Ar-Rum

الروم

The Romans60 ayahsMeccan

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

الٓمٓ﴿١

1’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]

غُلِبَتِ ٱلرُّومُ﴿٢

2Wọ́n[1] ṣẹ́gun Rōmu

فِيٓ أَدۡنَى ٱلۡأَرۡضِ وَهُم مِّنۢ بَعۡدِ غَلَبِهِمۡ سَيَغۡلِبُونَ﴿٣

3ní àwọn ilẹ̀ tó wà nítòsí (erékùsù Lárúbáwá).[1] Lẹ́yìn ìṣẹ́gun wọn, àwọn náà máa ṣẹ́gun wọn

فِي بِضۡعِ سِنِينَۗ لِلَّهِ ٱلۡأَمۡرُ مِن قَبۡلُ وَمِنۢ بَعۡدُۚ وَيَوۡمَئِذٖ يَفۡرَحُ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ﴿٤

4ní ọdún díẹ̀ (sí ìgbà náà). Ti Allāhu ni àṣẹ ní ìṣáájú àti ní ìkẹ́yìn. Ní ọjọ́ yẹn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo máa dunnú

بِنَصۡرِ ٱللَّهِۚ يَنصُرُ مَن يَشَآءُۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ﴿٥

5sí àrànṣe Allāhu. Ó ń ṣàrànṣe fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

وَعۡدَ ٱللَّهِۖ لَا يُخۡلِفُ ٱللَّهُ وَعۡدَهُۥ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ﴿٦

6(Èyí jẹ́) àdéhùn Allāhu. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.

يَعۡلَمُونَ ظَٰهِرٗا مِّنَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَهُمۡ عَنِ ٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ غَٰفِلُونَ﴿٧

7Wọ́n nímọ̀ nípa gban̄gba nínú ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Afọ́nú-fọ́ra sì ni wọ́n nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

أَوَلَمۡ يَتَفَكَّرُواْ فِيٓ أَنفُسِهِمۗ مَّا خَلَقَ ٱللَّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَآ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَأَجَلٖ مُّسَمّٗىۗ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلنَّاسِ بِلِقَآيِٕ رَبِّهِمۡ لَكَٰفِرُونَ﴿٨

8Ṣé wọn kò ronú nípa ọ̀rọ̀ ara wọn ni? Allāhu kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn.

أَوَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَانُوٓاْ أَشَدَّ مِنۡهُمۡ قُوَّةٗ وَأَثَارُواْ ٱلۡأَرۡضَ وَعَمَرُوهَآ أَكۡثَرَ مِمَّا عَمَرُوهَا وَجَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِۖ فَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيَظۡلِمَهُمۡ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ﴿٩

9Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n fi ilẹ̀ dáko. Wọ́n sì lo ilẹ̀ fún ohun tí ó pọ̀ ju bí (àwọn ará Mọkkah) ṣe lò ó. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sì mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Nítorí náà, Allāhu kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.

ثُمَّ كَانَ عَٰقِبَةَ ٱلَّذِينَ أَسَٰٓـُٔواْ ٱلسُّوٓأَىٰٓ أَن كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَكَانُواْ بِهَا يَسۡتَهۡزِءُونَ﴿١٠

10Lẹ́yìn náà, aburú jẹ́ àtubọ̀tán àwọn tó ṣaburú nítorí pé, wọ́n pe àwọn āyah Allāhu ní irọ́. Wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́.

ٱللَّهُ يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ ثُمَّ إِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ﴿١١

11Allāhu ń pilẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, O máa dá a padà (sípò alààyè). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.

وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يُبۡلِسُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ﴿١٢

12Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yó sọ̀rètí nù.

وَلَمۡ يَكُن لَّهُم مِّن شُرَكَآئِهِمۡ شُفَعَٰٓؤُاْ وَكَانُواْ بِشُرَكَآئِهِمۡ كَٰفِرِينَ﴿١٣

13Àti pé kò níí sí àwọn olùṣìpẹ̀ fún wọn nínú àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì máa jẹ́ alátakò òrìṣà wọn.

وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يَوۡمَئِذٖ يَتَفَرَّقُونَ﴿١٤

14Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, ní ọjọ́ yẹn ni wọn yóò pínyà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَهُمۡ فِي رَوۡضَةٖ يُحۡبَرُونَ﴿١٥

15Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, wọn yóò wà ní àbàtà Ọgbà Ìdẹ̀ra,[1] tí wọn yó sì máa dùn wọ́n nínú.

وَأَمَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَلِقَآيِٕ ٱلۡأٓخِرَةِ فَأُوْلَٰٓئِكَ فِي ٱلۡعَذَابِ مُحۡضَرُونَ﴿١٦

16Ní ti àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pe àwọn āyah Wa àti ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni (àwọn mọlāika) máa kó wá sínú Iná.

فَسُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ حِينَ تُمۡسُونَ وَحِينَ تُصۡبِحُونَ﴿١٧

17Nítorí náà, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu nígbà tí ẹ bá wà ní ìrọ̀lẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní òwúrọ̀.

وَلَهُ ٱلۡحَمۡدُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَعَشِيّٗا وَحِينَ تُظۡهِرُونَ﴿١٨

18TiRẹ̀ sì ni ọpẹ́ nínú àwọn sánmọ̀ àti lórí ilẹ̀ ní àṣálẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní ọ̀sán.

يُخۡرِجُ ٱلۡحَيَّ مِنَ ٱلۡمَيِّتِ وَيُخۡرِجُ ٱلۡمَيِّتَ مِنَ ٱلۡحَيِّ وَيُحۡيِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَاۚ وَكَذَٰلِكَ تُخۡرَجُونَ﴿١٩

19(Allāhu) ń yọ alààyè jáde láti ara òkú. Ó ń yọ òkú jáde láti ara alààyè. Ó ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Báyẹn ni A óò ṣe mu ẹ̀yin náà jáde.

وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَنۡ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٖ ثُمَّ إِذَآ أَنتُم بَشَرٞ تَنتَشِرُونَ﴿٢٠

20Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà náà ẹ̀yin di abara tí ẹ̀ ń fọ́nká (lórí ilẹ̀ ayé).

وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَنۡ خَلَقَ لَكُم مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ أَزۡوَٰجٗا لِّتَسۡكُنُوٓاْ إِلَيۡهَا وَجَعَلَ بَيۡنَكُم مَّوَدَّةٗ وَرَحۡمَةًۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ﴿٢١

21Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá àwọn aya fún yín láti ara yín nítorí kí ẹ lè rí ìfàyàbalẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì fi ìfẹ́ àti ìkẹ́ sí ààrin yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó láròjinlẹ̀.

وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦ خَلۡقُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱخۡتِلَٰفُ أَلۡسِنَتِكُمۡ وَأَلۡوَٰنِكُمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّلۡعَٰلِمِينَ﴿٢٢

22Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀, dídá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn èdè yín àti àwọn àwọ̀ ara yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onímọ̀.

وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦ مَنَامُكُم بِٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَٱبۡتِغَآؤُكُم مِّن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَسۡمَعُونَ﴿٢٣

23Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni oorun yín ní alẹ́ àti ní ọ̀sán àti wíwá tí ẹ̀ ń wá nínú oore Rẹ̀ (fún ìjẹ-ìmu). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń gbọ́rọ̀.

وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦ يُرِيكُمُ ٱلۡبَرۡقَ خَوۡفٗا وَطَمَعٗا وَيُنَزِّلُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَيُحۡيِۦ بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَآۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ﴿٢٤

24Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni fífi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ti ẹ̀rù àti ìrètí. Ó sì ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó ń fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń ṣe làákàyè.

وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَن تَقُومَ ٱلسَّمَآءُ وَٱلۡأَرۡضُ بِأَمۡرِهِۦۚ ثُمَّ إِذَا دَعَاكُمۡ دَعۡوَةٗ مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ إِذَآ أَنتُمۡ تَخۡرُجُونَ﴿٢٥

25Àti pé nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá pè yín ní ìpè kan nígbà náà ni ẹ̀yin yóò máa jáde láti inú ilẹ̀.

وَلَهُۥ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ كُلّٞ لَّهُۥ قَٰنِتُونَ﴿٢٦

26TiRẹ̀ ni àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀.[1]

وَهُوَ ٱلَّذِي يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ وَهُوَ أَهۡوَنُ عَلَيۡهِۚ وَلَهُ ٱلۡمَثَلُ ٱلۡأَعۡلَىٰ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ﴿٢٧

27Òun ni Ẹni tí Ó ń bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sípò alààyè fún àjíǹde). Ó sì rọrùn jùlọ fún Un (láti ṣe bẹ́ẹ̀). TiRẹ̀ ni ìròyìn tó ga jùlọ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀.[1] Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

ضَرَبَ لَكُم مَّثَلٗا مِّنۡ أَنفُسِكُمۡۖ هَل لَّكُم مِّن مَّا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُم مِّن شُرَكَآءَ فِي مَا رَزَقۡنَٰكُمۡ فَأَنتُمۡ فِيهِ سَوَآءٞ تَخَافُونَهُمۡ كَخِيفَتِكُمۡ أَنفُسَكُمۡۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ﴿٢٨

28(Allāhu) ṣàkàwé kan fún yín nípa ara yín. Ǹjẹ́ ẹ ní akẹgbẹ́ nínú àwọn ẹrú yín lórí ohun tí A fún yín ní arísìkí, tí ẹ jọ máa pín (dúkìá náà) ní dọ́gban̄dọ́gba, tí ẹ ó sì máa páyà wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń páyà ara yin náà? Báyẹn ni A ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó ń ṣe làákàyè.[1]

بَلِ ٱتَّبَعَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓاْ أَهۡوَآءَهُم بِغَيۡرِ عِلۡمٖۖ فَمَن يَهۡدِي مَنۡ أَضَلَّ ٱللَّهُۖ وَمَا لَهُم مِّن نَّٰصِرِينَ﴿٢٩

29Ńṣe ni àwọn tó ṣàbòsí tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn láì sí ìmọ̀ kan (fún wọn). Ta sì ni ó lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà? Kò sì níí sí àwọn alárànṣe fún wọn.

فَأَقِمۡ وَجۡهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفٗاۚ فِطۡرَتَ ٱللَّهِ ٱلَّتِي فَطَرَ ٱلنَّاسَ عَلَيۡهَاۚ لَا تَبۡدِيلَ لِخَلۡقِ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ ٱلدِّينُ ٱلۡقَيِّمُ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ﴿٣٠

30Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn Islām, ẹ̀sìn àdámọ́ Allāhu èyí tí Ó dá mọ́ àwọn ènìyàn. Kò sí ìyípadà fún ẹ̀sìn Allāhu.[1] (ìyẹn ni pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ yí ẹ̀sìn Allāhu padà.)[2] Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.[3]

۞ مُنِيبِينَ إِلَيۡهِ وَٱتَّقُوهُ وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَلَا تَكُونُواْ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ﴿٣١

31(Ẹ jẹ́) olùṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Ẹ páyà Rẹ̀. Ẹ kí ìrun. Ẹ má ṣe wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.

مِنَ ٱلَّذِينَ فَرَّقُواْ دِينَهُمۡ وَكَانُواْ شِيَعٗاۖ كُلُّ حِزۡبِۭ بِمَا لَدَيۡهِمۡ فَرِحُونَ﴿٣٢

32(Ẹ má ṣe wà) nínú àwọn tó dá ẹ̀sìn wọn sí kélekèle, tí wọ́n sì di ìjọ-ìjọ. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun tí ó wà lọ́dọ̀ wọn.

وَإِذَا مَسَّ ٱلنَّاسَ ضُرّٞ دَعَوۡاْ رَبَّهُم مُّنِيبِينَ إِلَيۡهِ ثُمَّ إِذَآ أَذَاقَهُم مِّنۡهُ رَحۡمَةً إِذَا فَرِيقٞ مِّنۡهُم بِرَبِّهِمۡ يُشۡرِكُونَ﴿٣٣

33Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, wọn yóò pe Olúwa wọn, tí wọn yóò máa ṣẹ́rí padà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí (Allāhu) bá fún wọn ní ìkẹ́ kan tọ́ wò láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, nígbà náà ni igun kan nínú wọn yóò máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn

لِيَكۡفُرُواْ بِمَآ ءَاتَيۡنَٰهُمۡۚ فَتَمَتَّعُواْ فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ﴿٣٤

34nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí ohun tí (Allāhu) fún wọn. Ẹ máa jayé lọ. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

أَمۡ أَنزَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ سُلۡطَٰنٗا فَهُوَ يَتَكَلَّمُ بِمَا كَانُواْ بِهِۦ يُشۡرِكُونَ﴿٣٥

35Tàbí A sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún wọn, tó ń sọ̀rọ̀ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀?

وَإِذَآ أَذَقۡنَا ٱلنَّاسَ رَحۡمَةٗ فَرِحُواْ بِهَاۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةُۢ بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡ إِذَا هُمۡ يَقۡنَطُونَ﴿٣٦

36Nígbà tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò, wọn yóò dunnú sí i. Tí aburú kan bá sì kàn wọ́n nípa ohun tí ọwọ́ wọn tì síwájú, nígbà náà ni wọn yóò sọ̀rètí nù.

أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ﴿٣٧

37Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́, (Ó sì ń) díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́)? Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó gbàgbọ́.

فَـَٔاتِ ذَا ٱلۡقُرۡبَىٰ حَقَّهُۥ وَٱلۡمِسۡكِينَ وَٱبۡنَ ٱلسَّبِيلِۚ ذَٰلِكَ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ يُرِيدُونَ وَجۡهَ ٱللَّهِۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ﴿٣٨

38Nítorí náà, fún ẹbí ni ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá ní n̄ǹkan). Ìyẹn lóore jùlọ fún àwọn tó ń fẹ́ Ojú rere Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.

وَمَآ ءَاتَيۡتُم مِّن رِّبٗا لِّيَرۡبُوَاْ فِيٓ أَمۡوَٰلِ ٱلنَّاسِ فَلَا يَرۡبُواْ عِندَ ٱللَّهِۖ وَمَآ ءَاتَيۡتُم مِّن زَكَوٰةٖ تُرِيدُونَ وَجۡهَ ٱللَّهِ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُضۡعِفُونَ﴿٣٩

39Ohunkóhun tí ẹ bá fún (àwọn ènìyàn) ní ẹ̀yáwó, nítorí kí ó lè di èlé láti ara dúkìá àwọn ènìyàn, kò lè lékún ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohunkóhun tí ẹ bá sì (fún àwọn ènìyàn) ní Zakāh, tí ẹ̀ ń fẹ́ ojú rere Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún ní àdìpèlé ẹ̀san.

ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَكُمۡ ثُمَّ رَزَقَكُمۡ ثُمَّ يُمِيتُكُمۡ ثُمَّ يُحۡيِيكُمۡۖ هَلۡ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَفۡعَلُ مِن ذَٰلِكُم مِّن شَيۡءٖۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ﴿٤٠

40Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín, lẹ́yìn náà, Ó fún yín ní arísìkí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà, O máa sọ yín di alààyè. Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tí ó lè ṣe n̄ǹkan kan nínú ìyẹn? Mímọ́ ni fún Un. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

ظَهَرَ ٱلۡفَسَادُ فِي ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِ بِمَا كَسَبَتۡ أَيۡدِي ٱلنَّاسِ لِيُذِيقَهُم بَعۡضَ ٱلَّذِي عَمِلُواْ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ﴿٤١

41Ìbàjẹ́ hàn lórí ilẹ̀ àti lójú omi nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ àwọn ènìyàn ṣe níṣẹ́ (aburú) nítorí kí (Allāhu) lè fi (ìyà) apá kan èyí tí wọ́n ṣe níṣẹ́ (aburú) tọ́ wọn lẹ́nu wò nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (níbi aburú).

قُلۡ سِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلُۚ كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّشۡرِكِينَ﴿٤٢

42Sọ pé: “Ẹ rìn lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí àtubọ̀tán àwọn tó ṣíwájú ṣe rí! Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n jẹ́ ọ̀ṣẹbọ.”

فَأَقِمۡ وَجۡهَكَ لِلدِّينِ ٱلۡقَيِّمِ مِن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَ يَوۡمٞ لَّا مَرَدَّ لَهُۥ مِنَ ٱللَّهِۖ يَوۡمَئِذٖ يَصَّدَّعُونَ﴿٤٣

43Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀rinlẹ̀ ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé, tí kò sí n̄ǹkan tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́dọ̀ Allāhu. Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ènìyàn yóò pínyà sí (èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò Iná).

مَن كَفَرَ فَعَلَيۡهِ كُفۡرُهُۥۖ وَمَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا فَلِأَنفُسِهِمۡ يَمۡهَدُونَ﴿٤٤

44Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, orí ara rẹ̀ ni (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń tẹ́ ìtẹ́ (Ọgbà Ìdẹ̀ra) sílẹ̀ fún

لِيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ مِن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلۡكَٰفِرِينَ﴿٤٥

45nítorí kí (Allāhu) lè san ẹ̀san rere nínú oore àjùlọ Rẹ̀ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́.

وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَن يُرۡسِلَ ٱلرِّيَاحَ مُبَشِّرَٰتٖ وَلِيُذِيقَكُم مِّن رَّحۡمَتِهِۦ وَلِتَجۡرِيَ ٱلۡفُلۡكُ بِأَمۡرِهِۦ وَلِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ﴿٤٦

46Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé, Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró ìdùnnú. Àti pé nítorí kí (Allāhu) lè fún yín tọ́ wò nínú ìkẹ́ Rẹ̀; àti nítorí kí ọkọ̀ ojú-omi lè rìn lójú-omi pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.

وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ رُسُلًا إِلَىٰ قَوۡمِهِمۡ فَجَآءُوهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَٱنتَقَمۡنَا مِنَ ٱلَّذِينَ أَجۡرَمُواْۖ وَكَانَ حَقًّا عَلَيۡنَا نَصۡرُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ﴿٤٧

47Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ sí àwọn ìjọ wọn. Wọ́n sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. A sì gbẹ̀san lára àwọn tó dẹ́ṣẹ̀. Ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ fún wa láti ṣe àrànṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

ٱللَّهُ ٱلَّذِي يُرۡسِلُ ٱلرِّيَٰحَ فَتُثِيرُ سَحَابٗا فَيَبۡسُطُهُۥ فِي ٱلسَّمَآءِ كَيۡفَ يَشَآءُ وَيَجۡعَلُهُۥ كِسَفٗا فَتَرَى ٱلۡوَدۡقَ يَخۡرُجُ مِنۡ خِلَٰلِهِۦۖ فَإِذَآ أَصَابَ بِهِۦ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦٓ إِذَا هُمۡ يَسۡتَبۡشِرُونَ﴿٤٨

48Allāhu ni Ẹni tó ń fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa gbé ẹ̀ṣújò dìde. (Allāhu) yó sì tẹ́ (ẹ̀ṣújò) sílẹ̀ s’ójú sánmọ̀ bí Ó bá ṣe fẹ́. Ó sì máa dá a kélekèle (sí ojú sánmọ̀). O sì máa rí òjò tí ó ma máa jáde láààrin rẹ̀. Nígbà tí Ó bá sì rọ (òjò náà) fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, nígbà náà wọn yó sì máa dunnú.

وَإِن كَانُواْ مِن قَبۡلِ أَن يُنَزَّلَ عَلَيۡهِم مِّن قَبۡلِهِۦ لَمُبۡلِسِينَ﴿٤٩

49Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú kí Ó tó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún wọn, wọ́n ti sọ̀rètí nù ṣíwájú rẹ̀.

فَٱنظُرۡ إِلَىٰٓ ءَاثَٰرِ رَحۡمَتِ ٱللَّهِ كَيۡفَ يُحۡيِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَآۚ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ﴿٥٠

50Nítorí náà, wòye sí àwọn orípa ìkẹ́ Allāhu, (wo) bí (Allāhu) ṣe ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú (Allāhu) yẹn ni Ó kúkú máa sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

وَلَئِنۡ أَرۡسَلۡنَا رِيحٗا فَرَأَوۡهُ مُصۡفَرّٗا لَّظَلُّواْ مِنۢ بَعۡدِهِۦ يَكۡفُرُونَ﴿٥١

51Dájúdájú tí A bá rán atẹ́gùn kan (sí wọn), kí wọ́n sì rí (n̄ǹkan ọ̀gbìn wọn) ní pípọ́n (jíjóná), dájúdájú wọn yó sì máa ṣàì moore lọ lẹ́yìn rẹ̀.

فَإِنَّكَ لَا تُسۡمِعُ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَلَا تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ ٱلدُّعَآءَ إِذَا وَلَّوۡاْ مُدۡبِرِينَ﴿٥٢

52Dájúdájú ìwọ kọ́ l’o máa mú àwọn òkú gbọ́rọ̀. O ò sì níí mú àwọn adití gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí ọ, tí wọ́n ń lọ.

وَمَآ أَنتَ بِهَٰدِ ٱلۡعُمۡيِ عَن ضَلَٰلَتِهِمۡۖ إِن تُسۡمِعُ إِلَّا مَن يُؤۡمِنُ بِـَٔايَٰتِنَا فَهُم مُّسۡلِمُونَ﴿٥٣

53Ìwọ kọ́ l’o máa fi ọ̀nà mọ àwọn afọ́jú níbi ìṣìnà wọn. Kò sí ẹni tí o máa mú gbọ́ ọ̀rọ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àwọn āyah Wa gbọ́. Àwọn sì ni (mùsùlùmí) olùjupá-jusẹ̀-sílẹ̀ fún Allāhu.[1]

۞ ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن ضَعۡفٖ ثُمَّ جَعَلَ مِنۢ بَعۡدِ ضَعۡفٖ قُوَّةٗ ثُمَّ جَعَلَ مِنۢ بَعۡدِ قُوَّةٖ ضَعۡفٗا وَشَيۡبَةٗۚ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ وَهُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡقَدِيرُ﴿٥٤

54Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti (ara n̄ǹkan) lílẹ, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn lílẹ Ó fun (yín ní) agbára, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn agbára, Ó tún fi lílẹ àti ogbó (si yín lára). Ó ń dá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Onímọ̀, Alágbára.

وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يُقۡسِمُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ مَا لَبِثُواْ غَيۡرَ سَاعَةٖۚ كَذَٰلِكَ كَانُواْ يُؤۡفَكُونَ﴿٥٥

55Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá ṣẹlẹ̀ (ìyẹn, ọjọ́ Àjíǹde), àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò máa búra pé àwọn kò gbé (ilé ayé) ju àkókò kan lọ.” Báyẹn ni wọ́n ṣe máa ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo.

وَقَالَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ وَٱلۡإِيمَٰنَ لَقَدۡ لَبِثۡتُمۡ فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡبَعۡثِۖ فَهَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡبَعۡثِ وَلَٰكِنَّكُمۡ كُنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ﴿٥٦

56Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ àti ìgbàgbọ́ òdodo yóò sọ pé: “Dájúdájú nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu, ẹ ti gbé ilé ayé títí Ọjọ́ Àjíǹde (fi tó). Nítorí náà, èyí ni Ọjọ́ Àjíǹde, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mọ̀.”

فَيَوۡمَئِذٖ لَّا يَنفَعُ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مَعۡذِرَتُهُمۡ وَلَا هُمۡ يُسۡتَعۡتَبُونَ﴿٥٧

57Nítorí náà ní ọjọ́ yẹn, àwọn tó ṣàbòsí, àwáwí wọn kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.

وَلَقَدۡ ضَرَبۡنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ مِن كُلِّ مَثَلٖۚ وَلَئِن جِئۡتَهُم بِـَٔايَةٖ لَّيَقُولَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا مُبۡطِلُونَ﴿٥٨

58A kúkú ti fi oríṣiríṣi àkàwé lélẹ̀ nínú al-Ƙur’ān yìí fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú tí o bá mú āyah kan wá fún wọn, dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: “Ẹ̀yin (Òjíṣẹ́) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe òpùrọ́.”

كَذَٰلِكَ يَطۡبَعُ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ﴿٥٩

59Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí dí ọkàn àwọn tí kò nímọ̀.

فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞۖ وَلَا يَسۡتَخِفَّنَّكَ ٱلَّذِينَ لَا يُوقِنُونَ﴿٦٠

60Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí kò mọ àmọ̀dájú (nípa Ọjọ́ ẹ̀san) sọ ọ́ di òpè (bí irú wọn).

RELATED SURAHS