Al-Mursalat

المرسلات

Those Sent Forth50 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلۡمُرۡسَلَٰتِ عُرۡفٗا﴿١

1Allāhu fi àwọn atẹ́gùn tó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé búra.

فَٱلۡعَٰصِفَٰتِ عَصۡفٗا﴿٢

2Ó fi àwọn ìjì atẹ́gùn tó ń jà búra.

وَٱلنَّٰشِرَٰتِ نَشۡرٗا﴿٣

3Ó fi àwọn atẹ́gùn tó ń tú èṣújò ká búra.

فَٱلۡفَٰرِقَٰتِ فَرۡقٗا﴿٤

4Ó fi àwọn tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́ búra.

فَٱلۡمُلۡقِيَٰتِ ذِكۡرًا﴿٥

5Ó fi àwọn mọlāika tó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́) búra.

عُذۡرًا أَوۡ نُذۡرًا﴿٦

6(Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀.

إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَوَٰقِعٞ﴿٧

7Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fún yín kúkú máa ṣẹlẹ̀.

فَإِذَا ٱلنُّجُومُ طُمِسَتۡ﴿٨

8Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́,

وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ فُرِجَتۡ﴿٩

9àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada,

وَإِذَا ٱلۡجِبَالُ نُسِفَتۡ﴿١٠

10àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù,

وَإِذَا ٱلرُّسُلُ أُقِّتَتۡ﴿١١

11àti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ (pẹ̀lú ìjọ wọn),

لِأَيِّ يَوۡمٍ أُجِّلَتۡ﴿١٢

12ọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná?

لِيَوۡمِ ٱلۡفَصۡلِ﴿١٣

13Fún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni.

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِ﴿١٤

14Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà?

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ﴿١٥

15Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

أَلَمۡ نُهۡلِكِ ٱلۡأَوَّلِينَ﴿١٦

16Ǹjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí?

ثُمَّ نُتۡبِعُهُمُ ٱلۡأٓخِرِينَ﴿١٧

17Lẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun).

كَذَٰلِكَ نَفۡعَلُ بِٱلۡمُجۡرِمِينَ﴿١٨

18Báyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ﴿١٩

19Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

أَلَمۡ نَخۡلُقكُّم مِّن مَّآءٖ مَّهِينٖ﴿٢٠

20Ṣé A kò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí?

فَجَعَلۡنَٰهُ فِي قَرَارٖ مَّكِينٍ﴿٢١

21Lẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ)

إِلَىٰ قَدَرٖ مَّعۡلُومٖ﴿٢٢

22títí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ).

فَقَدَرۡنَا فَنِعۡمَ ٱلۡقَٰدِرُونَ﴿٢٣

23A sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀. Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá tó dára.

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ﴿٢٤

24Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

أَلَمۡ نَجۡعَلِ ٱلۡأَرۡضَ كِفَاتًا﴿٢٥

25Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun tó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn;

أَحۡيَآءٗ وَأَمۡوَٰتٗا﴿٢٦

26(ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú?

وَجَعَلۡنَا فِيهَا رَوَٰسِيَ شَٰمِخَٰتٖ وَأَسۡقَيۡنَٰكُم مَّآءٗ فُرَاتٗا﴿٢٧

27A sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fún yín ní omi dídùn mu.

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ﴿٢٨

28Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

ٱنطَلِقُوٓاْ إِلَىٰ مَا كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ﴿٢٩

29Ẹ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.

ٱنطَلِقُوٓاْ إِلَىٰ ظِلّٖ ذِي ثَلَٰثِ شُعَبٖ﴿٣٠

30Ẹ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta.

لَّا ظَلِيلٖ وَلَا يُغۡنِي مِنَ ٱللَّهَبِ﴿٣١

31Kì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná.

إِنَّهَا تَرۡمِي بِشَرَرٖ كَٱلۡقَصۡرِ﴿٣٢

32Dájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè tó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì.

كَأَنَّهُۥ جِمَٰلَتٞ صُفۡرٞ﴿٣٣

33(Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn.

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ﴿٣٤

34Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

هَٰذَا يَوۡمُ لَا يَنطِقُونَ﴿٣٥

35Èyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀.

وَلَا يُؤۡذَنُ لَهُمۡ فَيَعۡتَذِرُونَ﴿٣٦

36A kò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá.

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ﴿٣٧

37Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

هَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِۖ جَمَعۡنَٰكُمۡ وَٱلۡأَوَّلِينَ﴿٣٨

38Èyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ.

فَإِن كَانَ لَكُمۡ كَيۡدٞ فَكِيدُونِ﴿٣٩

39Tí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò.

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ﴿٤٠

40Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي ظِلَٰلٖ وَعُيُونٖ﴿٤١

41Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú,

وَفَوَٰكِهَ مِمَّا يَشۡتَهُونَ﴿٤٢

42àti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́.

كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ هَنِيٓـَٔۢا بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ﴿٤٣

43Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ﴿٤٤

44Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ﴿٤٥

45Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

كُلُواْ وَتَمَتَّعُواْ قَلِيلًا إِنَّكُم مُّجۡرِمُونَ﴿٤٦

46Ẹ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ﴿٤٧

47Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱرۡكَعُواْ لَا يَرۡكَعُونَ﴿٤٨

48Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun.

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ﴿٤٩

49Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

فَبِأَيِّ حَدِيثِۭ بَعۡدَهُۥ يُؤۡمِنُونَ﴿٥٠

50Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?[1]

RELATED SURAHS