Al-'Adiyat

العاديات

The Chargers11 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلۡعَٰدِيَٰتِ ضَبۡحٗا﴿١

1Allāhu fi àwọn ẹṣin tó ń sáré tó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun búra.

فَٱلۡمُورِيَٰتِ قَدۡحٗا﴿٢

2Ó tún fi àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá) búra.

فَٱلۡمُغِيرَٰتِ صُبۡحٗا﴿٣

3Ó tún fi àwọn ẹṣin tó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù búra.

فَأَثَرۡنَ بِهِۦ نَقۡعٗا﴿٤

4Wọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè.

فَوَسَطۡنَ بِهِۦ جَمۡعًا﴿٥

5Wọ́n tún bẹ́ gìjà pẹ̀lú eruku ẹsẹ̀ wọn sáààrin àkójọ ọ̀tá.

إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لِرَبِّهِۦ لَكَنُودٞ﴿٦

6Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀.

وَإِنَّهُۥ عَلَىٰ ذَٰلِكَ لَشَهِيدٞ﴿٧

7Dájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.

وَإِنَّهُۥ لِحُبِّ ٱلۡخَيۡرِ لَشَدِيدٌ﴿٨

8Àti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé.

۞ أَفَلَا يَعۡلَمُ إِذَا بُعۡثِرَ مَا فِي ٱلۡقُبُورِ﴿٩

9Ṣé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun tó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde),

وَحُصِّلَ مَا فِي ٱلصُّدُورِ﴿١٠

10tí wọ́n sì tú ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá,

إِنَّ رَبَّهُم بِهِمۡ يَوۡمَئِذٖ لَّخَبِيرُۢ﴿١١

11dájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn?

RELATED SURAHS