الشعراء
The Poets • 227 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Tọ̄ sīn mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
2Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
3Nítorí kí ni o ṣe máa para rẹ pé wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
4Tí A bá fẹ́, A máa sọ àmì kan kalẹ̀ fún wọn láti sánmọ̀. Àwọn ọrùn wọn kò sì níí yé tẹríba fún un.
5Kò sí ìrántí kan tí ó máa dé bá wọn ní titun láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé àfi kí wọ́n jẹ́ olùgbúnrí kúrò níbẹ̀.
6Dájúdájú wọ́n ti pe (āyah Wa) nírọ́. Nítorí náà, àwọn ìró ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn.
7Ṣé wọn kò rí ilẹ̀ pé mélòó mélòó nínú gbogbo oríṣiríṣi n̄ǹkan alápọ̀n-ọ́nlé tí A mú hù jáde láti inú rẹ̀?
8Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
9Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
10(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ pe (Ànábì) Mūsā pé: “Lọ bá ìjọ alábòsí,
11ìjọ Fir‘aon (kí o sì sọ̱ fún wọn) pé, ‘Ṣé wọn kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni.’ ”
12Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.
13Ó sì máa jẹ́ ìnira fún mi (tí wọ́n bá pè mí ní òpùrọ́). Ahọ́n mi kò sì já gaaraga. Nítorí náà, ránṣẹ́ sí Hārūn.
14Àti pé mo ní ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́rùn lọ́dọ̀ wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí.”
15(Allāhu) sọ pé: “Rárá (wọn kò lè pa ọ́). Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Wa lọ (bá wọn). Dájúdájú Àwa ń bẹ pẹ̀lú yín; À ń gbọ́ (ọ̀rọ̀ yín).
16Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ bá Fir‘aon. Kí ẹ sọ fún un pé: “Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
17(À ń sọ fún ọ) pé kí o jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ.”
18(Fir‘aon) wí pé: “Ṣé kì í ṣe ní ààrin wa ni a ti tọ́ ọ ní kékeré ni, tí o sì gbé ní ọ̀dọ̀ wa fún ọdún púpọ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ?
19O sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tí o ṣe (sí wa). Ìwọ sì wà nínú àwọn aláìmoore.”
20(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Mo ṣe é nígbà náà nígbà tí mo wà nínú àwọn aláṣìṣe (èmi kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é).
21Mo sì sá fún yín nígbà tí mo bẹ̀rù yín. Lẹ́yìn náà, Allāhu ta mí lọ́rẹ ipò Ànábì. Ó sì ṣe mí ní (ọ̀kan) nínú àwọn Òjíṣẹ́.
22Àti pé ìyẹn ni ìdẹ̀ra tí ò ń ṣe ìrègún rẹ̀ lé mi lórí. Pé ó sọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl di ẹrú (ńkọ́?).[1]
23Fir‘aon wí pé: “Kí ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”
24(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.”
25(Fir‘aon) wí fún àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ (tó ń sọ ni)?”
26(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
27(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ yín èyí tí wọ́n rán si yín, wèrè mà ni.”
28(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa ibùyọ òòrùn, ibùwọ̀ òòrùn àti ohunkóhun tó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ bá máa ń ṣe làákàyè.”
29(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú tí o bá fi lè jọ́sìn fún ọlọ́hun kan yàtọ̀ sí mi, dájúdájú mo máa sọ ọ́ di ara àwọn ẹlẹ́wọ̀n.”
30(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé mo mú kiní kan tó yanjú wá fún ọ ńkọ́?”
31(Fir‘aon) wí pé: “Mú un wá nígbà náà tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”
32Nítorí náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé.
33Ó tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ síta, ó sì di funfun fún àwọn olùwòran.
34(Fir‘aon) wí fún àwọn ìjòyè tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa.
35Ó fẹ́ fi idán rẹ̀ kó yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni. Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?”[1]
36Wọ́n wí pé: “Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ[1] sí àwọn ìlú
37(pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ.”
38Wọ́n sì kó àwọn òpìdán jọ ní àsìkò tí wọ́n fi àdéhùn sí ní ọjọ́ tí (gbogbo ìlú) ti mọ̀.
39Wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn pé: “Ṣé ẹ̀yin máa kó jọ (síbẹ̀) bí?
40Nítorí kí á lè tẹ̀lé àwọn òpìdán tí ó bá jẹ́ pé àwọn ni olùborí.”
41Nígbà tí àwọn òpìdán dé, wọ́n wí fún Fir‘aon pé: “Ǹjẹ́ owó-ọ̀yà kan wà fún wa, tí ó bá jẹ́ pé àwa gan-an la jẹ́ olùborí?”
42(Fir‘aon) wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú nígbà náà ẹ máa wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).”
43(Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ fẹ́ jù sílẹ̀.”
44Wọ́n sì ju àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn sílẹ̀. Wọ́n wí pé: “Pẹ̀lú ògo Fir‘aon, dájúdájú àwa, àwa ni olùborí.”
45Nígbà náà, (Ànábì) Mūsā ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀. Ó sì ń gbé ohun tí wọ́n pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló.
46Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).
47Wọ́n sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá,
48Olúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.”
49Fir‘aon wí pé: “Ẹ gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fún yín! Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Láìpẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ wá mọ̀. Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.”
50(Àwọn òpìdán) sọ pé: “Kò sí ìnira fún wa! Dájúdájú àwa yó sì fàbọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wa.
51Dájúdájú àwa n retí pé Olúwa wa yóò ṣe àforíjìn àwọn àṣìṣe wa fún wa nítorí pé àwa jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo.”[1]
52A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru (nítorí pé), dájúdájú wọn yóò lépa yín.”
53Fir‘aon sì rán àwọn akónijọ sínú àwọn ìlú (láti sọ pé):
54“Dájúdájú àwọn (ọmọ ’Isrọ̄’īl) wọ̀nyí, ìjọ péréte díẹ̀ ni wọ́n.
55Àti pé dájúdájú wọ́n ti ṣe ohun tó ń bí wa nínú.
56Dájúdájú gbogbo wa ni kí á sì wà tìfura-tìfura.”
57Nítorí náà, A mú (ìjọ Fir‘aon) jáde kúrò nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi,
58àti àwọn ilé ọrọ̀ àti ibùjókòó àpọ́nlé.
59Báyẹn (lọ̀rọ̀ rí). A sì jogún rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.
60Wọ́n sì lépa wọn ní àsìkò tí òòrùn yọ.
61Nígbà tí ìjọ méjèèjì ríra wọn, àwọn ìjọ (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú wọn yóò lé wa bá.”
62(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Rárá, dájúdájú Olúwa mi ń bẹ pẹ̀lú mi. Ó sì máa fi ọ̀nà mọ̀ mí.”
63A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Fi ọ̀pá rẹ na agbami òkun.” (Ó fi nà án). Ó sì pín (sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀).[1] Ìpín kọ̀ọ̀kan sì dà bí àpáta ńlá.
64A sì mú ìjọ kejì (ìyẹn, ìjọ Fir‘aon) súnmọ́ ibẹ̀ yẹn.
65A gba (Ànábì) Mūsā àti gbogbo àwọn tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ là pátápátá.
66Lẹ́yìn náà, A tẹ ìjọ kejì rì (sínú agbami).
67Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
68Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
69Ka ìtàn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm fún wọn.
70Nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ná?”
71Wọ́n wí pé: “À ń jọ́sìn fún àwọn ère òrìṣà kan ni. A ò sì níí yé takú tì wọ́n lọ́rùn.”
72(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Ǹjẹ́ wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ bá ń pè wọ́n?
73Tàbí (ṣé) wọ́n lè ṣe yín ní àǹfààní tàbí wọ́n lè fi ìnira kàn yín?”
74Wọ́n wí pé: “Rárá o! A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni”
75(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “ Ẹ sọ fún mi, kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún,
76ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín àwọn ẹni ìṣáájú?
77Dájúdájú àwọn ni ọ̀tá fún mi àyàfi Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
78(Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Nítorí náà, Ó máa fi ọ̀nà mọ̀ mí;
79Ẹni tó ń fún mi ní jíjẹ, tó ń fún mi ní mímu;
80Àti pé nígbà tí ara mi kò bá yá, Òun l’Ó ń wò mí sàn;
81Ẹni tí Ó máa pa mí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ mí di alààyè;
82Ẹni tí mo ní ìrètí sí pé Ó máa forí àwọn àṣìṣe mi jìn mí ní Ọjọ́ Ẹ̀san.
83Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ ipò Ànábì. Dà mí pọ̀ mọ́ àwọn ẹni rere.
84Fi òdodo sórí ahọ́n àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi nìpa mi (ìyẹn ni pé, jẹ́ kí àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi máa sọ̀rọ̀ mi ní dáadáa).[1]
85Ṣe mí ní ọ̀kan nínú àwọn olùjogún Ọgbà Ìdẹ̀ra.
86Kí O sì foríjin bàbá mi. Dájúdájú ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùṣìnà.
87Má ṣe dójú tì mí ní ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.
88Ọjọ́ tí dúkìá kan tàbí àwọn ọmọ kò níí ṣàǹfààní.
89Àyàfi ẹni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ọkàn mímọ́.”[1]
90A máa mú Ọgbà Ìdẹ̀ra súnmọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
91Wọ́n sì máa fi iná Jẹhīm han àwọn olùṣìnà,
92wọn yó sì sọ fún wọn pé: “Níbo ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún wà?”
93(N̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu, ṣé wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ tàbí ṣé wọ́n lè ran ara wọn lọ́wọ́?
94Wọ́n sì máa taari gbogbo wọn ṣubú sínú Iná; àwọn (olùṣìnà) àti àwọn ọ̀gá wọn (nínú ìṣìnà),
95àti àwọn ọmọ ogun ’Iblīs pátápátá.
96(Àwọn aláìgbàgbọ́), nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn jiyàn nínú Iná, wọ́n á wí pé:
97“A fi Allāhu búra, dájúdájú àwa kúkú ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé
98nígbà tí a fi yín ṣe akẹgbẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
99Kò sí ohun tí ó ṣì wá lọ́nà bí kò ṣe àwọn (aṣ-ṣaetọ̄n) ẹlẹ́ṣẹ̀.
100Kò sì sí àwọn olùṣìpẹ̀ kan fún wa mọ́.
101Kò tún sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan (fún wa.)
102Tí ó bá jẹ́ pé ìpadà sí ilé ayé wà fún wa ni, nígbà náà àwa ìbá wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
103Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
104Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
105Ìjọ (Ànábì) Nūh pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
106Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Nūh, sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
107Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
108Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
109Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
110Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.”
111Wọ́n wí pé: “Ṣé kí á gbà ọ́ gbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ l’ó ń tẹ̀lé ọ!?”
112Ó sọ pé: “Èmi kò nímọ̀ sí ohun tí wọ́n ń ṣe (lẹ́yìn mi).
113Kò sí ìṣírò-iṣẹ́ wọn lọ́dọ̀ ẹnì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Olúwa mi, tí ó bá jẹ́ pé ẹ bá fura.
114Èmi kò sì níí lé àwọn onígbàgbọ́ òdodo dànù.
115Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”
116Wọ́n wí pé: “Dájúdájú tí ìwọ Nūh kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa jù lókò.”
117Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pè mí ní òpùrọ́.
118Nítorí náà, ṣèdájọ́ tààrà láààrin èmi àti àwọn. Kí o sì la èmi àti àwọn tó wà pẹ̀lú mi nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
119A la òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi tó kún kẹ́kẹ́.
120Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn tó ṣẹ́kù lẹ́yìn wọn rì sínú omi.
121Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
122Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
123Àwọn ìran ‘Ād pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
124Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
125Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
126Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
127Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
128Ṣé ẹ óò máa kọ́ ilé ńlá ńlá sí àwọn àyè gíga (kí ẹ lè) máa fi àwọn olùrékọjá ṣẹ̀fẹ̀?
129Ẹ sì ń kọ́ àwọn ilé ńlá ńlá bí ẹni pé ẹ máa ṣe gbére (nílé ayé yìí).
130Nígbà tí ẹ bá sì gbá (ènìyàn mú láti fìyà jẹ wọ́n), ẹ̀ ń gbá wọn mú ní ìgbámú aláìlójú-àánú.
131Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
132Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tí ẹ mọ̀;
133Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ẹran-ọ̀sìn àti àwọn ọmọ,
134àti àwọn ọgbà oko pẹ̀lú àwọn ìṣẹ́lẹ̀rú omi.
135Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá fún yín.”
136Wọ́n wí pé: “Bákan náà ni fún wa; yálà o ṣe wáàsí fún wa tàbí o ò sí nínú àwọn oníwáàsí.”
137- Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìwà àwọn ẹni àkọ́kọ́.[1] –
138Wọn kò sì níí jẹ wá níyà.”
139Nítorí náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. A sì pa wọ́n run. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
140Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
141Àwọn ìran Thamūd pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
142Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih, sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
143Dájúdájú emi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
144Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
145Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
146Ṣé kí wọ́n fi yín sílẹ̀ síbi n̄ǹkan tí ó wà (nílé ayé) níbí yìí (nínú ìgbádùn ayé, kí ẹ jẹ́) olùfọkànbalẹ̀
147nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi.
148àti oko irúgbìn pẹ̀lú igi dàbínù tí àwọn èso wọn ti gbó?
149Ẹ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àwọn àpáta (gẹ́gẹ́ bí) akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ olùgbéraga!
150Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
151Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àṣẹ àwọn alákọyọ (aláṣejù),
152àwọn tó ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣe rere.”
153Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.
154Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Nítorí náà, mú àmì kan wá tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
155Ó sọ pé: “Èyí ni abo ràkúnmí kan. Omi wà fún òhun, omi sì wà fún ẹ̀yin náà ní ọjọ́ tí a ti mọ̀ (ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀).
156Ẹ má ṣe fi aburú kan kàn án nítorí kí ìyà ọjọ́ ńlá má baà jẹ yín.”
157Wọ́n sì gún un pa. Nítorí náà, wọ́n sì di alábàámọ̀.
158Ìyà náà jẹ wọ́n. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
159Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
160Ìjọ Lūt pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
161Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Lūt, sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
162Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
163Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
164Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
165Ṣé àwọn ọkùnrin nínú ẹ̀dá ni ẹ̀yin ọkùnrin yóò lọ máa bá (fún adùn ìbálòpọ̀)?
166Ẹ sì ń pa ohun tí Olúwa yín dá fún yín tì nínú àwọn ìyàwó yín! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni ẹ̀yin.”
167Wọ́n wí pé: “Tí ìwọ Lūt kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa lé jáde kúrò nínú ìlú.”
168Ó sọ pé: “Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùkórira sí iṣẹ́ (aburú) ọwọ́ yín.
169Olúwa mi, la èmi àti àwọn ènìyàn mi níbí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (aburú).”
170Nítorí náà, A la òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pátápátá.
171Àfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).[1]
172Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run.
173A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú.
174Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
175Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
176Àwọn ará ’Aekah pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
177Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb, sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ̀yin kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
178Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
179Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
180Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
181Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún. Kí ẹ sì má ṣe wà nínú àwọn tó ń dín òṣùwọ̀n kù.
182Ẹ fi ìwọ̀n tó tọ́[1] wọn n̄ǹkan.
183Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀.
184Kí ẹ sì bẹ̀rù Ẹni tí Ó dá yín àti àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́.”
185Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.
186Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Àti pé a kò rò ọ́ sí kiní kan bí kò ṣe pé o wà nínú àwọn òpùrọ́.
187Nítorí náà, jẹ́ kí apá kan nínú sánmọ̀ ya lù wá mọ́lẹ̀, tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
188Ó sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
189Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà ọjọ́ ẹ̀ṣújò sì jẹ wọ́n. Dájúdájú ó jẹ́ ìyà ọjọ́ ńlá.
190Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
191Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
192Dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
193Mọlāika Jibrīl, olùfọkàntán l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀
194sínú ọkàn rẹ nítorí kí o lè wà nínú àwọn olùkìlọ̀
195pẹ̀lú èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé.
196Dájúdájú (ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀) wà nínú ìpín-ìpín Tírà àwọn ẹni àkọ́kọ́.
197Ṣé kò jẹ́ àmì kan fún wọn pé àwọn onímọ̀ (nínú) àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nímọ̀ (sí àsọọ́lẹ̀ nípa) rẹ̀ (nínú tírà ọwọ́ wọn)?[1]
198Tí ó bá jẹ́ pé A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún apá kan àwọn elédè mìíràn ni,
199tí ó sì ké e fún wọn, wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo.
200Báyẹn ni A ṣe mú (àtakò) wọ inú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
201Wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
202(Ìyà náà) yóò dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura.
203Nígbà náà ni wọn yóò wí pé: “Ǹjẹ́ wọ́n lè lọ́ wa lára bí?”
204Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?[1]
205Sọ fún Mi tí A bá fún wọn ní ìgbádùn ayé fún ọdún gbọọrọ!
206Lẹ́yìn náà, kí ohun tí À ń ṣe ní ìlérí fún wọn dé bá wọn.
207Ohun tí A ṣe ní ìgbádùn fún wọn kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.
208A ò sì pa ìlú kan run àfi kí wọ́n ti ní àwọn olùkìlọ̀.
209Ìrántí (dé fún wọn sẹ́). Àti pé Àwa kì í ṣe alábòsí.
210Kì í ṣe àwọn aṣ-ṣaetọ̄n ni wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀.
211Kò yẹ fún wọn. Wọn kò sì lágbára rẹ̀.
212Dájúdájú A ti mú wọn takété sí gbígbọ́ rẹ̀ (láti ojú sánmọ̀).
213Nítorí náà, má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, nítorí kí ìwọ má baà wà nínú àwọn tí A máa jẹ níyà.
214Kí o sì kìlọ̀ fún àwọn ẹbí rẹ tó súnmọ́ jùlọ.
215Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn tó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
216Tí wọ́n bá sì yapa (àṣẹ) rẹ, sọ pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe (níṣẹ́ aburú).”
217Kí o sì gbáralé Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run;
218Ẹni tó ń rí ọ nígbà tí ò ń dìde nàró (fún ìrun kíkí)
219àti ìyírapadà rẹ (fún rukuu àti ìforíkanlẹ̀) láààrin àwọn olùforíkanlẹ̀.
220Dájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
221Ṣé kí n̄g sọ ẹni tí àwọn aṣ-ṣaetọ̄n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá fún yín?
222Wọ́n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá gbogbo àwọn òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
223(Àwọn aṣ-ṣaetọ̄n) ń dẹtí (sí ìró sánmọ̀). Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òpùrọ́.
224Àwọn eléwì, àwọn olùṣìnà l’ó ń tẹ̀lé wọn.
225Ṣé o ò rí i pé gbogbo ọ̀gbun ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń tẹnu bọ̀ ni?
226Àti pé dájúdájú wọ́n ń sọ ohun tí wọn kò níí ṣe.
227Àfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, tí wọ́n rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀, tí wọ́n sì jàjà gbara lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàbòsí sí wọn. Àwọn tó ṣàbòsí sì máa mọ irú ìkángun tí wọ́n máa gúnlẹ̀ sí.