Al-Balad

البلد

The City20 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

لَآ أُقۡسِمُ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ﴿١

1Èmi (Allāhu) ń fi ìlú yìí[1] búra.

وَأَنتَ حِلُّۢ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ﴿٢

2Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).[1]

وَوَالِدٖ وَمَا وَلَدَ﴿٣

3Èmi (Allāhu) ń fi òbí àti ohun tó bí búra.

لَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ فِي كَبَدٍ﴿٤

4Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.

أَيَحۡسَبُ أَن لَّن يَقۡدِرَ عَلَيۡهِ أَحَدٞ﴿٥

5Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?

يَقُولُ أَهۡلَكۡتُ مَالٗا لُّبَدًا﴿٦

6Ó (sì) ń wí pé: “Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -)”

أَيَحۡسَبُ أَن لَّمۡ يَرَهُۥٓ أَحَدٌ﴿٧

7Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?

أَلَمۡ نَجۡعَل لَّهُۥ عَيۡنَيۡنِ﴿٨

8Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un?

وَلِسَانٗا وَشَفَتَيۡنِ﴿٩

9Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?

وَهَدَيۡنَٰهُ ٱلنَّجۡدَيۡنِ﴿١٠

10A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.

فَلَا ٱقۡتَحَمَ ٱلۡعَقَبَةَ﴿١١

11Kò sì lọ rin ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí níbi Iná!

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡعَقَبَةُ﴿١٢

12Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí?

فَكُّ رَقَبَةٍ﴿١٣

13(Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.

أَوۡ إِطۡعَٰمٞ فِي يَوۡمٖ ذِي مَسۡغَبَةٖ﴿١٤

14Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.

يَتِيمٗا ذَا مَقۡرَبَةٍ﴿١٥

15(Ẹ lè fún) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,

أَوۡ مِسۡكِينٗا ذَا مَتۡرَبَةٖ﴿١٦

16tàbí mẹ̀kúnnù tí kò ní gá tí kò ní go (olòṣì paraku).

ثُمَّ كَانَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلصَّبۡرِ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلۡمَرۡحَمَةِ﴿١٧

17Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.

أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ﴿١٨

18Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.

وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِنَا هُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشۡـَٔمَةِ﴿١٩

19Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.[1]

عَلَيۡهِمۡ نَارٞ مُّؤۡصَدَةُۢ﴿٢٠

20Wọ́n máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.

RELATED SURAHS