Al-Qiyamah

القيامة

The Resurrection40 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

لَآ أُقۡسِمُ بِيَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ﴿١

1Èmi (Allāhu) ń fi Ọjọ́ Àjíǹde búra.

وَلَآ أُقۡسِمُ بِٱلنَّفۡسِ ٱللَّوَّامَةِ﴿٢

2Mo tún ń fi ẹ̀mí tó máa dá ara rẹ̀ ní ẹ̀bi búra.

أَيَحۡسَبُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَلَّن نَّجۡمَعَ عِظَامَهُۥ﴿٣

3Ṣé ènìyàn lérò pé A kò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni?

بَلَىٰ قَٰدِرِينَ عَلَىٰٓ أَن نُّسَوِّيَ بَنَانَهُۥ﴿٤

4Rárá. (À ń jẹ́) Alágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba.

بَلۡ يُرِيدُ ٱلۡإِنسَٰنُ لِيَفۡجُرَ أَمَامَهُۥ﴿٥

5Rárá ènìyàn fẹ́ máa ṣe aburú lọ bẹ́ẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀

يَسۡـَٔلُ أَيَّانَ يَوۡمُ ٱلۡقِيَٰمَةِ﴿٦

6ni ó fi ń bèèrè pé: “Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde?”

فَإِذَا بَرِقَ ٱلۡبَصَرُ﴿٧

7Nígbà tí ojú bá rí ìdààmú tó sì yà sílẹ̀ tí kò lè padé,

وَخَسَفَ ٱلۡقَمَرُ﴿٨

8àti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn,

وَجُمِعَ ٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُ﴿٩

9àti (nígbà) tí wọ́n bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn tí ìmọ́lẹ̀ méjèèjì pòóró,

يَقُولُ ٱلۡإِنسَٰنُ يَوۡمَئِذٍ أَيۡنَ ٱلۡمَفَرُّ﴿١٠

10ènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: “Níbo ni ibùsásí wà?”

كَلَّا لَا وَزَرَ﴿١١

11Rárá, kò sí ibùsásí.

إِلَىٰ رَبِّكَ يَوۡمَئِذٍ ٱلۡمُسۡتَقَرُّ﴿١٢

12Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn.

يُنَبَّؤُاْ ٱلۡإِنسَٰنُ يَوۡمَئِذِۭ بِمَا قَدَّمَ وَأَخَّرَ﴿١٣

13Wọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun tó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).

بَلِ ٱلۡإِنسَٰنُ عَلَىٰ نَفۡسِهِۦ بَصِيرَةٞ﴿١٤

14Ṣebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀,

وَلَوۡ أَلۡقَىٰ مَعَاذِيرَهُۥ﴿١٥

15ìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá.

لَا تُحَرِّكۡ بِهِۦ لِسَانَكَ لِتَعۡجَلَ بِهِۦٓ﴿١٦

16Má ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e.

إِنَّ عَلَيۡنَا جَمۡعَهُۥ وَقُرۡءَانَهُۥ﴿١٧

17Dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀.

فَإِذَا قَرَأۡنَٰهُ فَٱتَّبِعۡ قُرۡءَانَهُۥ﴿١٨

18Nígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀.

ثُمَّ إِنَّ عَلَيۡنَا بَيَانَهُۥ﴿١٩

19Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ.

كَلَّا بَلۡ تُحِبُّونَ ٱلۡعَاجِلَةَ﴿٢٠

20Kò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé ni.

وَتَذَرُونَ ٱلۡأٓخِرَةَ﴿٢١

21Ẹ sì ń gbé ọ̀run jù sílẹ̀.

وُجُوهٞ يَوۡمَئِذٖ نَّاضِرَةٌ﴿٢٢

22Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú).

إِلَىٰ رَبِّهَا نَاظِرَةٞ﴿٢٣

23Olúwa wọn ni wọn yóò máa wò.

وَوُجُوهٞ يَوۡمَئِذِۭ بَاسِرَةٞ﴿٢٤

24Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́.

تَظُنُّ أَن يُفۡعَلَ بِهَا فَاقِرَةٞ﴿٢٥

25(Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé wọ́n máa fi aburú kan òhun.

كَلَّآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلتَّرَاقِيَ﴿٢٦

26Kò rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò.

وَقِيلَ مَنۡۜ رَاقٖ﴿٢٧

27A sì máa sọ pé: “Ǹjẹ́ olùpọfọ̀ kan wà bí (tí ó máa pọfọ̀ láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú)?

وَظَنَّ أَنَّهُ ٱلۡفِرَاقُ﴿٢٨

28Ó sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé.

وَٱلۡتَفَّتِ ٱلسَّاقُ بِٱلسَّاقِ﴿٢٩

29Ojúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun.

إِلَىٰ رَبِّكَ يَوۡمَئِذٍ ٱلۡمَسَاقُ﴿٣٠

30Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn.

فَلَا صَدَّقَ وَلَا صَلَّىٰ﴿٣١

31Kò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun.

وَلَٰكِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ﴿٣٢

32Ṣùgbọ́n ó pe òdodo ní irọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i.

ثُمَّ ذَهَبَ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ يَتَمَطَّىٰٓ﴿٣٣

33Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí.

أَوۡلَىٰ لَكَ فَأَوۡلَىٰ﴿٣٤

34(Ìparun nílé ayé) ló tọ́ sí ọ jùlọ (lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ wọ̀nyẹn). (Ìyẹn) ló sì tọ́ sí ọ jùlọ.

ثُمَّ أَوۡلَىٰ لَكَ فَأَوۡلَىٰٓ﴿٣٥

35Lẹ́yìn náà, (Iná) ló tọ́ sí ọ jùlọ (ní ọ̀run). (Ìyẹn) ló sì tọ́ sí ọ jùlọ.

أَيَحۡسَبُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَن يُتۡرَكَ سُدًى﴿٣٦

36Ṣé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni?

أَلَمۡ يَكُ نُطۡفَةٗ مِّن مَّنِيّٖ يُمۡنَىٰ﴿٣٧

37Ṣé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni?

ثُمَّ كَانَ عَلَقَةٗ فَخَلَقَ فَسَوَّىٰ﴿٣٨

38Lẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é tó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn.

فَجَعَلَ مِنۡهُ ٱلزَّوۡجَيۡنِ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰٓ﴿٣٩

39(Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti ara rẹ̀, akọ àti abo.

أَلَيۡسَ ذَٰلِكَ بِقَٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يُحۡـِۧيَ ٱلۡمَوۡتَىٰ﴿٤٠

40Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí?

RELATED SURAHS