún.
4Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́.
5Òrìṣà ni kí o jìnnà sí.
6Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà.
7Olúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún.
8Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde,
9ìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira,
10tí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́.
11Fi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan (ìyẹn nínú ikùn ìyá rẹ̀).
12Mo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá
13àti àwọn ọmọkúnrin tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.
14Mo sì fi àyè ìrọ̀rùn gbá a dáadáa.
15Lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún.
16Rárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa.
17Èmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná)[1].
18Dájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀).
19Wọ́n sì ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
20Lẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
21Lẹ́yìn náà, ó wò sùn.
22Lẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí.
23Lẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìndà, ó sì ṣègbéraga.
24Ó sì wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́.
25Kí ni èyí bí kò ṣe ọ̀rọ̀ abara”
26Èmi yóò fi sínú iná Saƙọr.
27Kí l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ iná Saƙọr?
28(Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì.[1]
29Ó máa jó awọ ara di dúdú.
30(Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
31Àwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika. Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: “Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara.
32Ẹ gbọ́! Allāhu fi òṣùpá búra.
33Ó tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.
34Ó tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́ búra.
35Dájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) tó tóbi.
36(Ó jẹ́) ìkìlọ̀ fún abara.
37Fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn (nínú ẹ̀ṣẹ̀).
38Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun tó ṣe níṣẹ́.
39Àyàfi àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
40Wọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra
41nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pé:
42“Kí ni ó mu yín wọ inú iná Saƙọr?”
43Wọn yóò wí pé: “Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni.
44Àwa kò sì sí nínú àwọn tó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
45Àwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ.
46Àti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́
47títí ikú fi dé bá wa.”
48Ìpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní.
49Kí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí
50bí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń sá lọ,
51tó sá fún kìnìhún?
52Rárá, ńṣe ni ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān).
53Rárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni.
54Ẹ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
55Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó rántí rẹ̀.
56Wọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì ni àforíjìn.