الناس
Mankind • 6 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Sọ pé: “Mo sá di Olúwa àwọn ènìyàn,
2Ọba àwọn ènìyàn,
3Ọlọ́hun àwọn ènìyàn,[1]
4níbi aburú (aṣ-Ṣaetọ̄n) oníròyíròyí, olùsásẹ́yìn (fún ẹni tó bá ń dárúkọ Allāhu[1]).
5(aṣ-Ṣaetọ̄n ni) ẹni tí ó ń kó ròyíròyí sínú àwọn ọkàn ènìyàn.
6(Ṣaetọ̄n náà) wà nínú àwọn àlùjànnú àti àwọn ènìyàn.”