المؤمنون
The Believers • 118 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Dájúdájú àwọn onígbàgbọ́ òdodo ti jèrè.
2Àwọn tó ń páyà (Allāhu) nínú ìrun wọn,
3àti àwọn tó ń ṣẹ́rí kúrò níbi ìsọkúsọ,
4àti àwọn tó ń ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀mí àti ara) wọn.[1]
5àti àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,
6àfi ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó wọn àti ẹrúbìnrin wọn. Dájúdájú wọn kì í ṣe ẹni èébú (tí wọ́n bá súnmọ́ wọn),
7nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wá òmíràn (súnmọ́) lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà,[1]
8àti àwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn,
9àti àwọn tó ń ṣọ́ ìrun wọn;
10àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùjogún,
11àwọn tó máa jogún ọgbà ìdẹ̀ra Firdaos. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
12Dájúdájú A ti ṣe ẹ̀dá ènìyàn láti inú ohun tí A mọ jáde láti inú ẹrẹ̀.
13Lẹ́yìn náà, A ṣe é ní àtọ̀ sínú àyè ìrọ̀rùn kan (ìyẹn, ilé-ọmọ).
14Lẹ́yìn náà, A sọ àtọ̀ di ẹ̀jẹ̀ dídì. Lẹ́yìn náà, A sọ ẹ̀jẹ̀ dídì di bááṣí ẹran. Lẹ́yìn náà, A sọ bááṣí ẹran di eegun. Lẹ́yìn náà, A fi ẹran bo eegun. Lẹ́yìn náà, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn.[1] Nítorí náà, ìbùkún ni fún Allāhu, Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá (oníṣẹ́-ọnà).
15Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn ìyẹn, dájúdájú ẹ̀yin yóò di òkú.
16Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní Ọjọ́ Àjíǹde wọ́n máa gbe yín dìde.
17Dájúdájú A dá àwọn sánmọ̀ méje sí òkè yín. Àwa kò sì níí dágunlá sí àwọn ẹ̀dá.
18À ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n níwọ̀n. Lẹ́yìn náà, À ń mú un dúró sínú ilẹ̀. Dájúdájú Àwa kúkú lágbára láti mú un lọ.
19Lẹ́yìn náà, A fi dá àwọn ọgbà oko dàbínù àti àjàrà fún yín; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso wà nínú rẹ̀ fún yín, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.
20Àti igi kan tó ń hù jáde níbi àpáta Sīnā’; ó ń mú epo àti n̄ǹkan ìṣebẹ̀ jáde fún àwọn tó ń jẹ ẹ́.
21Àti pé dájúdájú àríwòye wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn; À ń fún yín mu nínú ohun tí ó wà nínú ikùn wọn. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àǹfààní (mìíràn) tún wà fún yín lára wọn, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.
22Ẹ sì ń kó ẹrù sí orí àwọn ẹran ọ̀sìn àti ọkọ̀ ojú-omi.
23Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun mìíràn tí ẹ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
24Àwọn olórí tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín, tí ó fẹ́ gbé àjùlọ fún ara rẹ̀ lórí yín. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (ránṣẹ́ sí wa ni), ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ ni. A kò sì gbọ́ èyí rí lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́.
25Kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí àlùjànnú ń bẹ lára rẹ̀. Nítorí náà, ẹ máa retí (ìkángun) rẹ̀ títí di ìgbà kan ná.”
26(Ànábì) Nūh sọ pé: “Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́.”
27Nítorí náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Ṣe ọkọ̀ ojú-omi ní ojú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Nígbà tí àṣẹ Wa bá dé, tí omi bá ṣẹ́ yọ ní ojú àrò, nígbà náà ni kí o kó sínú ọkọ̀ ojú-omi gbogbo n̄ǹkan ní oríṣi méjì takọ-tabo àti ará ilé rẹ, àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí nínú wọn (fún ìparun). Má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ṣàbòsí; dájúdájú A óò tẹ̀ wọ́n rì sínú omi ni.
28Nígbà tí o bá jókòó sínú ọkọ̀ ojú-omi náà, ìwọ àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ, sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó gbà wá là lọ́wọ́ ijọ alábòsí.”
29Sọ pé: “Olúwa mi, sọ̀ mí kalẹ̀ sí ibùsọ̀ ìbùkún. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn amúnigúnlẹ̀.”[1]
30Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Àwa sì ni À ń dán ẹ̀dá wò.
31Lẹ́yìn náà, A mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn.
32A tún rán Òjíṣẹ́ kan sí wọn láààrin ara wọn (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun mìíràn tí ẹ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
33Àwọn olórí tó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀, àwọn tó pe ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn nírọ́, àwọn tí A ṣe gbẹdẹmukẹ fún nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí, wọ́n wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín; ó ń jẹ nínú ohun tí ẹ̀ ń jẹ, ó sì ń mu nínú ohun tí ẹ̀ ń mu.
34Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé abara kan bí irú yín, dájúdájú ẹ mà ti di ẹni òfò nìyẹn.
35Ṣé ó ń ṣe àdéhùn fún yín pé nígbà tí ẹ bá kú, tí ẹ sì di erùpẹ̀ àti egungun tán, dájúdájú wọn yóò mu yín jáde (ní alààyè)?
36Ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín (yìí) jìnnà tefétefé (sí òdodo).
37Kò sí ìṣẹ̀mí ayé kan mọ́ àyàfi èyí tí à ń lò yìí; àwa kan ń kú, àwa kan ń wáyé. Àti pé wọn kò níí gbé wa dìde mọ́.
38(Òjíṣẹ́ náà) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Àwa kò sì níí gbà á gbọ́.”
39(Òjíṣẹ́ náà) sọ pé: “Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́.”
40(Allāhu) sọ pé: “Láìpẹ́ ńṣe ni wọn yóò di alábàámọ̀.”
41Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. A sì sọ wọ́n di pàǹtí. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ alábòsí.
42Lẹ́yìn náà, A tún mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn.
43Ìjọ kan kò níí lọ ṣíwájú àkókò (ìparun) rẹ̀, wọn kò sì níí sún (ìparun wọn) sẹ́yìn.
44Lẹ́yìn náà, A rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́ ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ ìjọ kan bá dé, wọ́n á pè é ní òpùrọ́. A sì mú apá kan wọn tẹ̀lé apá kan nínú ìparun. A tún sọ wọ́n di ìtàn. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ tí kò gbàgbọ́ ní òdodo.
45Lẹ́yìn náà, A rán (Ànábì) Mūsā àti ọmọ-ìyá rẹ̀ (Ànábì) Hārūn níṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé.
46(A rán wọn níṣẹ́) sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣègbéraga, wọ́n sì jẹ́ ìjọ olùjẹgàba.
47Wọ́n wí pé: “Ṣé kí á gba abara méjì bí irú wa gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹrú wa ni àwọn ènìyàn wọn?”
48Nítorí náà, wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. Wọ́n sì wà nínú àwọn olùparun.
49Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà.
50A ṣe ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ ní àmì kan. A sì ṣe ibùgbé fún àwọn méjèèjì sí ibi gíga kan, tó ní ibùgbé, tó sì ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú.[1]
51Ẹ̀yin Òjíṣẹ́, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa, kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú Èmi ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
52Àti pé dájúdájú (’Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.
53Ṣùgbọ́n wọ́n gé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn wọn láààrin ara wọn sí kélekèle. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun tó ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wọn.
54Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ sínú ìṣìnà wọn títí di ìgbà kan ná.
55Ṣé wọ́n ń lérò pé (bí) A ṣe ń fi dúkìá àti ọmọ nìkan ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn,
56ni A óò ṣe máa yára ti àwọn oore sí ọ̀dọ̀ wọn lọ (títí láéláé). Rárá, wọn kò fura ni![1]
57Dájúdájú àwọn tó ń páyà (ìṣírò-iṣẹ́) nípa ìpáyà wọn nínú Olúwa wọn;
58àti àwọn tó ń gba àwọn āyah Olúwa wọn gbọ́;
59àti àwọn tí kì í ṣẹbọ sí Olúwa wọn,
60àti àwọn tí wọ́n ń ṣe ohun wọ́n ń ṣe (nínú àwọn iṣẹ́ rere) pẹ̀lú ìbẹ̀rù nínú ọkàn wọn pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn;
61àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ń yára ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn sì ni aṣíwájú nínú (àwọn ẹ̀san) iṣẹ́ náà.
62Àti pé A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tírà kan tó ń sọ òdodo (nípa iṣẹ́ ẹ̀dá) ń bẹ lọ́dọ̀ Wa. A kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
63Àmọ́ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ wà nínú ìfọ́núfọ́ra nípa (al-Ƙur’ān) yìí. Àti pé wọ́n ní àwọn iṣẹ́ kan lọ́wọ́, tí ó yàtọ̀ sí iṣẹ́ rere yẹn.[1] Wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ náà
64títí di ìgbà tí A máa gbá àwọn onígbẹdẹmukẹ nínú wọn mú pẹ̀lú ìyà. Nígbà náà ni wọ́n máa kígbe (fún ìrànlọ́wọ́).
65Ẹ má ṣe kígbe (fún ìrànlọ́wọ́) ní òní. Dájúdájú kò sí ẹni tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lọ́dọ̀ Wa.
66Wọ́n kúkú ń ka àwọn āyah Mi fún yín. Àmọ́ ńṣe ni ẹ̀ ń fà sẹ́yìn (níbi òdodo).
67Ẹ̀ sì ń fi (Kaaba) ṣègbéraga, ẹ tún sọ ìsọkúsọ (nípa al-Ƙur’ān) ní alẹ́!
68Ṣé wọn kò ronú sí ọ̀rọ̀ náà ni? Tàbí ohun tó dé bá wọn jẹ́ ohun tí kò dé bá àwọn bàbá wọn àkọ́kọ́ rí ni?
69Tàbí wọn kò mọ Òjíṣẹ́ wọn mọ́ ni wọ́n fi di alátakò rẹ̀?
70Tàbí wọn ń wí pé àlùjànnú kan ń bẹ lára rẹ̀ ni? Rárá o. Ó mú òdodo wá bá wọn ni. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì jẹ́ olùkórira òdodo.
71Tí ó bá jẹ́ pé (Allāhu), Ọba Òdodo tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni, àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àwọn tó wà nínú wọn ìbá kúkú ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n A mú ìṣítí nípa ọ̀rọ̀ ara wọn wá fún wọn ni, wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbi ìṣítí (tí A mú wá fún) wọn.
72Tàbí ò ń béèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn ni? Owó-ọ̀yà Olúwa rẹ̀ lóore jùlọ. Àti pé Òun l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.[1]
73Àti pé dájúdájú ò ń pè wọ́n sójú ọ̀nà tààrà ni.
74Àwọn tí kò sì gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni wọ́n ń ṣẹ́rí kúrò lójú ọ̀nà náà.
75Tí ó bá jẹ́ pé A kẹ́ wọn (nílé ayé), tí A sì gbé gbogbo ìṣòro ara wọn kúrò fún wọn, wọn ìbá tún won̄koko mọ́ ìtayọ ẹnu-ààlà wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà (nínú ìṣìnà).
76Dájúdájú A fi ìyà jẹ wọ́n. Àmọ́ wọn kò tẹríba fún Olúwa wọn, wọn kò sì rawọ́ rasẹ̀ sí I
77títí di ìgbà tí A fi ṣílẹ̀kùn ìyà líle fún wọn; nígbà náà ni wọ́n sọ̀rètí nù.
78(Allāhu), Òun ni Ẹni tí Ó ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fún yín. Ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá sì kéré púpọ̀.
79Òun ni Ẹni tí Ó da yín sórí ilẹ̀, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n yóò ko yín jọ sí.
80Òun ni Ẹni tó ń sọ ẹ̀dá di alààyè, Ó ń sọ ẹ̀dá di òkú, tiRẹ̀ sì ni ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán, ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?
81Rárá (wọn kò níí ṣe làákàyè, ṣebí) irú ohun tí àwọn ẹni àkọ́kọ́ wí ni àwọn náà wí.
82Wọ́n wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé wọn yóò gbé wa dìde ni?
83Wọ́n kúkú ti ṣàdéhùn èyí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
84Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí Ó ni ilẹ̀ àti ẹni tí ó wà ní orí rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”
85Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?”
86Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ méjèèje àti Olúwa Ìtẹ́ ńlá?”
87Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
88Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”
89Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń dan yín?”
90Àmọ́ sá, òdodo ni A mú wá ba wọn. Dájúdájú àwọn sì ni òpùrọ́.
91Allāhu kò fi ẹnì kan kan ṣe ọmọ, kò sì sí ọlọ́hun kan pẹ̀lú Rẹ̀. (Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà, ọlọ́hun kọ̀ọ̀kan ìbá ti kó ẹ̀dá tó dá lọ, apá kan wọn ìbá sì borí apá kan. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀ nípa ọmọ bíbí).
92(Allāhu) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nítorí náà, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n fi ń ṣẹbọ sí I.
93Sọ pé: “Olúwa mi, Ó ṣeé ṣe kí Ó fi ohun tí wọ́n ń ṣèlérí rẹ̀ fún wọn hàn mí,
94Olúwa mi, má ṣe fi mí sínú ìjọ alábòsí.”
95Dájúdájú Àwa lágbára láti fi ohun tí A ṣèlérí rẹ̀ fún wọn hàn ọ́.
96Fi èyí tó dára tí àìdára dànù. Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n fi ń ròyìn (Wa).
97Sọ pé: “Olúwa mi, mò ń sádi Ọ́ níbi ròyíròyí t’àwọn aṣ-ṣaetọ̄n.
98Mò ń sádi Ọ́, Olúwa mi, níbi kí wọ́n wá bá mi.”
99(Wọ́n ń ṣẹ̀mí lọ) títí di ìgbà tí ikú fi máa dé bá ọ̀kan nínú wọn. Ó sì máa wí pé: “Olúwa mi, Ẹ dá mi padà (sílé ayé)
100nítorí kí èmi lè ṣe iṣẹ́ rere nínú èyí tí mo gbé jù sílẹ̀. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, dájúdájú ó jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí ó kàn ń wí ni, (àmọ́) gàgá ti wà ní ẹ̀yìn wọn títí di ọjọ́ tí A óò gbé wọn dìde.[1]
101Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, kò níí sí ìbátan láààrin wọn ní ọjọ́ yẹn, wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè.[1]
102Ẹnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n, àwọn wọ̀nyẹn ni olùjèrè.
103Ẹnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá fúyẹ́, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú iná Jahanamọ.
104Iná yóò máa jó wọn lójú. Wọn yó sì wà nínú rẹ̀, tí Iná yóò ti bà wọ́n lójú jẹ́.
105Ṣé wọ́n kì í ka àwọn āyah Mi fún yín ni, àmọ́ tí ẹ̀ ń pè é ní irọ́?
106Wọ́n wí pé: “Olúwa wa, orí burúkú ló kọlù wá; àwa sì jẹ́ ìjọ olùṣìnà.
107Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú Iná. Tí a bá fi lè padà (síbi iṣẹ́ ibi nílé ayé), dájúdájú nígbà náà alábòsí ni àwa.”
108(Allāhu) sọ pé: “Ẹ tẹ̀rì sínú rẹ̀. Ẹ má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀.”
109Dájúdájú igun kan wà nínú àwọn ẹrúsìn Mi, tí wọ́n ń sọ pé: “Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì l’óore jùlọ nínú àwọn aláàánú.”[1]
110Ṣùgbọ́n ẹ sọ wọ́n di oníyẹ̀yẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí àwọn yẹ̀yẹ́ (yín) fi mu yín gbàgbé ìrántí Mi. Ẹ̀yin sì ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín.
111Dájúdájú Mo san wọ́n ní ẹ̀san ní òní nítorí sùúrù wọn; dájúdájú àwọn gan-an ni olùjèrè.
112(Allāhu) sọ pé: “Ọdún mélòó ni ẹ̀yin (aláìgbàgbọ́) lò lórí ilẹ̀ ayé?”
113Wọ́n wí pé: “A lo ọjọ́ kan tàbí abala ọjọ́ kan, bi àwọn olùṣírò-ọjọ́ léèrè wò.”
114(Allāhu) sọ pé: “Ẹ kò gbé ilé ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀.”
115Ṣé ẹ lérò pé A kàn ṣẹ̀dá yín fún ìranù ni, àti pé dájúdájú wọn ò níí da yín padà sọ́dọ̀ Wa?”
116Nítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Olúwa Ìtẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé.
117Ẹni tí ó bá pe ọlọ́hun mìíràn pẹ̀lú Allāhu, kò ní ẹ̀rí lọ́wọ́ lórí rẹ̀. Dájúdájú ìṣírò-iṣẹ́ rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́ kò níí jèrè.
118Sọ pé: “Olúwa mi, ṣàforíjìn, kí O sì kẹ́ (mi). Ìwọ sì l’óore jùlọ nínú àwọn aláàánú.”[1]