الهمزة
The Gossipmonger • 9 ayahs • Meccan
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
1Ègbé ni fún gbogbo abúnilójú-ẹni, abúnilẹ́yìn-ẹni,
2ẹni tí ó kó dúkìá jọ, tí ó sì kà á lákàtúnkà (láì ná an fún ẹ̀sìn).
3Ó ń lérò pé dájúdájú dúkìá rẹ̀ yóò mú un ṣe gbére (nílé ayé).
4Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀). Dájúdájú wọ́n máa kù ú lókò sínú Hutọmọh ni.
5Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Hutọmọh?
6(Òhun ni) Iná Allāhu tí wọ́n ń kò (tó ń jó geregere),
7èyí tí ó máa jó (ẹ̀dá) wọ inú ọkàn lọ.
8Dájúdájú wọ́n máa ti (àwọn ìlẹ̀kùn) Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.
9(Wọ́n máa wà) láààrin àwọn òpó kìrìbìtì gíga (nínú Iná).