Al-Insan

الإنسان

Man31 ayahsMedinan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

هَلۡ أَتَىٰ عَلَى ٱلۡإِنسَٰنِ حِينٞ مِّنَ ٱلدَّهۡرِ لَمۡ يَكُن شَيۡـٔٗا مَّذۡكُورًا﴿١

1Ṣebí àkókò kan nínú ìgbà ti ré kọjá lórí ènìyàn tí (ènìyàn) kò jẹ́ kiní kan tí wọ́n ń dárúkọ?

إِنَّا خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِن نُّطۡفَةٍ أَمۡشَاجٖ نَّبۡتَلِيهِ فَجَعَلۡنَٰهُ سَمِيعَۢا بَصِيرًا﴿٢

2Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara àtọ̀ tó ròpọ̀ mọ́ra wọn (láti ara ọkùnrin àti obìnrin), A sì máa dán an wò.[1] A sì ṣe é ní olùgbọ́, olùríran.

إِنَّا هَدَيۡنَٰهُ ٱلسَّبِيلَ إِمَّا شَاكِرٗا وَإِمَّا كَفُورًا﴿٣

3Dájúdájú A fi ọ̀nà mọ̀ ọ́n; Ó lè jẹ́ olùdúpẹ́, ó sì lè jẹ́ aláìmoore.

إِنَّآ أَعۡتَدۡنَا لِلۡكَٰفِرِينَ سَلَٰسِلَاْ وَأَغۡلَٰلٗا وَسَعِيرًا﴿٤

4Dájúdájú Àwa pèsè àwọn ẹ̀wọ̀n, àjàgà àti Iná sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ يَشۡرَبُونَ مِن كَأۡسٖ كَانَ مِزَاجُهَا كَافُورًا﴿٥

5Dájúdájú àwọn ẹni rere, wọn yóò máa mu omi kan nínú ife. Ohun tí A pòpọ̀ mọ́ (omi náà) ni káfúrà.

عَيۡنٗا يَشۡرَبُ بِهَا عِبَادُ ٱللَّهِ يُفَجِّرُونَهَا تَفۡجِيرٗا﴿٦

6Omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan ni, tí àwọn ẹrúsìn Allāhu yóò máa mu, tí wọn yó sì máa mú un ṣàn jáde dáadáa (ní ibi tí wọ́n bá ti fẹ́ ẹ).

يُوفُونَ بِٱلنَّذۡرِ وَيَخَافُونَ يَوۡمٗا كَانَ شَرُّهُۥ مُسۡتَطِيرٗا﴿٧

7Wọ́n ń mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ. Wọ́n sì ń páyà ọjọ́ kan, tí aburú rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa fọ́nká gan-an.

وَيُطۡعِمُونَ ٱلطَّعَامَ عَلَىٰ حُبِّهِۦ مِسۡكِينٗا وَيَتِيمٗا وَأَسِيرًا﴿٨

8Tòhun ti bí wọ́n ṣe ní ìfẹ́ sí (ọrọ̀ tó), wọ́n ń fún mẹ̀kúnnù, ọmọ òrukàn àti ẹrú ní oúnjẹ jẹ.

إِنَّمَا نُطۡعِمُكُمۡ لِوَجۡهِ ٱللَّهِ لَا نُرِيدُ مِنكُمۡ جَزَآءٗ وَلَا شُكُورًا﴿٩

9(Wọ́n sì ń sọ pé:) “Nítorí Ojú rere Allāhu (nìkan) l’a fi ń fun yín ní oúnjẹ jẹ; àwa kò sì gbèrò ẹ̀san tàbí ìdúpẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ yín.

إِنَّا نَخَافُ مِن رَّبِّنَا يَوۡمًا عَبُوسٗا قَمۡطَرِيرٗا﴿١٠

10Dájúdájú àwa ń páyà ọjọ́ kan tí (ẹ̀dá yóò) fajú ro kókó ní ọ̀dọ̀ Olúwa wa.”

فَوَقَىٰهُمُ ٱللَّهُ شَرَّ ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمِ وَلَقَّىٰهُمۡ نَضۡرَةٗ وَسُرُورٗا﴿١١

11Nítorí náà, Allāhu yóò ṣọ́ wọn níbi aburú ọjọ́ yẹn. Ó sì máa fún wọn ni ìtutù ojú àti ìdùnnú.

وَجَزَىٰهُم بِمَا صَبَرُواْ جَنَّةٗ وَحَرِيرٗا﴿١٢

12Ó sì máa san wọ́n ní ẹ̀san Ọgbà Ìdẹ̀ra àti aṣọ àlàárì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù.

مُّتَّكِـِٔينَ فِيهَا عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِۖ لَا يَرَوۡنَ فِيهَا شَمۡسٗا وَلَا زَمۡهَرِيرٗا﴿١٣

13Wọn yóò máa rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn wọn. Wọn kò sì níí rí òòrùn tàbí òtútù.

وَدَانِيَةً عَلَيۡهِمۡ ظِلَٰلُهَا وَذُلِّلَتۡ قُطُوفُهَا تَذۡلِيلٗا﴿١٤

14Àwọn ibòji (inú Ọgbà Ìdẹ̀ra) yóò súnmọ́ wọn. A sì máa mú àwọn esò ibẹ̀ súnmọ́ àrọ́wọ́tó wọn ní ti sísúnmọ́.

وَيُطَافُ عَلَيۡهِم بِـَٔانِيَةٖ مِّن فِضَّةٖ وَأَكۡوَابٖ كَانَتۡ قَوَارِيرَا۠﴿١٥

15Àti pé wọn yóò máa gbé ife ìmumi ńlá tí wọ́n ṣe láti ara fàdákà àti àwọn ife ìmumi kékeré tí ó jẹ́ aláwo káà kiri ọ̀dọ̀ wọn.

قَوَارِيرَاْ مِن فِضَّةٖ قَدَّرُوهَا تَقۡدِيرٗا﴿١٦

16Ife aláwo tí wọ́n ṣe láti ara fàdákà ni (wọ́n). A sì ṣe wọ́n níwọ̀n- níwọ̀n (tí ó ṣe wẹ́kú ohun tí wọ́n fẹ́ mu).

وَيُسۡقَوۡنَ فِيهَا كَأۡسٗا كَانَ مِزَاجُهَا زَنجَبِيلًا﴿١٧

17Àti pé wọn yóò máa fún wọn ní ife ọtí kan mu nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). Ohun tí A pòpọ̀ mọ́ (ọtí náà) ni atalẹ̀.

عَيۡنٗا فِيهَا تُسَمَّىٰ سَلۡسَبِيلٗا﴿١٨

18Nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra (wọn yóò tún máa mu) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí À ń pè ní omi salsabīl.

۞ وَيَطُوفُ عَلَيۡهِمۡ وِلۡدَٰنٞ مُّخَلَّدُونَ إِذَا رَأَيۡتَهُمۡ حَسِبۡتَهُمۡ لُؤۡلُؤٗا مَّنثُورٗا﴿١٩

19Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí gbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. Nígbà tí ìwọ bá sì rí wọn, ìwọ yóò kà wọ́n kún òkúta olówó iyebíye tí wọ́n fọ́n kalẹ̀.

وَإِذَا رَأَيۡتَ ثَمَّ رَأَيۡتَ نَعِيمٗا وَمُلۡكٗا كَبِيرًا﴿٢٠

20Nígbà tí ìwọ bá sì wo ibẹ̀ yẹn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra), ìwọ yóò rí ìdẹ̀ra àti ọlá tó tóbi.

عَٰلِيَهُمۡ ثِيَابُ سُندُسٍ خُضۡرٞ وَإِسۡتَبۡرَقٞۖ وَحُلُّوٓاْ أَسَاوِرَ مِن فِضَّةٖ وَسَقَىٰهُمۡ رَبُّهُمۡ شَرَابٗا طَهُورًا﴿٢١

21Aṣọ àlàárì fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláwọ̀ ewéko àti aṣọ àlàárì tó nípọn máa wà lókè wọn (àti lára wọn). A sì máa fi ẹ̀gbà-ọwọ́ onífàdákà ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́. Olúwa wọn yó sì fún wọn ní ohun mímu mímọ́ mu.

إِنَّ هَٰذَا كَانَ لَكُمۡ جَزَآءٗ وَكَانَ سَعۡيُكُم مَّشۡكُورًا﴿٢٢

22Dájúdájú èyí jẹ́ ẹ̀san fun yín. Wọ́n sì máa fi ẹ̀san rere àdìpèlé dúpẹ́ iṣẹ́ yín fun yín.

إِنَّا نَحۡنُ نَزَّلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡقُرۡءَانَ تَنزِيلٗا﴿٢٣

23Dájúdájú Àwa l’A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ díẹ̀ díẹ̀.[1]

فَٱصۡبِرۡ لِحُكۡمِ رَبِّكَ وَلَا تُطِعۡ مِنۡهُمۡ ءَاثِمًا أَوۡ كَفُورٗا﴿٢٤

24Nítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Má ṣe tẹ̀lé ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí aláìmoore kan nínú wọn.

وَٱذۡكُرِ ٱسۡمَ رَبِّكَ بُكۡرَةٗ وَأَصِيلٗا﴿٢٥

25Rántí orúkọ Olúwa rẹ ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.

وَمِنَ ٱلَّيۡلِ فَٱسۡجُدۡ لَهُۥ وَسَبِّحۡهُ لَيۡلٗا طَوِيلًا﴿٢٦

26Àti ní òru, forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì ṣàfọ̀mọ́ fún Un ní òru fún ìgbà pípẹ́.

إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ يُحِبُّونَ ٱلۡعَاجِلَةَ وَيَذَرُونَ وَرَآءَهُمۡ يَوۡمٗا ثَقِيلٗا﴿٢٧

27Dájúdájú àwọn wọ̀nyí fẹ́ràn ayé. Wọ́n sì ń pa ọjọ́ tó wúwo tì sẹ́yìn wọn.

نَّحۡنُ خَلَقۡنَٰهُمۡ وَشَدَدۡنَآ أَسۡرَهُمۡۖ وَإِذَا شِئۡنَا بَدَّلۡنَآ أَمۡثَٰلَهُمۡ تَبۡدِيلًا﴿٢٨

28Àwa l’A ṣẹ̀dá wọn. A sì ṣe ìṣẹ̀dá wọn dáradára. Nígbà tí A bá sì fẹ́, A óò fi irú wọn pààrọ̀ wọn ní ti ìpààrọ̀.

إِنَّ هَٰذِهِۦ تَذۡكِرَةٞۖ فَمَن شَآءَ ٱتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ سَبِيلٗا﴿٢٩

29Dájúdájú èyí ni ìrántí. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ojú ọ̀nà tọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.

وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا﴿٣٠

30Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (kiní kan) àfi tí Allāhu bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.[1]

يُدۡخِلُ مَن يَشَآءُ فِي رَحۡمَتِهِۦۚ وَٱلظَّٰلِمِينَ أَعَدَّ لَهُمۡ عَذَابًا أَلِيمَۢا﴿٣١

31Ó máa fi ẹni tí ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ rẹ̀. (Ní ti) àwọn alábòsí, Ó sì pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ dè wọ́n.

RELATED SURAHS