القارعة
The Striking Calamity • 11 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Àkókò ìjáyà.
2Kí ni Àkókò ìjáyà?
3Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Àkókò ìjáyà?
4(Òhun ni) ọjọ́ tí ènìyàn yó dà bí àfòpiná tí wọ́n fọ́nká síta,
5àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú tí wọ́n gbọ̀n dànù.
6Nítorí náà, ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n,
7ó sì máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí.
8Ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá sì fúyẹ́,
9Hāwiyah sì ni ibùgbé rẹ̀.
10Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀?
11(Òhun ni) Iná gbígbóná tó ń jó gan-an.