Al-Ma'arij

المعارج

The Ascending Stairways44 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

سَأَلَ سَآئِلُۢ بِعَذَابٖ وَاقِعٖ﴿١

1Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà tó máa ṣẹlẹ̀

لِّلۡكَٰفِرِينَ لَيۡسَ لَهُۥ دَافِعٞ﴿٢

2sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́

مِّنَ ٱللَّهِ ذِي ٱلۡمَعَارِجِ﴿٣

3lọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga.

تَعۡرُجُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ إِلَيۡهِ فِي يَوۡمٖ كَانَ مِقۡدَارُهُۥ خَمۡسِينَ أَلۡفَ سَنَةٖ﴿٤

4Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín).[1]

فَٱصۡبِرۡ صَبۡرٗا جَمِيلًا﴿٥

5Nítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù tó rẹwà.

إِنَّهُمۡ يَرَوۡنَهُۥ بَعِيدٗا﴿٦

6Dájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun tó jìnnà.

وَنَرَىٰهُ قَرِيبٗا﴿٧

7A sì ń wò ó ní ohun tó súnmọ́.

يَوۡمَ تَكُونُ ٱلسَّمَآءُ كَٱلۡمُهۡلِ﴿٨

8(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí ògéré epo gbígbóná,

وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ﴿٩

9àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun,

وَلَا يَسۡـَٔلُ حَمِيمٌ حَمِيمٗا﴿١٠

10ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀).

يُبَصَّرُونَهُمۡۚ يَوَدُّ ٱلۡمُجۡرِمُ لَوۡ يَفۡتَدِي مِنۡ عَذَابِ يَوۡمِئِذِۭ بِبَنِيهِ﴿١١

11Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn.

وَصَٰحِبَتِهِۦ وَأَخِيهِ﴿١٢

12Ìyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀,

وَفَصِيلَتِهِ ٱلَّتِي تُـٔۡوِيهِ﴿١٣

13àti àwọn ẹbí rẹ̀ tó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé,

وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا ثُمَّ يُنجِيهِ﴿١٤

14àti gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná).

كَلَّآۖ إِنَّهَا لَظَىٰ﴿١٥

15Rárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná tó ń jò fòfò).

نَزَّاعَةٗ لِّلشَّوَىٰ﴿١٦

16Ó máa bó awọ orí tòró.

تَدۡعُواْ مَنۡ أَدۡبَرَ وَتَوَلَّىٰ﴿١٧

17(Iná) yó máa ké sí ẹni tó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i,

وَجَمَعَ فَأَوۡعَىٰٓ﴿١٨

18ó kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn).

۞ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ خُلِقَ هَلُوعًا﴿١٩

19Dájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà.

إِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ جَزُوعٗا﴿٢٠

20Nígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó.

وَإِذَا مَسَّهُ ٱلۡخَيۡرُ مَنُوعًا﴿٢١

21Nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì ba oore, ó máa yahun.

إِلَّا ٱلۡمُصَلِّينَ﴿٢٢

22Àyàfi àwọn olùkírun,

ٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ دَآئِمُونَ﴿٢٣

23àwọn tí wọ́n dúnnímọ́ ìrun wọn;

وَٱلَّذِينَ فِيٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ حَقّٞ مَّعۡلُومٞ﴿٢٤

24àwọn tó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn

لِّلسَّآئِلِ وَٱلۡمَحۡرُومِ﴿٢٥

25sí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún;

وَٱلَّذِينَ يُصَدِّقُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ﴿٢٦

26àwọn tó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo;

وَٱلَّذِينَ هُم مِّنۡ عَذَابِ رَبِّهِم مُّشۡفِقُونَ﴿٢٧

27àwọn tó ń páyà ìyà Olúwa wọn,

إِنَّ عَذَابَ رَبِّهِمۡ غَيۡرُ مَأۡمُونٖ﴿٢٨

28dájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí;

وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِفُرُوجِهِمۡ حَٰفِظُونَ﴿٢٩

29àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,

إِلَّا عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَإِنَّهُمۡ غَيۡرُ مَلُومِينَ﴿٣٠

30àyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú,

فَمَنِ ٱبۡتَغَىٰ وَرَآءَ ذَٰلِكَ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡعَادُونَ﴿٣١

31nítorí náà, ẹnikẹ́ni tó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùtayọ-ẹnu ààlà;

وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِأَمَٰنَٰتِهِمۡ وَعَهۡدِهِمۡ رَٰعُونَ﴿٣٢

32àwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn;

وَٱلَّذِينَ هُم بِشَهَٰدَٰتِهِمۡ قَآئِمُونَ﴿٣٣

33àwọn tó ń dúró ti ìjẹ́rìí (òdodo) wọn;

وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ يُحَافِظُونَ﴿٣٤

34àti àwọn tó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn.

أُوْلَٰٓئِكَ فِي جَنَّٰتٖ مُّكۡرَمُونَ﴿٣٥

35Àwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.

فَمَالِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ قِبَلَكَ مُهۡطِعِينَ﴿٣٦

36Kí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ,

عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَعَنِ ٱلشِّمَالِ عِزِينَ﴿٣٧

37tí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)?

أَيَطۡمَعُ كُلُّ ٱمۡرِيٕٖ مِّنۡهُمۡ أَن يُدۡخَلَ جَنَّةَ نَعِيمٖ﴿٣٨

38Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni?

كَلَّآۖ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّمَّا يَعۡلَمُونَ﴿٣٩

39Rárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀.

فَلَآ أُقۡسِمُ بِرَبِّ ٱلۡمَشَٰرِقِ وَٱلۡمَغَٰرِبِ إِنَّا لَقَٰدِرُونَ﴿٤٠

40Nítorí náà, Èmi ń fi Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn[1] búra, dájúdájú Àwa ni Alágbára

عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ خَيۡرٗا مِّنۡهُمۡ وَمَا نَحۡنُ بِمَسۡبُوقِينَ﴿٤١

41láti yí (ìrísí wọn) padà (ní ọjọ́ Àjíǹde) sí (ìrísí kan) tó máa dára ju (ìrísí) wọn (tayé). Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara.[1]

فَذَرۡهُمۡ يَخُوضُواْ وَيَلۡعَبُواْ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ﴿٤٢

42Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.

يَوۡمَ يَخۡرُجُونَ مِنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ سِرَاعٗا كَأَنَّهُمۡ إِلَىٰ نُصُبٖ يُوفِضُونَ﴿٤٣

43Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan.

خَٰشِعَةً أَبۡصَٰرُهُمۡ تَرۡهَقُهُمۡ ذِلَّةٞۚ ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمُ ٱلَّذِي كَانُواْ يُوعَدُونَ﴿٤٤

44Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.

RELATED SURAHS