مريم
Mary • 98 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Kāf hā yā ‘aēn sọ̄d. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
2(Èyí ni) ìrántí nípa ìkẹ́ tí Olúwa Rẹ ṣe fún ẹrúsìn Rẹ̀ (Ànábì) Zakariyyā.
3(Rántí) nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ ní ìpè ìkọ̀kọ̀.
4Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú eegun ara mi ti lẹ, orí (mi) ti kún fún ewú, èmi kò sì níí pasán nípa bí mo ṣe ń pè Ọ́, Olúwa mi.
5Àti pé dájúdájú mò ń páyà àwọn ìbátan mi lẹ́yìn (ikú) mi. Ìyàwó mi sì jẹ́ àgàn. Nítorí náà, ta mí lọ́rẹ láti ọ̀dọ̀ Rẹ ọmọ rere kan,
6(tí) ó máa jogún mi, tí ó sì máa jogún àwọn ẹbí (Ànábì) Ya‘ƙūb. Kí O sì ṣe é ní ẹni tí O yọ́nú sí, Olúwa mi.”
7Zakariyyā, dájúdájú Àwa máa fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan, orúkọ rẹ̀ ni Yahyā. A kò fún ẹnì kan ní (irú) orúkọ (yìí) rí ṣíwájú (rẹ̀).
8Ó sọ pé: “Olúwa mi, báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí ìyàwó mi jẹ́ àgàn, tí mo sì ti di àgbàlagbà gan-an.”
9(Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ni (ó máa rí).” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún Mi. Mó kúkú dá ìwọ náà ṣíwájú (rẹ̀), nígbà tí ìwọ kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan.”
10(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” (Mọlāika) sọ pé: “Àmì rẹ ni pé, o ò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, kì í ṣe ti àmódi.”
11Nígbà náà, ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ láti inú ilé ìjọ́sìn. Ó sì tọ́ka sí wọn pé kí wọ́n máa ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.
12Yahyā, mú Tírà náà dání dáradára. A sì fún un ní àgbọ́yé ẹ̀sìn láti kékeré.
13(Ànábì Yahyā jẹ́) ìkẹ́ àti ẹni mímọ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó sì jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).
14(Ó tún jẹ́) oníwà rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Kò sì jẹ́ ajẹninípá, olùyapa.
15Àlàáfíà ni fún un ní ọjọ́ tí wọ́n bí i, àti ní ọjọ́ tí ó máa kú àti ní ọjọ́ tí A óò gbé e dìde láàyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde).
16Sọ ìtàn Mọryam tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. (Rántí) nígbà tí ó yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ sí àyè kan ní ìlà òòrùn.
17Ó mú gàgá kan (láti fi ara rẹ̀ pamọ́) fún wọn. A sì rán mọlāika Wa sí i. Ó sì fara hàn án ní àwòrán abara pípé.[1]
18(Mọryam) sọ pé: “Èmi sá di Àjọkẹ́-ayé kúrò lọ́dọ̀ rẹ, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).”[1]
19(Mọlāika) sọ pé: “Èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ, (Ó rán mi sí ọ) pé kí n̄g fún ọ ní ọmọkùnrin mímọ́ kan.”[1]
20Ó sọ pé: “Báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí abara kan kò fọwọ́ kàn mí, tí èmi kò sì jẹ́ alágbèrè.”
21(Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ló máa rí.” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún mi. Àti pé nítorí kí Á lè ṣe é ní àmì fún àwọn ènìyàn ni. Ó sì jẹ́ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó tún jẹ́ ọ̀rọ̀ tí A ti parí (tí ó gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ.)”
22Nítorí náà, ó lóyún rẹ̀. Ó sì yẹra pẹ̀lú rẹ̀ sí àyè kan tó jìnnà.
23Ìrọbí ọmọ sì mú un wá sí ìdí igi dàbínù. Ó sọ pé: “Háà! Kí n̄g ti kú ṣíwájú èyí, kí n̄g sì ti di ẹni tí wọ́n ti gbàgbé pátápátá.”
24Nígbà náà, (mọlāika) pè é láti ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ti ṣe odò kékeré kan sí ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ.
25Mi igi dàbínù náà sọ́dọ̀ rẹ, kí dàbínú tútù, tó tó ká jẹ sì máa jábọ́ sílẹ̀ fún ọ.
26Nítorí náà, jẹ, mu kí ojú rẹ sì tutù. Tí o bá sì rí ẹnì kan nínú abara, sọ fún un pé: “Dájúdájú mo jẹ́jẹ̀ẹ́ ìkẹ́nuró fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, èmi kò níí bá ènìyàn kan sọ̀rọ̀ ní òní.”
27Ó sì mú ọmọ náà wá bá àwọn ènìyàn rẹ̀ (ní ẹni tí) ó gbé e dání. Wọ́n sọ pé: “Mọryam, dájúdájú o ti gbé n̄ǹkan ìyanu ńlá wá.
28Arábìnrin Hārūn, bàbá rẹ kì í ṣe ènìyàn burúkú. Àti pé ìyá rẹ kì í ṣe alágbèrè.”
29Ó sì tọ́ka sí ọmọ náà. Wọ́n sọ pé: “Báwo ni a ó ṣe bá ẹni tó wà lórí ìtẹ́, tó jẹ́ ọmọ òpóǹló sọ̀rọ̀?”
30(Ọmọ náà) sọ̀rọ̀ pé: “Dájúdájú ẹrú Allāhu ni èmi. (Allāhu) fún mi ní Tírà. Ó sì ṣe mí ní Ànábì. [1]
31Ó ṣe mí ní ẹni ìbùkún ní ibikíbi tí mo bá wà. Ó pa mí láṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ lódiwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nípò alààyè (lórí ilẹ̀ ayé).
32(Ó ṣe mí ní) oníwà rere sí ìyá mi. Kò sì ṣe mí ní ajẹninípá, olórí burúkú.
33Àlàáfíà ni fún mi ní ọjọ́ tí wọ́n bí mi, àti ní ọjọ́ tí mo máa kú àti ní ọjọ́ tí Wọ́n á gbé mi dìde ní alààyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde).”
34Ìyẹn ni (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam. (Èyí jẹ́) ọ̀rọ̀ òdodo tí àwọn (yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀.
35Kò yẹ fún Allāhu láti sọ ẹnì kan kan di ọmọ. Mímọ́ ni fún Un. Nígbà tí Ó bá pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
36Àti pé dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà.
37Àwọn ìjọ (yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) sì yapa-ẹnu (lórí èyí) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (ní àsìkò) ìjẹ́rìí gban̄gba l’ọ́jọ́ ńlá (Ọjọ́ Àjíǹde).
38Kí ni wọn kò níí gbọ́, kí sì ni wọn kò níí rí ní ọjọ́ tí wọn yóò wá bá Wa![1] Ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ní ọjọ́ òní (ní ilé ayé) wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
39Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná, wọn kò sì gbàgbọ́.
40Dájúdájú Àwa l’A máa jogún ilẹ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò dá wọn padà sí.
41Mú (ìtàn) ’Ibrọ̄hīm wá sí ìrántí (bí ó ṣe) wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì.
42Rántí nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, nítorí kí ni o fi ń jọ́sìn fún ohun tí kò gbọ́rọ̀, tí kò ríran, tí kò sì lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kan kan.
43Bàbá mi, dájúdájú ìmọ̀ tí ìwọ kò ní ti dé bá mi. Nítorí náà, tẹ̀lé mi, kí n̄g fi ọ̀nà tààrà mọ̀ ọ́.
44Bàbá mi, má ṣe bọ aṣ-Ṣaetọ̄n. Dájúdájú aṣ-ṣaetọ̄n jẹ́ olùyapa àṣẹ Àjọkẹ́-ayé.
45Bàbá mi, dájúdájú èmi ń páyà pé kí ìyà kan láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé má fọwọ́ bà ọ́ nítorí kí ìwọ má baà di ọ̀rẹ́ aṣ-ṣaetọ̄n (nínú Iná).”
46(Bàbá rẹ̀) wí pé: “Ṣé ìwọ yóò kọ àwọn ọlọ́hun mi sílẹ̀ ni, ’Ibrọ̄hīm? Dájúdájú tí o ò bá jáwọ́ (nínú ohun tí ò ń sọ), dájúdájú mo máa lẹ̀ ọ́ lókò pa. Tíẹ̀ yẹra fún mi fún ìgbà kan ná..”
47(’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Àlàáfíà kí ó máa bá ọ. Mo máa bá ọ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Ó jẹ́ Olóore mi.
48Àti pé mo máa yẹra fún ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Èmi yó sì máa pe Olúwa mi. Ó sì súnmọ́ pé èmi kò níí pasán pẹ̀lú àdúà mi sí Olúwa mi.”
49Nígbà tí ó yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, A sì ta á lọ́rẹ (ọmọ), ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ rẹ̀). A sì ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní Ànábì.[1]
50Àti pé A ta wọ́n lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa. A sì fi òdodo sórí ahọ́n gbogbo àwọn ènìyàn nìpa wọn (ìyẹn ni pé, gbogbo ìjọ ẹlẹ́sìn ló ń sọ̀rọ̀ wọn ní dáadáa).
51Sọ ìtàn (Ànábì) Mūsā tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ ẹni-ẹ̀ṣà, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì.
52A pè é ní ẹ̀bá àpáta ní apá ọwọ́ ọ̀tún (Mūsā). A sì mú un súnmọ́ tòsí láti bá a sọ̀rọ̀.
53A sì fi arákùnrin rẹ̀, Hārūn, (tí ó jẹ́) Ànábì, ta á lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa.
54Sọ ìtàn (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olùmú-àdéhùn-ṣẹ, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì.
55Ó máa ń pa ará ilé rẹ̀ ní àṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Ó sì jẹ́ ẹni ìyọ́nú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀.
56Sọ ìtàn (Ànábì) ’Idrīs tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì.
57A sì gbé e sí àyè gíga (nínú sánmọ̀).
58Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) Ādam àti nínú àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh àti nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Isrọ̄’īl àti nínú àwọn tí A ti fi mọ̀nà, tí A sì ṣà lẹ́ṣà. Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Àjọkẹ́-ayé fún wọn, wọ́n máa dojú bolẹ̀; tí wọ́n á foríkanlẹ̀, tí wọ́n á sì máa sunkún.
59Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn, tí wọ́n rá ìrun kíkí láre, tí wọ́n tẹ̀lé àwọn adùn. Láìpẹ́ wọn máa pàdé òfò (nínú Iná).
60Àyàfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí ṣàbòsí kan kan sí wọn.
61(Wọn yóò wọ inú) àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn ní ìkọ̀kọ̀[1] fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Dájúdájú (Allāhu), àdéhùn Rẹ̀ ń bọ̀ wá ṣẹ.
62Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀ àfi àlàáfíà. Ìjẹ-ìmu wọn wà nínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.
63Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A óò jogún rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù (Mi) nínú àwọn ẹrúsìn Wa.
64Àwa (mọlāika) kì í sọ̀kalẹ̀ àyàfi pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ. TiRẹ̀ ni ohun tí ń bẹ níwájú wa, ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wa àti ohun tí ń bẹ láààrin (méjèèjì) yẹn. Àti pé Olúwa rẹ kì í ṣe onígbàgbé.
65Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀?
66Ènìyàn ń wí pé: “Ṣé nígbà tí mo bá kú, wọn yóò tún mú mi jáde láìpẹ́ ní alààyè?”
67Ṣé ènìyàn kò rántí pé dájúdájú Àwa ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nígbà tí kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan?
68Nítorí náà, mo fi Olúwa rẹ búra; dájúdájú A máa kó àwọn àti àwọn aṣ-ṣaetọ̄n jọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú wọn wá sí ayíká iná Jahanamọ lórí ìkúnlẹ̀.
69Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan ẹni tí ó le jùlọ nínú wọn níbi ẹ̀ṣẹ̀ dídá sí Àjọkẹ́-ayé.
70Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí wíwọ inú Iná.
71Kò sí ẹnì kan nínú yín àfi kí ó débẹ̀ (àfi kí ó gba ibẹ̀ kọjá). Ó di dandan kí ó ṣẹlẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.
72Lẹ́yìn náà, A máa gba àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu) là. A sì máa fi àwọn alábósì sílẹ̀ sínú Iná lórí ìkúnlẹ̀.[1]
73Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò sọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Èwo nínú ìjọ méjèèjì (àwa tàbí ẹ̀yin) ló lóore jùlọ ní ibùgbé, ló sì dára jùlọ ní ìjókòó (afẹ́)?”
74Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn, tí wọ́n dára jù wọ́n lọ ní ọrọ̀ (ayé) àti ní ìrísí!
75Sọ pé: “Ẹni tí ó bá wà nínú ìṣìnà, Àjọkẹ́-ayé yó sì fẹ (ìṣìnà) lójú fún un tààrà, títí di ìgbà tí wọn máa rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, yálà ìyà tàbí Àkókò náà. Nígbà náà, wọn yóò mọ ẹni tí ó burú jùlọ ní ipò, tí ó sì lẹ jùlọ ní ọmọ ogun.
76Allāhu yó sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún àwọn tó mọ̀nà. Àwọn iṣẹ́ rere ẹlẹ́san gbére lóore jùlọ ní ẹ̀san, ó sì lóore jùlọ ní ibùdésí lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.
77Sọ fún mi nípa ẹni tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí ó sì wí pé: “Dájúdájú wọn yóò fún mi ní dúkìá àti ọmọ!”
78Ṣé ó rí ìkọ̀kọ̀ ni tàbí ó rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé?
79Rárá. A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tó ń wí. A sì máa fẹ ìyà lójú fún un tààrà.
80A ó sì jogún ohun tó ń wí fún un. Ó sì máa wá bá Wa ní òun nìkan.
81Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè fún wọn ní agbára.
82Rárá. Wọ́n máa tako ìjọ́sìn wọn, wọ́n si máa di ọ̀tá wọn.
83Ṣé ìwọ kò wòye pé dájúdájú Àwa ń dẹ àwọn aṣ-ṣaetọ̄n sí àwọn aláìgbàgbọ́ ni, tí wọ́n sì ń gùn wọ́n gan-an (síbi ẹ̀ṣẹ̀)?
84Nítorí náà, má ṣe kánjú nípa (ìyà) wọn. A kúkú ń ka (ọjọ́) fún wọn ní kíkà tààrà.
85(Rántí) ọjọ́ tí A óò kó àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) jọ sọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé lórí n̄ǹkan ìgùn.
86A sì máa da àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ sínú iná Jahanamọ wìtìwìtì.
87Wọn kò níí ní ìkápá ìṣìpẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àdéhùn láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé.
88Wọ́n wí pé: “Àjọkẹ́-ayé fi ẹnì kan ṣe ọmọ.”
89Dájúdájú ẹ ti mú n̄ǹkan aburú wá.
90Àwọn sánmọ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nítorí rẹ̀, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àwọn àpáta sì fẹ́rẹ̀ dàwó lulẹ̀ gbì
91fún wí pé wọ́n pe ẹnì kan ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé.
92Kò sì yẹ fún Àjọkẹ́-ayé láti fi ẹnì kan ṣe ọmọ.
93Kò sí ẹnì kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àyàfi kí ó wá bá Àjọkẹ́-ayé ní ipò ẹrúsìn.
94Dájúdájú (Allāhu) mọ̀ wọ́n. Ó sì ka òǹkà wọn tààrà.
95Gbogbo wọn yó sì wá bá A ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìkọ̀ọ̀kan.
96Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, Àjọkẹ́-ayé yóò fi ìfẹ́ sáààrin wọn.
97Nítorí náà, dájúdájú A fi èdè abínibí rẹ (èdè Lárúbáwá) ṣe (kíké al-Ƙur’ān àti àgbọ́yé rẹ̀) ní ìrọ̀rùn nítorí kí o lè fi ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ìjọ tó ń ja òdodo níyàn
98Mélòó mélòó nínú ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn! Ǹjẹ́ o gbọ́ ìró ẹnì kan kan nínú wọn mọ́ tàbí (ǹjẹ́) o gbọ́ ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ wọn bí?