الطور
The Mount • 49 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Allāhu fi àpáta Tūr búra.
2Ó tún fi Tírà tí wọ́n kọ n̄ǹkan sínú rẹ̀ búra .
3(Wọ́n kọ̀ ọ́) sínú n̄ǹkan ìkọ̀wé tí wọ́n tẹ́ ojú rẹ̀ sílẹ̀.
4Allāhu fi Ilé tí àwọn mọlāika ń wọnú rẹ̀ ní ojoojúmọ́ nínú sánmọ̀ búra.
5Ó tún fi àjà tí wọ́n gbé sókè (ìyẹn, sánmọ̀) búra.
6Ó tún fi agbami odò tí wọ́n máa mú iná jáde nínú rẹ̀ búra.
7Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ máa ṣẹlẹ̀.
8Kò sí ẹni tí ó máa dènà rẹ̀.
9(Ó máa ṣẹlẹ̀) ní ọjọ́ tí sánmọ̀ máa mì tìtì tààrà.
10àpáta sì máa rìn lọ dànù.
11Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn tó pe òdodo ní irọ́,
12àwọn tí wọ́n wà nínú ìsọkúsọ, tí wọ́n ń ṣeré.
13(Rántí) ọjọ́ tí wọn yóò máa tì wọ́n lọ́ sínú iná Jahanamọ ní ìtìkutì.
14Èyí ni Iná náà tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.
15Ṣé idán ni èyí ni tàbí ẹ̀yin kò ríran?
16Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ. Ẹ fara dà á tàbí ẹ kò fara dà á, bákan náà ni fún yín. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san.
17Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà àti ìdẹ̀ra.
18Wọn yóò máa jẹ ìgbádùn pẹ̀lú ohun tí Olúwa wọn fún wọn. Àti pé (Allāhu) yóò ṣọ́ wọn kúrò níbi ìyà iná Jẹhīm.
19Ẹ máa jẹ, ẹ máa mu ní gbẹdẹmukẹ nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
20Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn tí wọ́n tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. A sì máa fún wọn ní àwọn ìyàwó ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́.
21Àti pé àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn tún tẹ̀lé wọn nínú ìgbàgbọ́ òdodo, A máa da àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn pọ̀ mọ́ wọn. A kò sì níí dín kiní kan kù nínú iṣẹ́ wọn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa dúró fún ohun tó ṣe níṣẹ́.
22A máa fún wọn ní àlékún èso àti ẹran tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí.
23Wọn yó sì máa gba ife ọtí mu láààrin ara wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kò sí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ àti ìwà ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
24Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. (Wọ́n) dà bí àlúùúlù (òkúta olówó-iye-bíye) tí wọ́n fi pamọ́ sínú apó rẹ̀.
25Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, wọn yó sì máa bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ara wọn.
26Wọn yóò sọ pé: “Dájúdájú tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àwa máa ń páyà láààrin àwọn ènìyàn wa.
27Ṣùgbọ́n Allāhu ṣàánú wa. Ó sì là wá kúrò níbi ìyà Iná.
28Dájúdájú àwa máa ń pè É tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olóore, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
29Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kì í ṣe adábigba tàbí wèrè lórí ìdẹ̀ra Olúwa rẹ.
30Tàbí wọ́n ń wí pé: “Eléwì kan tí à ń retí àpadàsí aburú fún ni.”
31Sọ pé: “Ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.
32Tàbí ọpọlọ wọn ló ń pa wọ́n láṣẹ èyí ni? Tàbí ìjọ alákọyọ ni wọ́n ni?
33Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni.” Rárá o, wọn kò gbàgbọ́ ni.
34Kí àwọn náà mú ọ̀rọ̀ kan bí irú rẹ̀ wá tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.
35Tàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn láì sí Aṣẹ̀dá? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni?
36Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Rárá o, wọn kò màmọ̀ dájú ni.
37Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni àwọn ilé ọrọ̀ Olúwa rẹ wà? Tàbí àwọn ni olùborí?
38Tàbí wọ́n ní àkàbà kan tí wọ́n ń fi gbọ́rọ̀ (nínú sánmọ̀)? Kí ẹni tí ó ń bá wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ mú ẹ̀rí tó yanjú wá?
39Tàbí àwọn ọmọbìnrin ni tiRẹ̀, àwọn ọmọkùnrin sì ni tiyín?
40Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?
41Tàbí ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń kọ ọ́ sílẹ̀?
42Tàbí wọ́n ń gbèrò ète kan ni? Nígbà náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn l’ó máa f’orí kó ète náà.
43Tàbí wọ́n ní ọlọ́hun kan lẹ́yìn Allāhu ni? Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
44Tí wọ́n bá rí apá kan nínú sánmọ̀ tó ya lúlẹ̀, wọ́n á wí pé: “Ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ ni (wọn kò níí gbàgbọ́).”
45Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ títí wọn yóò fi bá ọjọ́ wọn tí wọn máa pa wọ́n sínú rẹ̀ pàdé.
46Ọjọ́ tí ète wọn kò níí fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀. A kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
47Àti pé dájúdájú ìyà kan ń bẹ fún àwọn tó ṣàbòsí yàtọ̀ sí (ìyà ọ̀run) yẹn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
48Ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa Rẹ, dájúdájú ìwọ wà ní ojútó Wa. Kí ó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ nígbà tí o bá fẹ́ dìde.[1]
49Àti pé ní alẹ́ àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá kúrò níta tán[1], ṣàfọ̀mọ́ fún Un.