القصص
The Stories • 88 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Tọ̄ sīn mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
2Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
3À ń ké nínú ìró (Ànábì) Mūsā àti Fir‘aon fún ọ pẹ̀lú òdodo nítorí ìjọ tó gbàgbọ́ lódodo.
4Dájúdájú Fir‘aon ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Ó ṣe àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìjọ-ìjọ; Ó ń sọ igun kan nínú wọn di ọ̀lẹ, ó ń pa àwọn ọmọkùnrin wọn, ó sì ń dá àwọn obìnrin wọn sí. Dájúdájú ó wà nínú àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
5A sì fẹ́ ṣèdẹ̀ra fún àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ lórí ilẹ̀, A (fẹ́) ṣe wọ́n ní aṣíwájú. A sì (fẹ́) kí wọ́n jogún (ilẹ̀).
6A (fẹ́) gbà wọ́n láàyè lórí ilẹ̀. Láti ara wọn, A sì (fẹ́) fi han Fir‘aon àti Hāmọ̄n pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì ohun tí wọ́n ń ṣọ́ra fún lára wọn.
7A sì ránṣẹ́ sí ìyá (Ànábì) Mūsā pé: “Fún un ní ọmú mu. Tí o bá sì ń páyà lórí rẹ̀, jù ú sínú odò. Má ṣe bẹ̀rù. Má sì ṣe banújẹ́. Dájúdájú Àwa máa dá a padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. A ó sì ṣe é ní ara àwọn Òjíṣẹ́.”
8Nígbà náà, àwọn ènìyàn Fir‘aon rí i he nítorí kí ó lè jẹ́ ọ̀tá àti ìbànújẹ́ fún wọn. Dájúdájú Fir‘aon, Hāmọ̄n àti àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì, wọ́n jẹ́ aláṣìṣe.
9Ìyàwó Fir‘aon wí pé: “Ìtutù-ojú ni (ọmọ yìí) fún èmi àti ìwọ. Ẹ má ṣe pa á. Ó lè jẹ́ pé ó máa ṣe wá ní àǹfààní tàbí kí a fi ṣe ọmọ.” Wọn kò sì fura.
10Ọkàn ìyá (Ànábì) Mūsā pami (lórí ọ̀rọ̀ Mūsā, kò sì rí n̄ǹkan mìíràn rò mọ́ tayọ rẹ̀) ó kúkú fẹ́ẹ̀ ṣàfi hàn rẹ̀ (pé ọmọ òun ni nígbà tí wọ́n pè é dé ọ̀dọ̀ Fir‘aon) tí kò bá jẹ́ pé A kì í lọ́kàn nítorí kí ó lè wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
11Ó sì sọ fún arábìnrin rẹ̀ pé: “Tọ ipa rẹ̀ lọ.” Ó sì ń wò ó láti ibi tó jìnnà. Wọn kò sì fura (sí i).
12A kò sì jẹ́ kí ó mu ọyàn (mìíràn) ṣíwájú (tìyá rẹ̀.) (Arábìnrin rẹ̀ sì) wí pé: “Ṣé kí èmi júwe yín sí ará ilé kan tí ó máa gbà á tọ́ fún yín? Wọn yó sì jẹ́ olùtọ́jú rẹ̀.”
13A sì dá a padà sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ nítorí kí ojú rẹ̀ lè tutù (fún ìdùnnú) àti nítorí kí ó má baà banújẹ́. Àti pé nítorí kí ó lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu, òdodo ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
14Nígbà tí ó dàgbà dáadáa, tí ó di géńdé, A fún un ní ọgbọ́n àti ìmọ̀. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
15Ó wọ inú ìlú nígbà tí àwọn ará ìlú ti gbàgbé (nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀).[1] Ó rí àwọn ọkùnrin méjì kan tí wọ́n ń bara wọn jà. Èyí wá láti inú ìran rẹ̀. Èyí sì wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Èyí tí ó wá láti inú ìran rẹ̀ wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ lórí èyí tí ó wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Mūsā kàn án ní ẹ̀ṣẹ́. Ó sì pa á. Ó sọ pé: “Èyí wà nínú iṣẹ́ aṣ-ṣaetọ̄n. Dájúdájú (aṣ-ṣaetọ̄n) ni ọ̀tá aṣini-lọ́nà pọ́nńbélé.”
16Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Nítorí náà, foríjìn mí.” Ó sì foríjìn ín. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
17Ó sọ pé: “Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe ìkẹ́ fún mi, èmi kò níí jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
18Nítorí náà, ó di ẹni tó ń bẹ̀rù nínú ìlú, ó sì ń retí (ẹ̀hónú ìran Fir‘aon). Nígbà náà ni ẹni tí ó wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní àná tún ń lọgun rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Mūsā sọ fún un pé: “Dájúdájú ìwọ ni olùṣìnà pọ́nńbélé.”
19Àmọ́ nígbà tí ó fẹ́ gbá ẹni tí ó jẹ́ ọ̀tá fún àwọn méjèèjì mú, ẹni náà wí pé: “Mūsā, ṣé o fẹ́ pa mí bí ó ṣe pa ẹnì kan ní àná? O ò gbèrò kan tayọ kí o jẹ́ aláìlójú-àánú lórí ilẹ̀; o ò sì gbèrò láti wà nínú àwọn alátùn-únṣe.”
20Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Mūsā, dájúdájú àwọn ìjòyè ń dá ìmọ̀ràn lórí rẹ láti pa ọ́. Nítorí náà, jáde (kúrò nínú ìlú), dájúdájú èmi wà nínú àwọn onímọ̀ràn rere fún ọ.”
21Ó sì jáde kúrò nínú (ìlú) pẹ̀lú ìpáyà, tí ó ń retí (ẹ̀hónú wọn), ó sì sọ pé: “Olúwa mi, là mí lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”
22Nígbà tí ó sì dojú kọ ọ̀kánkán ìlú Mọdyan, ó sọ pé: “Ó súnmọ́ kí Olúwa mi fọ̀nà tààrà (sí ìlú Mọdyan) mọ̀ mí.”
23Nígbà tí ó dé ibi (kànǹga) omi (ìlú) Mọdyan, ó bá ìjọ ènìyàn kan níbẹ̀ tí wọ́n ń fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn ní omi mu. Lẹ́yìn wọn, ó tún rí àwọn obìnrin méjì kan tí wọ́n ń fà sẹ́yìn (pẹ̀lú ẹran-ọ̀sìn wọn). Ó sọ pé: “Kí l’ó ṣe ẹ̀yin méjèèjì?” Wọ́n sọ pé: “A kò lè fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wa ní omi mu títí àwọn adaran bá tó kó àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn lọ. Àgbàlágbà arúgbó sì ni bàbá wa.”
24Ó sì bá wọn fún (ẹran-ọ̀sìn) wọn ní omi mu. Lẹ́yìn náà, ó padà síbi ibòji, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi bùkátà sí ohun tí O bá sọ̀kalẹ̀ fún mi nínú oore.”
25Ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì wá bá a, ó sì ń rìn pẹ̀lú ìtìjú, ó sọ pé: “Dájúdájú bàbá mi ń pè ọ́ nítorí kí ó lè san ọ́ ní ẹ̀san omi tí o fún (àwọn ẹran-ọ̀sìn) wa mu.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ ìtàn (ara rẹ̀) fún un. (Bàbá náà) sọ pé: “Má bẹ̀rù. O ti là lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”
26Ọ̀kan nínú (àwọn ọmọbìnrin) méjèèjì sọ pé: “Bàbá mi o, gbà á síṣẹ́. Dájúdájú ẹni tó dára jùlọ tí o lè gbà síṣẹ́ ni alágbára, olùfọkàntán.”
27Ó sọ pé: “Dájúdájú mo fẹ́ fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin mi méjèèjì wọ̀nyí fún ọ ní aya lórí (àdéhùn) pé o máa bá mi ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́jọ. Ṣùgbọ́n tí o bá ṣe é pé ọdún mẹ́wàá, láti ọ̀dọ̀ rẹ nìyẹn. Èmi kò sì fẹ́ kó ìnira bá ọ. Tí Allāhu bá fẹ́, o máa rí mi pé mo wà nínú àwọn ẹni rere.”
28(Mūsā) sọ pé: “(Àdéhùn) yìí wà láààrin èmi àti ìwọ. Èyíkéyìí tí mo bá mú ṣẹ nínú àdéhùn méjèèjì náà, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣàbòsí sí mi. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí).”
29Nígbà tí Mūsā parí àkókò náà, ó mú ará ilé rẹ̀ rin (ìrìn-àjò). Ó sì rí iná kan ní ẹ̀bá àpáta. Ó sọ fún ará ilé rẹ̀ pé: “Ẹ dúró (síbí ná). Èmi rí iná kan. Ó ṣe é ṣe kí n̄g mú ìró kan wá ba yín láti ibẹ̀ tàbí (kí n̄g mú) ògúnná kan wá nítorí kí ẹ lè rí ohun yẹ́ná.”
30Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é níbi etí àfonífojì ní ọwọ́ ọ̀tún (rẹ̀) ní àyè ìbùkún láti ibi igi náà. (A sọ pé): “Mūsā, dájúdájú Èmi (tí Mò ń bá ọ sọ̀rọ̀), Èmi ni Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
31Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀.” (Ó sì jù ú sílẹ̀). Nígbà tí ó rí i tó ń mira bí ẹni pé ejò ni, Mūsā pẹ̀yìndà, ó ń sá lọ́, kò sì padà sẹ́yìn. (Allāhu sọ pé): “Mūsā, máa bọ̀ padà, má sì ṣe páyà. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn olùfàyàbalẹ̀.
32Ti ọwọ́ rẹ bọ igbá-àyà ẹ̀wù rẹ, ó sì máa jáde ní funfun tí kì í ṣe ti aburú. Pa ọwọ́ rẹ mọ́ra níbi ẹ̀rù.[1] Nítorí náà, àwọn ẹ̀rí méjì nìwọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”
33(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi pa ẹnì kan nínú wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí.
34Àti pé arákùnrin mi Hārūn, ó dá láhọ́n jù mí lọ. Nítorí náà, rán an níṣẹ́ pẹ̀lú mi, kí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí yóò máa jẹ́rìí sí òdodo ọ̀rọ̀ mi. Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.”
35(Allāhu) sọ pé: “A máa fi arákùnrin rẹ kún ọ lọ́wọ́. A sì máa fún ẹ̀yin méjèèjì ní agbára, wọn kò níí lè dé ọ̀dọ̀ ẹ̀yin méjèèjì. Pẹ̀lú àwọn àmì Wa, ẹ̀yin méjèèjì àti àwọn tó bá tẹ̀lé ẹ̀yin méjèèjì l’ó máa borí.”
36Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé bá wọn pẹ̀lú àwọn àmì Wa tó yanjú, wọ́n wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán àdáhun. A kò gbọ́ èyí (rí) láààrin àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
37(Ànábì) Mūsā sì sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mú ìmọ̀nà wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ àti ẹni tí àtubọ̀tán ilé (ìkẹ́) máa jẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”
38Fir‘aon wí pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, èmi kò mọ̀ pé ọlọ́hun kan tún wà lẹ́yìn mi fún yín! Nítorí náà, Hāmọ̄n, dá iná fún mi, kí o fi mọ amọ̀, kí o sì kọ́ ilé gíga kan fún mi nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā. (Nítorí pé) dájúdájú mò ń rò ó sí ara àwọn òpùrọ́.”
39Òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì ṣègbéraga lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì rò pé dájúdájú A ò níí dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Wa.
40Nítorí náà, A gbá òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mú; A jù wọ́n sínú agbami odò. Wo bí àtubọ̀tán àwọn alábòsí ti rí.
41A ṣe wọ́n ní aṣíwájú tó ń pèpè sínú Iná. Tí ó bá sì di Ọjọ́ Àjíǹde, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
42Àti pé A fi ègún tẹ̀lé wọn ní ilé ayé yìí. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yó sì wà nínú àwọn ẹni ìparun.
43Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà lẹ́yìn ìgbà tí A ti pa àwọn ìjọ àkọ́kọ́ rẹ́. (Tírà náà jẹ́) ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí fún àwọn ènìyàn, ìmọ̀nà àti ìkẹ́ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
44Ìwọ kò sí ní ẹ̀bá ìwọ̀-òòrùn nígbà tí A fi ọ̀rọ̀ náà ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā. Àti pé ìwọ kò sí nínú àwọn tó wà níbẹ̀.
45Ṣùgbọ́n A ṣẹ̀dá àwọn ìran kan tí ẹ̀mí wọn gùn. O ò kúkú gbé láààrin ará ìlú Mọdyan, tí ò ń ké àwọn āyah Wa fún wọn, ṣùgbọ́n Àwa l’à ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́.
46Ìwọ kò sì sí ní ẹ̀bá àpáta náà, nígbà tí A pèpè, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá rí ṣíwájú rẹ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.[1]
47Tí ó bá jẹ́ pé àdánwò kan kàn wọ́n nítorí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn tì síwájú, wọn ìbá wí pé: “Olúwa wa, ti Ó bá jẹ́ pé O rán Òjíṣẹ́ kan sí wa ni, a à bá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ, a à bá sì wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
48Ṣùgbọ́n nígbà tí òdodo dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n fún un ní irú ohun tí Wọ́n fún (Ànábì) Mūsā?” Ṣé wọn kò sì ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí A fún (Ànábì) Mūsā ṣíwájú bí? Wọ́n wí pé: “Òpìdán méjì tó ń ranra wọn lọ́wọ́ (ni wọ́n).” Wọ́n sì tún wí pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìkọ̀ọ̀kan (wọn).”
49Sọ pé: “Nítorí náà, ẹ mú tírà kan wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tó ń tọ́ ni sí ọ̀nà ju ti àwọn méjèèjì lọ, mo sì máa tẹ̀lé e, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
50Tí wọn kò bá jẹ́pè rẹ, mọ̀ pé wọ́n kàn ń tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni. Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni tó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀, láì sí ìmọ̀nà (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu! Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
51Àti pé dájúdájú A ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
52Àwọn tí A fún ní Tírà ṣíwájú rẹ̀, wọ́n gbàgbọ́ nínú al-Ƙur’ān.
53Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọ́n á sọ pé: “A gbà á gbọ́. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa. Dájúdájú àwa ti jẹ́ mùsùlùmí ṣíwájú rẹ̀.”[1]
54Àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní ẹ̀ẹ̀ mejì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù, wọ́n sì ń fi dáadáa ti àìdaa dànù. Àti pé wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.
55Àti pé nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ burúkú, wọ́n á ṣẹ́rí kúrò níbẹ̀, wọ́n á sì sọ pé: “Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Kí àlàáfíà máa ba yín. A kò wá àwọn aláìmọ̀kan (ní alábàáṣepọ̀).”
56Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́.[1] Àti pé Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
57Wọ́n wí pé: “Tí a bá (fi lè) tẹ̀lé ìmọ̀nà pẹ̀lú rẹ, àwọn ọ̀ṣẹbọ yóò kó wa kúrò lórí ilẹ̀ wa.” Ṣé A ò fún wọn ní ibùgbé (tí ó jẹ́) àyè ọ̀wọ̀ ìfọ̀kànbalẹ̀, tí wọ́n sì ń kó àwọn èso gbogbo n̄ǹkan wá síbẹ̀, tí ó jẹ́ èsè láti ọ̀dọ̀ Wa? Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
58Mélòó mélòó nínú ìlú tí A parẹ́, tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ ayé-jíjẹ nínú ìlú. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ibùgbé wọn, tí A kò jẹ́ kí ẹnì kan kan gbé ibẹ̀ lẹ́yìn wọn bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀. Àwa sì jẹ́ Olùjogún.
59Olúwa rẹ kò sì níí pa àwọn ìlú run (ní àsìkò tìrẹ yìí) títí Ó fi máa gbé Òjíṣẹ́ kan dìde nínú Olú-ìlú-ayé (ìyẹn, ìlú Mọkkah, ẹni tí) yóò máa ké àwọn āyah Wa fún wọn. (Ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀.) A ò sì níí pa àwọn ìlú (yìí) run sẹ́ àfi kí àwọn ara ibẹ̀ jẹ́ alábòsí.
60Kò sí ohun tí A fún yín bí kò ṣe nítorí ìgbádùn ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Ohun tó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé. Nítorí náà, ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni?
61Ǹjẹ́ ẹni tí A bá ṣàdéhùn ní àdéhùn tó dára, tí ó sì máa pàdé rẹ̀, dà bí ẹni tí A fún ní ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé bí, lẹ́yìn náà ní Ọjọ́ Àjíǹde tí ó máa wà nínú àwọn tí wọn yóò mú wá (fún ìyà Iná)?
62(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Níbo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ wà?”
63Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí wí pé: “Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí tí a kó ṣìnà, a kó wọn ṣìnà gẹ́gẹ́ bí àwa náà ṣe ṣìnà. A yọwọ́ yọsẹ̀ (nínú ọ̀rọ̀ wọn) níwájú Rẹ (báyìí); kì í ṣe àwa ni wọ́n ń jọ́sìn fún.”
64A sọ (fún wọn) pé: “Ẹ pe àwọn òrìṣà yín.” Wọ́n sì pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn kò dá wọn lóhùn. Wọ́n ti rí Iná. Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n jẹ́ olùmọ̀nà ni (ìyà ìbá tí jẹ wọ́n.)
65(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Kí ni ẹ fọ̀ ní èsì fún àwọn Òjíṣẹ́?”
66Èsì ọ̀rọ̀ yó sì fọ́jú pọ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́ ní ọjọ́ yẹn; wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè.[1]
67Ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, ó súnmọ́ pé ó máa wà nínú àwọn olùjèrè.
68Olúwa rẹ l’Ó ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń ṣa (ohun tí Ó bá fẹ́) ní ẹ̀ṣà. Ṣíṣa ẹ̀ṣà kò tọ́ sí wọn.[1] Mímọ́ ni fún Allāhu. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
69Olúwa rẹ sì mọ ohun tí igbá-àyà wọn ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀.
70Òun sì ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. TiRẹ̀ ni gbogbo ẹyìn ní ilé ayé yìí àti ní ọ̀run. TiRẹ̀ sì ni ìdájọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
71Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá sọ òru di ohun tí ó máa wà títí láéláé fún yín di Ọjọ́ Àjíǹde, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu l’ó máa fún yín ní ìmọ́lẹ̀? Ṣé ẹ kò gbọ́rọ̀ ni?”
72Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá sọ ọ̀sán di ohun tí ó máa wà títí láéláé fún yín di Ọjọ́ Àjíǹde, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu l’ó máa fún yín ní alẹ́ tí ẹ óò máa sinmi nínú rẹ̀? Ṣé ẹ kò ríran ni?”
73Nínú ìkẹ́ Rẹ̀ (ni pé), Ó ṣe òru àti ọ̀sán fún yín; nítorí kí ẹ lè sinmi nínú (òru) àti nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Rẹ̀ (ní ọ̀sán) àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.
74(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Níbo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ wà?”
75A sì máa mú ẹlẹ́rìí kan jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan. A máa sọ pé: “Ẹ mú ẹ̀rí yín wá.” Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé dájúdájú òdodo ń jẹ́ ti Allāhu. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.[1]
76Dájúdájú Ƙọ̄rūn wà nínú ìjọ (Ànábì) Mūsā, ṣùgbọ́n ó ṣègbéraga sí wọn. A sì fún un ní àwọn àpótí-ọrọ̀ èyí tí àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ̀ wúwo láti gbé fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àwọn alágbára. (Rántí) nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ fún un pé: “Má ṣe yọ ayọ̀ àyọ̀jù. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn aláyọ̀jù.
77Fi n̄ǹkan tí Allāhu fún ọ wá ilé Ìkẹ́yìn. Má sì ṣe gbàgbé ìpín rẹ ní ilé ayé. Ṣe dáadáa gẹ́gẹ́ bí Allāhu ti ṣe dáadáa fún ọ. Má sì ṣe wá ìbàjẹ́ ṣe lórí ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn òbìlẹ̀jẹ́.”
78Ó wí pé: “Dájúdájú wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ tó ń bẹ lọ́dọ̀ mi ni.”[1] Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ti parun nínú àwọn ìran tó ṣíwájú rẹ̀, ẹni tí ó lágbára jù ú lọ, tí ó sì ní àkójọ ọrọ̀ jù ú lọ? A ò sì níí bi àwọn arúfin léèrè (ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó kúkú ti wà ní àkọsílẹ̀.)
79Ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Àwọn tó ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé yìí sì wí pé: “Háà! Kí á sì ní irú ohun tí wọ́n fún Ƙọ̄rūn. Dájúdájú ó ní ìpín ńlá nínú oore.”
80Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ sọ pé: “Ègbé ni fún yín! Ẹ̀san Allāhu lóore jùlọ fún ẹni tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì sí ẹni tí ó máa rí (ẹ̀san náà) gbà àfi àwọn onísùúrù.”
81Nítorí náà, A jẹ́ kí ilẹ̀ ríri gbé òun àti ilé rẹ̀ mì. Kò ní ìjọ kan tí ó lè ràn án lọ́wọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì sí nínú àwọn tó lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́.
82Àwọn tó ń rankàn ipò rẹ̀ ní àná sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ṣé ẹ rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu kẹ́ wa ni, ìbá jẹ́ kí ilẹ̀ ríri gbé àwa náà mì ni. Ṣé ẹ rí i pé àwọn aláìmoore kò níí jèrè.”
83Ilé Ìkẹ́yìn yẹn, A máa fi fún àwọn tí kò fẹ́ máa ṣe ìgbéraga àti ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Ìgbẹ̀yìn rere sì wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
84Ẹnikẹ́ni tí ó bá dé pẹ̀lú iṣẹ́ rere, tirẹ̀ ni rere tó lóore ju èyí tó mú wá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì dé pẹ̀lú iṣẹ́ aburú, A kò níí san àwọn tó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san kan àfi ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
85Dájúdájú Ẹni tí Ó ṣe al-Ƙur’ān ní ọ̀ran-anyàn fún ọ (láti mú un lò àti láti pèpè sí i), Ó sì máa dá ọ padà sí ibùpadàsí kan (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra). Sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mú ìmọ̀nà wá àti ta ni ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”
86Ìwọ kò sì retí pé A óò sọ tírà al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ (tẹ́lẹ̀), àmọ́ ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún àwọn aláìgbàgbọ́.
87Má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́ ọ lórí kúrò níbi àwọn āyah Allāhu lẹ́yìn ìgbà tí A ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún ọ. Pèpè sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
88Má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Gbogbo n̄ǹkan l’ó máa parun àfi Ojú Rẹ̀ (ìyẹn pàápàá bíbẹ Allāhu -subhānu wa ta‘ālā -). TiRẹ̀ ni ìdájọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni wọn yóò da yín padà sí.