Al-Furqan

الفرقان

The Criterion77 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

تَبَارَكَ ٱلَّذِي نَزَّلَ ٱلۡفُرۡقَانَ عَلَىٰ عَبۡدِهِۦ لِيَكُونَ لِلۡعَٰلَمِينَ نَذِيرًا﴿١

1Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun tó ń ṣe ìpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ fún gbogbo ẹ̀dá.

ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَمۡ يَتَّخِذۡ وَلَدٗا وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ شَرِيكٞ فِي ٱلۡمُلۡكِ وَخَلَقَ كُلَّ شَيۡءٖ فَقَدَّرَهُۥ تَقۡدِيرٗا﴿٢

2(Òun ni) Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò mú ẹnì kan kan ní ọmọ. Kò sí akẹgbẹ́ fún Un nínú ìjọba (Rẹ̀). Ó dá gbogbo n̄ǹkan. Ó sì yan òdíwọ̀n (ìrísí, ìṣẹ̀mí àti àyànmọ́) fún un níwọ̀n-níwọ̀n.

وَٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةٗ لَّا يَخۡلُقُونَ شَيۡـٔٗا وَهُمۡ يُخۡلَقُونَ وَلَا يَمۡلِكُونَ لِأَنفُسِهِمۡ ضَرّٗا وَلَا نَفۡعٗا وَلَا يَمۡلِكُونَ مَوۡتٗا وَلَا حَيَوٰةٗ وَلَا نُشُورٗا﴿٣

3(Àwọn aláìgbàgbọ́) sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu, àwọn tí kò lè dá n̄ǹkan kan, A sì dá wọn ni. Wọn kò sì ní ìkápá ìnira tàbí àǹfààní kan fún ẹ̀mí ara wọn. Àti pé wọn kò ní ìkápá lórí ikú, ìṣẹ̀mí àti àjíǹde.

وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّآ إِفۡكٌ ٱفۡتَرَىٰهُ وَأَعَانَهُۥ عَلَيۡهِ قَوۡمٌ ءَاخَرُونَۖ فَقَدۡ جَآءُو ظُلۡمٗا وَزُورٗا﴿٤

4Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àdápa irọ́ kan tí ó dá àdápa rẹ̀ (mọ́ Allāhu), tí àwọn ènìyàn mìíràn sì ràn án lọ́wọ́ lórí rẹ̀.” Dájúdájú (àwọn aláìgbàgbọ́) ti gbé àbòsí àti irọ́ dé.

وَقَالُوٓاْ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ ٱكۡتَتَبَهَا فَهِيَ تُمۡلَىٰ عَلَيۡهِ بُكۡرَةٗ وَأَصِيلٗا﴿٥

5Wọ́n tún wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́, tí ó ṣàdàkọ rẹ̀ ni. Òhun ni wọ́n ń pè fún un ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.”

قُلۡ أَنزَلَهُ ٱلَّذِي يَعۡلَمُ ٱلسِّرَّ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّهُۥ كَانَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا﴿٦

6Sọ pé: “Ẹni tí Ó mọ ìkọ̀kọ̀ tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ l’Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀. Dájúdájú Òun ni Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”

وَقَالُواْ مَالِ هَٰذَا ٱلرَّسُولِ يَأۡكُلُ ٱلطَّعَامَ وَيَمۡشِي فِي ٱلۡأَسۡوَاقِ لَوۡلَآ أُنزِلَ إِلَيۡهِ مَلَكٞ فَيَكُونَ مَعَهُۥ نَذِيرًا﴿٧

7Wọ́n tún wí pé: “Kí ló mú Òjíṣẹ́ yìí, tó ń jẹun, tó ń rìn nínú àwọn ọjà? Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún un kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ pẹ̀lú rẹ̀?

أَوۡ يُلۡقَىٰٓ إِلَيۡهِ كَنزٌ أَوۡ تَكُونُ لَهُۥ جَنَّةٞ يَأۡكُلُ مِنۡهَاۚ وَقَالَ ٱلظَّٰلِمُونَ إِن تَتَّبِعُونَ إِلَّا رَجُلٗا مَّسۡحُورًا﴿٨

8Tàbí (nítorí kí ni) wọn kò ṣe ju àpótí-ọrọ̀ kan sọ́dọ̀ rẹ̀, tàbí kí ó ní ọgbà oko kan tí ó ma máa jẹ nínú rẹ̀?” Àwọn alábòsí sì tún wí pé: “Ta ni ẹ̀ ń tẹ̀lé bí kò ṣe ọkùnrin eléèdì kan.”

ٱنظُرۡ كَيۡفَ ضَرَبُواْ لَكَ ٱلۡأَمۡثَٰلَ فَضَلُّواْ فَلَا يَسۡتَطِيعُونَ سَبِيلٗا﴿٩

9Wo bí wọ́n ṣe fún ọ ní àwọn àfiwé (burúkú)! Nítorí náà, wọ́n ti ṣìnà; wọn kò sì lè mọ̀nà.

تَبَارَكَ ٱلَّذِيٓ إِن شَآءَ جَعَلَ لَكَ خَيۡرٗا مِّن ذَٰلِكَ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ وَيَجۡعَل لَّكَ قُصُورَۢا﴿١٠

10Ìbùkún ni fún Ẹni tí (ó jẹ́ pé) bí Ó bá fẹ́, Ó máa ṣoore tó dára ju ìyẹn fún ọ. (Ó sì máa jẹ́) àwọn ọgbà tí àwọn odò yóò máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ó sì máa fún ọ ni àwọn ààfin kan.

بَلۡ كَذَّبُواْ بِٱلسَّاعَةِۖ وَأَعۡتَدۡنَا لِمَن كَذَّبَ بِٱلسَّاعَةِ سَعِيرًا﴿١١

11Ńṣe ni wọ́n pe Àkókò náà nírọ́. A sì ti pèsè Iná tó ń jo sílẹ̀ de ẹnikẹ́ni tí ó bá pe Àkókò náà nírọ́.

إِذَا رَأَتۡهُم مِّن مَّكَانِۭ بَعِيدٖ سَمِعُواْ لَهَا تَغَيُّظٗا وَزَفِيرٗا﴿١٢

12Nígbà tí (Iná náà) bá rí wọn láti àyè kan tí ó jìnnà, wọn yó sì máa gbọ́ ohùn ìbínú àti kíkùn (rẹ̀).

وَإِذَآ أُلۡقُواْ مِنۡهَا مَكَانٗا ضَيِّقٗا مُّقَرَّنِينَ دَعَوۡاْ هُنَالِكَ ثُبُورٗا﴿١٣

13Nígbà tí wọ́n bá sì jù wọ́n sí àyè tó há gádígádí nínú (Iná), tí wọ́n de ọwọ́ wọn mọ́ wọn lọ́rùn, wọn yó sì máa kígbe ìparun níbẹ̀.

لَّا تَدۡعُواْ ٱلۡيَوۡمَ ثُبُورٗا وَٰحِدٗا وَٱدۡعُواْ ثُبُورٗا كَثِيرٗا﴿١٤

14(A ó sọ pé): “Ẹ má ṣe kígbe ìparun ẹyọ kan, ẹ kígbe ìparun lọ́pọ̀lọ́pọ̀.”

قُلۡ أَذَٰلِكَ خَيۡرٌ أَمۡ جَنَّةُ ٱلۡخُلۡدِ ٱلَّتِي وُعِدَ ٱلۡمُتَّقُونَۚ كَانَتۡ لَهُمۡ جَزَآءٗ وَمَصِيرٗا﴿١٥

15Sọ pé: “Ǹjẹ́ ìyẹn ló lóore jùlọ ni tàbí Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, èyí tí A ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu. Ó sì jẹ́ ẹ̀san àti ìkángun rere fún wọn.

لَّهُمۡ فِيهَا مَا يَشَآءُونَ خَٰلِدِينَۚ كَانَ عَلَىٰ رَبِّكَ وَعۡدٗا مَّسۡـُٔولٗا﴿١٦

16Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ wà fún wọn nínú rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n (nínú rẹ̀). (Èyí) jẹ́ àdéhùn tí wọ́n ti tọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.

وَيَوۡمَ يَحۡشُرُهُمۡ وَمَا يَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ فَيَقُولُ ءَأَنتُمۡ أَضۡلَلۡتُمۡ عِبَادِي هَٰٓؤُلَآءِ أَمۡ هُمۡ ضَلُّواْ ٱلسَّبِيلَ﴿١٧

17Àti pé (rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó àwọn abọ̀rìṣà àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu jọ, (Allāhu) yó sì sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣi àwọn ẹrúsìn Mi wọ̀nyí lọ́nà ni tàbí àwọn ni wọ́n ṣìnà (fúnra wọn)?”[1]

قَالُواْ سُبۡحَٰنَكَ مَا كَانَ يَنۢبَغِي لَنَآ أَن نَّتَّخِذَ مِن دُونِكَ مِنۡ أَوۡلِيَآءَ وَلَٰكِن مَّتَّعۡتَهُمۡ وَءَابَآءَهُمۡ حَتَّىٰ نَسُواْ ٱلذِّكۡرَ وَكَانُواْ قَوۡمَۢا بُورٗا﴿١٨

18Wọ́n wí pé: “Mímọ́ ni fún Ọ! Kò tọ́ fún wa láti mú àwọn kan ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Rẹ. Ṣùgbọ́n Ìwọ l’O fún àwọn àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn, títí wọ́n fi gbàgbé Ìrántí. Wọ́n sì jẹ́ ẹni ìparun.”

فَقَدۡ كَذَّبُوكُم بِمَا تَقُولُونَ فَمَا تَسۡتَطِيعُونَ صَرۡفٗا وَلَا نَصۡرٗاۚ وَمَن يَظۡلِم مِّنكُمۡ نُذِقۡهُ عَذَابٗا كَبِيرٗا﴿١٩

19(Allāhu sọ pé): “Dájúdájú àwọn òrìṣà ti pe ẹ̀yin abọ̀rìṣà ní òpùrọ́ nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ (pé olùṣìpẹ̀ ni wọ́n). Ní báyìí ẹ kò lè gbé ìyà Iná kúrò fún yín, ẹ kò sì lè ran ara yín lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣe àbòsí (ẹbọ ṣíṣe) nínú yín, A sì máa fún un ní ìyà tó tóbi tọ́ wò.”

وَمَآ أَرۡسَلۡنَا قَبۡلَكَ مِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ إِلَّآ إِنَّهُمۡ لَيَأۡكُلُونَ ٱلطَّعَامَ وَيَمۡشُونَ فِي ٱلۡأَسۡوَاقِۗ وَجَعَلۡنَا بَعۡضَكُمۡ لِبَعۡضٖ فِتۡنَةً أَتَصۡبِرُونَۗ وَكَانَ رَبُّكَ بَصِيرٗا﴿٢٠

20A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ rí ṣíwájú rẹ àfi kí wọ́n jẹun, kí wọ́n sì rìn nínú ọjà. A ti fi apá kan yín ṣe àdánwò fún apá kan, ǹjẹ́ ẹ máa ṣe sùúrù bí? Olúwa Rẹ sì ń jẹ́ Olùríran.

۞ وَقَالَ ٱلَّذِينَ لَا يَرۡجُونَ لِقَآءَنَا لَوۡلَآ أُنزِلَ عَلَيۡنَا ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ أَوۡ نَرَىٰ رَبَّنَاۗ لَقَدِ ٱسۡتَكۡبَرُواْ فِيٓ أَنفُسِهِمۡ وَعَتَوۡ عُتُوّٗا كَبِيرٗا﴿٢١

21Àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run) wí pé: “Wọn kò ṣe sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ fún wa tàbí kí á rí Olúwa wa (ní ojúkojú)? Dájúdájú wọ́n ti ṣègbéraga nínú ẹ̀mí wọn. Wọ́n sì ti tayọ ẹnu-ààlà ní ìtayọ ẹnu-ààlà tó tóbi.

يَوۡمَ يَرَوۡنَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ لَا بُشۡرَىٰ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُجۡرِمِينَ وَيَقُولُونَ حِجۡرٗا مَّحۡجُورٗا﴿٢٢

22Ní ọjọ́ tí wọ́n bá fi lè rí àwọn mọlāika, kò níí sí ìró ìdùnnú fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọjọ́ yẹn. (Àwọn mọlāika) yó sì sọ pé: “Èèwọ̀, èèwọ̀ (ni ìró ìdùnnú fún ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀).”

وَقَدِمۡنَآ إِلَىٰ مَا عَمِلُواْ مِنۡ عَمَلٖ فَجَعَلۡنَٰهُ هَبَآءٗ مَّنثُورًا﴿٢٣

23Àti pé A máa wá ṣíbi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa sọ ọ́ di eruku tí wọ́n fẹ́ dànù.

أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِ يَوۡمَئِذٍ خَيۡرٞ مُّسۡتَقَرّٗا وَأَحۡسَنُ مَقِيلٗا﴿٢٤

24Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ní ọjọ́ yẹn, (ọgbà wọn) máa lóore jùlọ ní ibùgbé. Ó sì máa dára jùlọ ní ibùsinmi.

وَيَوۡمَ تَشَقَّقُ ٱلسَّمَآءُ بِٱلۡغَمَٰمِ وَنُزِّلَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ تَنزِيلًا﴿٢٥

25Àti pé (rántí) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣújò funfun (tí yóò máa tú jáde nínú wọn).[1] A sì máa sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ tààrà.

ٱلۡمُلۡكُ يَوۡمَئِذٍ ٱلۡحَقُّ لِلرَّحۡمَٰنِۚ وَكَانَ يَوۡمًا عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ عَسِيرٗا﴿٢٦

26Ìjọba òdodo ti ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Àjọkẹ́-ayé. Ó sì jẹ́ ọjọ́ kan tí ó máa nira fún àwọn aláìgbàgbọ́.

وَيَوۡمَ يَعَضُّ ٱلظَّالِمُ عَلَىٰ يَدَيۡهِ يَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي ٱتَّخَذۡتُ مَعَ ٱلرَّسُولِ سَبِيلٗا﴿٢٧

27(Rántí) ọjọ́ tí alábòsí yóò jẹ ìka ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì, ó sì máa wí pé: “Yéè! Èmi ìbá ti tọ ọ̀nà kan (náà) pẹ̀lú Òjíṣẹ́ náà.

يَٰوَيۡلَتَىٰ لَيۡتَنِي لَمۡ أَتَّخِذۡ فُلَانًا خَلِيلٗا﴿٢٨

28Ègbé mi o, yéè! Èmi ìbá tí mú lágbájá ní ọ̀rẹ́ àyò.

لَّقَدۡ أَضَلَّنِي عَنِ ٱلذِّكۡرِ بَعۡدَ إِذۡ جَآءَنِيۗ وَكَانَ ٱلشَّيۡطَٰنُ لِلۡإِنسَٰنِ خَذُولٗا﴿٢٩

29Dájúdájú ó ti ṣì mí lọ́nà kúrò níbi Ìrántí lẹ́yìn tí ó dé bá mi. Dájúdájú aṣ-ṣaetọ̄n ń jẹ́ adáni-dáṣòro fún ọmọnìyàn.”

وَقَالَ ٱلرَّسُولُ يَٰرَبِّ إِنَّ قَوۡمِي ٱتَّخَذُواْ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ مَهۡجُورٗا﴿٣٠

30Òjíṣẹ́ náà sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pa al-Ƙur’ān yìí tì.”

وَكَذَٰلِكَ جَعَلۡنَا لِكُلِّ نَبِيٍّ عَدُوّٗا مِّنَ ٱلۡمُجۡرِمِينَۗ وَكَفَىٰ بِرَبِّكَ هَادِيٗا وَنَصِيرٗا﴿٣١

31Báyẹn ni A ṣe àwọn kan nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀tá fún Ànábì kọ̀ọ̀kan. Olúwa rẹ sì tó ní Afinimọ̀nà àti Alárànṣe.

وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوۡلَا نُزِّلَ عَلَيۡهِ ٱلۡقُرۡءَانُ جُمۡلَةٗ وَٰحِدَةٗۚ كَذَٰلِكَ لِنُثَبِّتَ بِهِۦ فُؤَادَكَۖ وَرَتَّلۡنَٰهُ تَرۡتِيلٗا﴿٣٢

32Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Wọn kò ṣe sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún un ní àpapọ̀ ní ẹ̀ẹ̀ kan náà?” (A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ díẹ̀díẹ̀) báyẹn nítorí kí A lè fi rinlẹ̀ sínú ọkàn rẹ. A sì ké e fún ọ díẹ̀díẹ̀.

وَلَا يَأۡتُونَكَ بِمَثَلٍ إِلَّا جِئۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ وَأَحۡسَنَ تَفۡسِيرًا﴿٣٣

33Wọn kò níí mú àpẹ̀ẹrẹ kan wá fún ọ (gẹ́gẹ́ bí ìbéèrè láti fi takò ọ́) àfi kí Á mú òdodo (ìyẹn, al-ƙur’ān) àti àlàyé tó dára jùlọ wá fún ọ (lórí rẹ̀).

ٱلَّذِينَ يُحۡشَرُونَ عَلَىٰ وُجُوهِهِمۡ إِلَىٰ جَهَنَّمَ أُوْلَٰٓئِكَ شَرّٞ مَّكَانٗا وَأَضَلُّ سَبِيلٗا﴿٣٤

34Àwọn tí A máa kó jọ lọ sínú iná Jahanamọ ní ìdojúbolẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àyè wọn burú jùlọ. Wọ́n sì ṣìnà jùlọ.

وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَجَعَلۡنَا مَعَهُۥٓ أَخَاهُ هَٰرُونَ وَزِيرٗا﴿٣٥

35Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A tún ṣe arákùnrin rẹ̀, Hārūn, ní amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún un.

فَقُلۡنَا ٱذۡهَبَآ إِلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا فَدَمَّرۡنَٰهُمۡ تَدۡمِيرٗا﴿٣٦

36A sì sọ pé: “Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ sọ́dọ̀ ìjọ tó pe àwọn āyah Wa nírọ́. A sì pa ìjọ náà run pátápátá.

وَقَوۡمَ نُوحٖ لَّمَّا كَذَّبُواْ ٱلرُّسُلَ أَغۡرَقۡنَٰهُمۡ وَجَعَلۡنَٰهُمۡ لِلنَّاسِ ءَايَةٗۖ وَأَعۡتَدۡنَا لِلظَّٰلِمِينَ عَذَابًا أَلِيمٗا﴿٣٧

37(Rántí) ìjọ (Ànábì) Nūh. Nígbà tí wọ́n pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́, A tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì kan fún àwọn ènìyàn. A sì ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn alábòsí.

وَعَادٗا وَثَمُودَاْ وَأَصۡحَٰبَ ٱلرَّسِّ وَقُرُونَۢا بَيۡنَ ذَٰلِكَ كَثِيرٗا﴿٣٨

38(Rántí) àwọn ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd, ìjọ Rass àti àwọn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran mìíràn (tó ń bẹ) láààrin wọn.

وَكُلّٗا ضَرَبۡنَا لَهُ ٱلۡأَمۡثَٰلَۖ وَكُلّٗا تَبَّرۡنَا تَتۡبِيرٗا﴿٣٩

39Ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A fún ní àwọn àpẹ̀ẹrẹ (gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí àti àlàyé ọ̀rọ̀). Ìkọ̀ọ̀kan wọn sì ni A parun pátápátá (torí àìgbàgbọ́ wọn).

وَلَقَدۡ أَتَوۡاْ عَلَى ٱلۡقَرۡيَةِ ٱلَّتِيٓ أُمۡطِرَتۡ مَطَرَ ٱلسَّوۡءِۚ أَفَلَمۡ يَكُونُواْ يَرَوۡنَهَاۚ بَلۡ كَانُواْ لَا يَرۡجُونَ نُشُورٗا﴿٤٠

40Àti pé dájúdájú àwọn náà kọjá ní ìlú tí A rọ òjò burúkú lé lórí. Ṣé wọn kì í rí i ni? Rárá, ńṣe ni wọn kò retí Àjíǹde.

وَإِذَا رَأَوۡكَ إِن يَتَّخِذُونَكَ إِلَّا هُزُوًا أَهَٰذَا ٱلَّذِي بَعَثَ ٱللَّهُ رَسُولًا﴿٤١

41Nígbà tí wọ́n bá sì rí ọ, kò sí ohun tí wọn yóò fi ọ́ ṣe bí kò ṣe yẹ̀yẹ́. (Wọ́n á wí pé): “Ṣé èyí ni ẹni tí Allāhu gbé dìde ní Òjíṣẹ́!?

إِن كَادَ لَيُضِلُّنَا عَنۡ ءَالِهَتِنَا لَوۡلَآ أَن صَبَرۡنَا عَلَيۡهَاۚ وَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ حِينَ يَرَوۡنَ ٱلۡعَذَابَ مَنۡ أَضَلُّ سَبِيلًا﴿٤٢

42Ó mà fẹ́ẹ̀ ṣẹ́rí wa kúrò níbi àwọn ọlọ́hun wa, tí kì í bá ṣe pé a takú sorí rẹ̀.” Láìpẹ́ wọn máa mọ ẹni tí ó ṣìnà jùlọ nígbà tí wọ́n bá rí ìyà.

أَرَءَيۡتَ مَنِ ٱتَّخَذَ إِلَٰهَهُۥ هَوَىٰهُ أَفَأَنتَ تَكُونُ عَلَيۡهِ وَكِيلًا﴿٤٣

43Sọ fún mi nípa ẹni tí ó sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ di ọlọ́hun rẹ̀! Nítorí náà, ṣé ìwọ máa jẹ́ aláàbò fún un ni (níbi ìyà)?

أَمۡ تَحۡسَبُ أَنَّ أَكۡثَرَهُمۡ يَسۡمَعُونَ أَوۡ يَعۡقِلُونَۚ إِنۡ هُمۡ إِلَّا كَٱلۡأَنۡعَٰمِ بَلۡ هُمۡ أَضَلُّ سَبِيلًا﴿٤٤

44Tàbí ìwọ ń rò pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ń gbọ́ràn tàbí pé wọ́n ń ṣe làákàyè? Kí ni wọ́n ná, bí kò ṣe bí àgùtàn. Rárá, wọ́n ṣìnà jùlọ.

أَلَمۡ تَرَ إِلَىٰ رَبِّكَ كَيۡفَ مَدَّ ٱلظِّلَّ وَلَوۡ شَآءَ لَجَعَلَهُۥ سَاكِنٗا ثُمَّ جَعَلۡنَا ٱلشَّمۡسَ عَلَيۡهِ دَلِيلٗا﴿٤٥

45Ṣé o ò rí (iṣẹ́) Olúwa rẹ ni, bí Ó ṣe fẹ òkùnkùn òwúrọ̀ lójú (sójú sánmọ̀)? Tí Ó bá fẹ́ ni, ìbá dá a dúró síbẹ̀. Lẹ́yìn náà, A fi òòrùn ṣe atọ́ka sí bíbẹ òkùnkùn.

ثُمَّ قَبَضۡنَٰهُ إِلَيۡنَا قَبۡضٗا يَسِيرٗا﴿٤٦

46Lẹ́yìn náà, A (fi ìmọ́lẹ̀ òòrùn) mú òkùnkùn (kúrò níta) wá sí ọ̀dọ̀ Wa ní mímú díẹ̀díẹ̀ (kí ojúmọ́ lè mọ́).

وَهُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ لِبَاسٗا وَٱلنَّوۡمَ سُبَاتٗا وَجَعَلَ ٱلنَّهَارَ نُشُورٗا﴿٤٧

47Àti pé Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òru ní ìbora fún yín. (Ó ṣe) oorun ní ìsinmi (fún yín). Ó tún ṣe ọ̀sán ní àsìkò ìtúsíta (fún wíwá ìjẹ-ìmu).

وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَرۡسَلَ ٱلرِّيَٰحَ بُشۡرَۢا بَيۡنَ يَدَيۡ رَحۡمَتِهِۦۚ وَأَنزَلۡنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ طَهُورٗا﴿٤٨

48Òun sì ni Ẹni t’Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró-ìdùnnú ṣíwájú ìkẹ́ Rẹ̀. A sì sọ omi mímọ́ kalẹ̀ láti sánmọ̀

لِّنُحۡـِۧيَ بِهِۦ بَلۡدَةٗ مَّيۡتٗا وَنُسۡقِيَهُۥ مِمَّا خَلَقۡنَآ أَنۡعَٰمٗا وَأَنَاسِيَّ كَثِيرٗا﴿٤٩

49nítorí kí A lè fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè ilẹ̀ àti nítorí kí A lè fún ẹran-ọ̀sìn àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn nínú àwọn tí A dá ní omi mu.

وَلَقَدۡ صَرَّفۡنَٰهُ بَيۡنَهُمۡ لِيَذَّكَّرُواْ فَأَبَىٰٓ أَكۡثَرُ ٱلنَّاسِ إِلَّا كُفُورٗا﴿٥٠

50Dájúdájú À ń darí omi yìí káàkiri láààrin wọn[1] nítorí kí wọ́n lè rántí (ìkẹ́ Olúwa wọn). Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kọ̀ (láti rántí) àfi àìmoore.

وَلَوۡ شِئۡنَا لَبَعَثۡنَا فِي كُلِّ قَرۡيَةٖ نَّذِيرٗا﴿٥١

51Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, A ìbá gbé olùkìlọ̀ kan dìde nínú ìlú kọ̀ọ̀kan.[1]

فَلَا تُطِعِ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَجَٰهِدۡهُم بِهِۦ جِهَادٗا كَبِيرٗا﴿٥٢

52Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́. Kí o sì fi (al-Ƙur’ān) jà wọ́n ní ogun tó tóbi.

۞ وَهُوَ ٱلَّذِي مَرَجَ ٱلۡبَحۡرَيۡنِ هَٰذَا عَذۡبٞ فُرَاتٞ وَهَٰذَا مِلۡحٌ أُجَاجٞ وَجَعَلَ بَيۡنَهُمَا بَرۡزَخٗا وَحِجۡرٗا مَّحۡجُورٗا﴿٥٣

53Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn odò méjì ṣàn kiri. Èyí (ni omi) tó dùn gan-an. Èyí sì (ni omi) iyọ̀ tó móró. Ó sì fi gàgá sí ààrin àwọn méjèèjì. (Ó sì) ṣe é ní èèwọ̀ pọ́nńbélé (fún wọn láti rò papọ̀ mọ́ra wọn).

وَهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ مِنَ ٱلۡمَآءِ بَشَرٗا فَجَعَلَهُۥ نَسَبٗا وَصِهۡرٗاۗ وَكَانَ رَبُّكَ قَدِيرٗا﴿٥٤

54Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá abara láti inú omi. Ó ṣe ìbátan ẹbí àti ìbátan àna fún un, Olúwa rẹ sì ń jẹ́ Alágbára.[1]

وَيَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُهُمۡ وَلَا يَضُرُّهُمۡۗ وَكَانَ ٱلۡكَافِرُ عَلَىٰ رَبِّهِۦ ظَهِيرٗا﴿٥٥

55Wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò lè ṣe wọ́n ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá wọn. Aláìgbàgbọ́ jẹ́ olùrànlọ́wọ́ (fún aṣ-ṣaetọ̄n) láti tako Olúwa rẹ̀.

وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا مُبَشِّرٗا وَنَذِيرٗا﴿٥٦

56A kò sì rán ọ níṣẹ́ tayọ kí o jẹ́ oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀.

قُلۡ مَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍ إِلَّا مَن شَآءَ أَن يَتَّخِذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ سَبِيلٗا﴿٥٧

57Sọ pé: “Èmi kò bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ yín lórí rẹ̀ àfi ẹni tí ó bá fẹ́ mú ọ̀nà (dáadáa) tọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.”[1]

وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱلۡحَيِّ ٱلَّذِي لَا يَمُوتُ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِهِۦۚ وَكَفَىٰ بِهِۦ بِذُنُوبِ عِبَادِهِۦ خَبِيرًا﴿٥٨

58Gbáralé Alààyè tí kò níí kú. Ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Un.[1] Allāhu sì tó ní Alámọ̀tán nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.

ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ ٱلرَّحۡمَٰنُ فَسۡـَٔلۡ بِهِۦ خَبِيرٗا﴿٥٩

59(Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti àwọn n̄ǹkan tó ń bẹ láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Àjọkẹ́-ayé ni, nítorí náà, bèèrè nípa Rẹ̀ (lọ́dọ̀ Rẹ̀ nítorí pé, Ó jẹ́) Alámọ̀tán.

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱسۡجُدُواْۤ لِلرَّحۡمَٰنِ قَالُواْ وَمَا ٱلرَّحۡمَٰنُ أَنَسۡجُدُ لِمَا تَأۡمُرُنَا وَزَادَهُمۡ نُفُورٗا۩﴿٦٠

60Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ fún Àjọkẹ́-ayé.” Wọ́n á wí pé: “Kí ni Àjọkẹ-ayé? Ṣé kí á forí kanlẹ̀ fún ohun tí ò ń pa wá láṣẹ rẹ̀ ni?” (Ìpèpè náà) sì mú wọn lékún ní sísá-sẹ́yìn.

تَبَارَكَ ٱلَّذِي جَعَلَ فِي ٱلسَّمَآءِ بُرُوجٗا وَجَعَلَ فِيهَا سِرَٰجٗا وَقَمَرٗا مُّنِيرٗا﴿٦١

61Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó ṣe àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ sínú sánmọ̀. Ó tún ṣe òòrùn àti òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú rẹ̀.

وَهُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ خِلۡفَةٗ لِّمَنۡ أَرَادَ أَن يَذَّكَّرَ أَوۡ أَرَادَ شُكُورٗا﴿٦٢

62Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òru àti ọ̀sán ní ìtẹ̀léǹtẹ̀lé (tí ìkíní yàtọ̀ sí ìkejì) nítorí ẹni tí ó bá gbèrò láti ṣe ìrántí (Allāhu) tàbí tí ó bá gbèrò ìdúpẹ́ (fún Un).

وَعِبَادُ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلَّذِينَ يَمۡشُونَ عَلَى ٱلۡأَرۡضِ هَوۡنٗا وَإِذَا خَاطَبَهُمُ ٱلۡجَٰهِلُونَ قَالُواْ سَلَٰمٗا﴿٦٣

63Àwọn ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé ni àwọn tó ń rìn jẹ́ẹ́jẹ́ lórí ilẹ̀. Nígbà tí àwọn òpè bá sì dojú ọ̀rọ̀ kọ wọ́n, wọn yóò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà.

وَٱلَّذِينَ يَبِيتُونَ لِرَبِّهِمۡ سُجَّدٗا وَقِيَٰمٗا﴿٦٤

64(Àwọn ni) àwọn tó ń lo òru wọn ní ìforíkanlẹ̀ àti ní ìdúró-kírun fún Olúwa wọn.

وَٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا ٱصۡرِفۡ عَنَّا عَذَابَ جَهَنَّمَۖ إِنَّ عَذَابَهَا كَانَ غَرَامًا﴿٦٥

65(Àwọn ni) àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, gbé ìyà iná Jahanamọ kúrò fún wa. Dájúdájú ìyà rẹ̀ jẹ́ ìyà àìnípẹ̀kun.

إِنَّهَا سَآءَتۡ مُسۡتَقَرّٗا وَمُقَامٗا﴿٦٦

66Dájúdájú ó burú ní ibùgbé àti ibùdúró.

وَٱلَّذِينَ إِذَآ أَنفَقُواْ لَمۡ يُسۡرِفُواْ وَلَمۡ يَقۡتُرُواْ وَكَانَ بَيۡنَ ذَٰلِكَ قَوَامٗا﴿٦٧

67Àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá náwó, wọn kò ná ìná-àpà, wọn kò sì ṣahun; (ìnáwó wọn) wà láààrin ìyẹn ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì.

وَٱلَّذِينَ لَا يَدۡعُونَ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ وَلَا يَقۡتُلُونَ ٱلنَّفۡسَ ٱلَّتِي حَرَّمَ ٱللَّهُ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَلَا يَزۡنُونَۚ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ يَلۡقَ أَثَامٗا﴿٦٨

68(Àwọn ni) àwọn tí kò pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Wọn kò pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Àti pé wọn kò ṣe zinā. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe (aburú) yẹn, ó máa pàdé (ìyà) ẹ̀ṣẹ̀.

يُضَٰعَفۡ لَهُ ٱلۡعَذَابُ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَيَخۡلُدۡ فِيهِۦ مُهَانًا﴿٦٩

69A óò ṣe ìyà ní ìlọ́po fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa ṣe gbére nínú rẹ̀ ní ẹni yẹpẹrẹ.

إِلَّا مَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ عَمَلٗا صَٰلِحٗا فَأُوْلَٰٓئِكَ يُبَدِّلُ ٱللَّهُ سَيِّـَٔاتِهِمۡ حَسَنَٰتٖۗ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمٗا﴿٧٠

70Àfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu yóò fi iṣẹ́ rere rọ́pò iṣẹ́ aburú wọn (ìyẹn, nípa ìronúpìwàdà wọn). Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

وَمَن تَابَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَإِنَّهُۥ يَتُوبُ إِلَى ٱللَّهِ مَتَابٗا﴿٧١

71Ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (kí ó mọ̀) pé dájúdájú ó ń ronú pìwàdà pátápátá sọ́dọ̀ Allāhu ni.

وَٱلَّذِينَ لَا يَشۡهَدُونَ ٱلزُّورَ وَإِذَا مَرُّواْ بِٱللَّغۡوِ مَرُّواْ كِرَامٗا﴿٧٢

72(Àwọn ni) àwọn tí kò jẹ́rìí èké. Tí wọ́n bá sì kọjá níbi ìbàjẹ́, wọ́n á kọjá pẹ̀lú àpọ́nlé.[1]

وَٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِّرُواْ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ لَمۡ يَخِرُّواْ عَلَيۡهَا صُمّٗا وَعُمۡيَانٗا﴿٧٣

73(Àwọn ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá fi àwọn āyah Olúwa wọn ṣèrántí fún wọn, wọn kò dà lulẹ̀ bí adití àti afọ́jú.

وَٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا هَبۡ لَنَا مِنۡ أَزۡوَٰجِنَا وَذُرِّيَّٰتِنَا قُرَّةَ أَعۡيُنٖ وَٱجۡعَلۡنَا لِلۡمُتَّقِينَ إِمَامًا﴿٧٤

74(Àwọn ni) àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, ta wá ní ọrẹ ìtutù-ojú (ìdùnnú àti ayọ̀) láti ara àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa. Kí O sì ṣe wá ní aṣíwájú (àwòkọ́ṣe rere) fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ).”

أُوْلَٰٓئِكَ يُجۡزَوۡنَ ٱلۡغُرۡفَةَ بِمَا صَبَرُواْ وَيُلَقَّوۡنَ فِيهَا تَحِيَّةٗ وَسَلَٰمًا﴿٧٥

75Àwọn wọ̀nyẹn, ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì gíga (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ni A máa fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí pé, wọ́n ṣe sùúrù. Ìkíni àti sísálámọ̀ ni A óò fi máa pàdé wọn nínú rẹ̀

خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ حَسُنَتۡ مُسۡتَقَرّٗا وَمُقَامٗا﴿٧٦

76Olúṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó dára ní ibùgbé àti ibùdúró.

قُلۡ مَا يَعۡبَؤُاْ بِكُمۡ رَبِّي لَوۡلَا دُعَآؤُكُمۡۖ فَقَدۡ كَذَّبۡتُمۡ فَسَوۡفَ يَكُونُ لِزَامَۢا﴿٧٧

77Sọ pé: “Olúwa mi kò kà yín kún tí kì í bá ṣe àdúà yín (àti ìjọ́sìn yín). Ẹ kúkú ti pe (àwọn āyah Rẹ̀) nírọ́. Láìpẹ́ ó sì máa di ìyà àìnípẹ̀kun (fún yín).”

RELATED SURAHS